Iná ṣẹ́yọ ní pápakọ̀ òfúrufú Heathrow, ọ̀pọ̀ ọkọ̀ òfúrufú há

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Inu okunkun birimu ni papakọ ofurufu Heathrow, niluu London wa bayii lẹyin ti ina kan dede sẹyọ lẹba papakọ ofurufu naa.
Awọn alaṣẹ ni papakọ ofurufu ọhun yoo wa ni titi pa titi di aago mejila latari oru, wọn si ti wọgile awọn irinajo ofuru to yẹ ko waye nibẹ.
Iroyin ni baalu to le ni ẹgbẹrun kan lo yẹ ko ṣiṣẹ ni papakọ ofurufu naa amọ won ti wọgile awọn irinajo naa latari iṣẹlẹ ọhun.
Yatọ si awọn ọkọ ofurufu ti ko ni fo, wọn tun ti wọgile awọn irinajo ọkọ oju irin to wa lagegbe papakọ ofurufu Heathrow.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹgbẹrun ile ni ko ni ina ijọba
Atẹjade kan lati ọọfisi ajọ apinnaka ilẹ Gẹẹsi, National Grid, sọ pe ko si ina lawọn agbegbe kan.
Wọn ni ina ọba ti pada de si ọdọ awọn onibara ti iye wọn jẹ ẹgbẹ mejilelọgọta, amọ nnkan bii ẹgbẹrun marun un eeyan ni ko tii si ina nile wọn.
A gbọ pe ina to ṣẹyọ ni West London naa ti ba awọn irinṣẹ kan to n pese ina jẹ nibẹ.
National Grid sọ loju opo ayelujara rẹ pe "A n ṣiṣẹ takuntakun lati da ina pada fun awọn onibara wa laipẹ, a o maa bun yin gbọ nipa aṣeyọri wa.
Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn baalu to yẹ ko balẹ si Heathrow?
Ọpọlọpọ ọkọ ofurufu to yẹ ko balẹ si Heathrow lo ṣi wa loju ofurufu lasiko ti ina ọhun ṣẹyọ, awọn alaṣẹ si ti n dari awọn ọkọ naa si awọn papakọ ofurufu mii bayii.
Yatọ si awọn papakọ ofurufu ti wọn n dari ọkọ si, wọn tun n dari awọn ọkọ si awọn orilẹede mii.
Fun apẹrẹ, baalu to n bọ lati Bangkok ni wọn ti dari si Brussels bayii, nigba ti wọn dari ọkọ to n bọ lati ilu New York si Iceland.
Wọn tun dari baalu to n bọ lati Boston, l'Amẹrika si papakọ ofurufu Goose Bay, ni Canada.
Oniruru awọn baalu mii ni wọn dari sawọn ibomii bii Ireland, Cardiff, Manchester, Munich, Frankfurt, Madrid ati bẹẹ bẹẹ lọ.















