Èèyàn méji bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá n'Ibadan fún pé wọ́n ní ẹ̀yà ara èèyàn lọ́wọ́

Atẹlẹsẹ oku to wa lori ibusun ati ẹno to n fa aṣọ rẹ nita

Oríṣun àwòrán, Google

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọkunrin meji kan, Ridwan Bello ati Fatai Adeleke ni awọn ọlọpaa ti mu niluu Ibadan bayii, lori ẹsun hihu oku, wọn si ni ẹya ara eeyan lọwọ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita, pe awọn afurasi yii ko niṣẹ meji ju ki wọn maa hu oku eeyan ki wọn si maa ta a fun oogun owo lọ.

Osifeso ṣalaye pe Ridwan Bello tawọn eeyan mọ si Asarailu, ni ọwọ kọkọ ba lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta ọdun 2025 .

Alukoro sọ pe nnkan bii aago meji aabọ ọsan ọjọ naa ni awọn ọlọpaa lati teṣan Iyaganku, ṣabẹwo sile rẹ lẹyin ti olobo ta wọn nipa iṣẹ laabi ti ẹni ọdun marundinlogoji (35) naa n ṣe.

Agbegbe Muslim, n'Ibadan ni ile naa wa bi ọlọpaa ṣe ṣalaye.

Kí ni wọ́n bá nílée Ridwan?

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Oyo ṣe ṣalaye nipa ohun ti wọn ba nilee Ridwan Bello (Asarailu) o ni:

"Lasiko ti a n yẹ inu ile naa wo, a ri gbunduku ara obinrin kan ati awọn ẹya ara eeyan mi-in ti wọn ti ge. Bẹẹ la ri ọwọ ati ẹsẹ pẹlu awọn egungun gbigbẹ ti wọn ko sinu apo ati inuu garawa .

"Nigba to n jẹwọ ẹṣẹ rẹ, Bello sọ pe itẹ oku kan to wa ni Awa-Ijebu, nijọba ibilẹ Ariwa ipinlẹ Ogun loun ti hu oku naa.

"O tun jẹwọ pe oun ta awọn ẹya ara rẹ fun oniṣegun kan, bẹẹ lo mu awọn agbofinro lọ sibi itẹ oku naa, nibi ti wọn ti fidi ohun to sọ mulẹ.

"Bo ṣe jẹwọ siwaju si i lo ṣatọkun bọwọ ṣe ba Fatai Adeleke, ẹni aadọrin ọdun (70 yrs), to maa n ra ẹya ara eeyan naa lọwọ rẹ.

Adeleke naa jẹwọ pe oun maa n ra ẹya ara oku eeyan lọwọọ Bello loootọ.

"A ti taari ẹjọ naa si ẹka to n ri si ẹsun ipaniyan nipinlẹ Oyo, bẹẹ ni iṣẹ n lọ lati mu awọn to ba tun lọwọ ninu rẹ."

Osifeso lo sọ bẹẹ.

Alukoro ọlọpaa Oyo gba awọn to n ṣọ itẹ oku nimọran lati maa kiyesara ju ti tẹlẹ lọ nitori awọn to n fi ara eeyan ṣowo yii.

Bakan naa lo rọ awọn awakọ lati maa yẹ ẹru awọn ero ọkọ wo finni-finni, lati kapa awọn to n gbe oku eeyan kiri apo kiri.

Bi ẹnikẹni ba kẹẹfin iwa ọdaran lagbegbe rẹ nipinlẹ Oyo, awọn nọmba yii ni ọlọpaa fi sita fun wọn lati pe, fun ifisun ati ifitonileti: 615 to jẹ nọmba pajawiri, tabi ki wọn pe 08081768614, 09054133071 ati 09061299291.