Àwọn ṣọ́jà Sudan gba ilé ìjọba padà lẹ́yìn ogun abẹ́lé ọlọ́dún méjì

Oríṣun àwòrán, Sudan TV
Awọn ẹṣọ ologun lorilẹede Sudan ti sọ pe awọn ti gba ile ijọba to wa ni Khartoum pada lọwọ awọn ikọ RSF.
Awọn aworan ati fidio ti wọn fi sori ayelujara, eyi ti BBC ti fidi ẹ mulẹ pe otitọ ni, ṣafihan awọn ologun ti wọn n yọ̀ pẹlu ibọn ti wọn gbe dani.
Bẹẹ lawọn mi-in kunlẹ, ti wọn n ṣe adua.
Ikọ ologun naa fi agbara wọn han, pẹlu bi wọn ṣe ri ile aarẹ naa gba lẹyin ọdun meji ti awọn RSF ti le wọn jade nibẹ.
Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ikọ RSF ko ti i sọ nnkan kan.
Nabil Abdallah, agbẹnusọ awọn ṣọja ni Sudan, ṣalaye lẹka iroyin abẹnu wọn, pe awọn ṣọja ti fipa gba ile ijọba naa ati awọn ile mi-in to jẹ tijọba to wa ni aarin gbungbun Khartoum.
"Awọn ẹṣọ wa ṣẹgun awọn alatako pẹlu nnkan ija wọn, a ti gba awọn nnkan ija kan lọwọ wọn ati ọpọlọpọ irinṣẹ ogun.
"A fi n da yin loju pe a ko ni i ṣiwọ ogun, afi ti a ba ṣẹgun tan patapata."
Abdallah lo sọ bẹẹ.
Ọdún méjì sẹ́yiì ni ogun abẹ́lé bẹ́ sílẹ̀ ní Khartoum

Oríṣun àwòrán, Sudan TV
Ogun abẹle to le lo bẹ silẹ ni Khartoum,lorilẹede Sudan lọdun meji sẹyin, igboro ilu naa kaakiri si ni ogun ti le ju.
Latigba naa ni ikọ ologun RSF ti gba olu ilu yii ati apa Iwọ-Oorun Sudan.
Bi awọn ologun ilu naa ṣe ri Khartoum gba pada yii jẹ iṣẹgun nla fun wọn, yoo si kopa pataki ninu ogun naa.
Koda, awọn ologun Sudan tun ri awọn iṣẹgun kan ko jọ lọsẹ to kọja lawọn apa kan laaarin ilu naa.
L'Ọjọbọ, awọn o ṣoju mi koro kan sọ pe awọn ri awọn irinṣẹ ogun lori afẹfẹ nitosi ile ijọba.
Ninu fidio kan to jade lọjọ Aiku, ọga ologun RSF, Mohammed Hamdan Dagalo, tawọn eeyan mọ si Hamedti, leri pe oun yoo gba ile ijọba naa atawọn agbegbe rẹ pada.
O tun dunkooko pe awọn ikọlu mi-in ṣi n bọ lapa Ariwa.
Gbogbo ajọsọ nipa alaafia to ti ṣiwaju ko mu eso rere wa, pẹlu bawọn RSF ṣe n leri pe awọn yoo ṣaa maa ja lọ tawọn yoo fi gba gbogbo aaye agbara tan ni.
Ogun Sudan yii ti tẹ ẹtọ ọpọ ọmọniyan mọlẹ, gẹgẹ bi Ajọ Iṣọkan Agbaye (UN) ṣe wi, awọn ṣọja ati RSF ti tẹ ẹtọ ọpọ eeyan loju mọlẹ gan-an.














