Ẹ̀yin awakùsà lọ́nà àìtọ́, agbégbọn, ajínigbé, ẹ dẹ́kun ìwà àìda, bíbẹ́ẹ̀kọ́, máà ba ojú yín jẹ́ - Makinde kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Ikilọ ti lọ si etígbọ̀ọ́ awọn eeyan to n wa kusa lọna aitọ nipinlẹ Oyo, awon ọmọ ẹgbẹ okunkun, agbebọn ati awọn oniṣẹ ibi yooku lati ṣiwọ ibajẹ tabi ki wọn koju ijiya ijọba.
Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ-ẹrọ Seyi Makinde lo kede ọrọ yii l'Ọjọbọ, ogunjọ oṣu Kẹta ọdun 2025.
Nibi ipade igbimọ to n ri si eto aabo nipinlẹ Oyo, eyi to waye n'Ibadan ni Gomina Makinde ti kilọ fun gbogbo ẹni ti ọwọ rẹ ko ba mọ, to si n ṣakoba fun aabo ipinlẹ yii.
Makinde sọ loju awọn aṣoju lati ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa nipinle Oyo, ati awọn agbofinro pẹlu awọn lọbalọba, pe ipinnu ti wa lati lo ijiya to tọ labẹ ofin fun eyikeyi awọn eeyan yii tọwọ ba tẹ.
O rọ wọn lati tete jawọ iwa to le da omi alaafia ipinlẹ naa ru, tabi ki wọn koju ijiya.
Ninu ọrọ tirẹ, Oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ aabo, CP Fatai Owoseni, sọ pe ipade naa ṣe pataki, lati le gbọ bi ọrọ aabo ṣe n lọ lati ẹnu awọn olori agbegbe kọọkan.
O rọ awọn eeyan Oyo lati mu ọrọ aabo ni pataki, ki wọn si maa lo nọmba 615 lati pe bi wọn ba ri nnkan pajawiri to nilo itẹtisi ijọba.
Owoseni sọ pe kia ni ijọba yoo da wọn lohun.

Oríṣun àwòrán, Gov. Seyi Makinde/ X
''Ìjọba yóò rí sí ọ̀rọ̀ ìjà ààlà ilẹ̀ lẹ́yìn ààwẹ̀ Ramadan''
Kọmiṣanna ọlọpaa Oyo, Johnson Adenola, sọ pe ijọba yoo ri si ọrọ ija aala ilẹ lẹyin aawẹ Ramadan.
Fun awọn to n wa kusa, kọmiṣanna sọ pe wọn gbọdọ gba iwe aṣẹ ki wọn too bẹrẹ iṣẹ iwakusa labẹ ofin.
O ni kawọn ẹlẹgbẹ okunkun atawọn amookunṣika yooku jawọ, ki wọn ma baa lugbadi ofin.
Nigba to n sọrọ lorukọ awọn ọba alaye yooku, Olu Igboora, Ọba Jimoh Olajide Titiloye, sọ pe awọn ọba ṣetan lati ran ijọba lọwọ lagbegbe wọn lori ọrọ aabo.
Bakan naa ni Sikiru Sanda, Alaga awọn alaga ijọba ibilẹ nipinlẹ Oyo, sọ pe gbogbo alaga kansu pata ni yoo kun ijọba lọwọ lati ṣẹgun iṣoro eto aabo.
Tẹ o ba gbagbe, Gomina Makinde kede ni nnkan bii oṣu meloo sẹyin, pe awọn agbesunmọmi to n kuro lapa Ariwa ti n sọlẹ sipinlẹ Oyo.

Oríṣun àwòrán, Gov. Seyi Makinde/ X














