Ìgbẹ́jọ́ Abdulrahman gbọ̀nà míì yọ, àṣírí tú nípa ibi tó wà, agbẹjọ́rò ìjọba àti tàwọn afurasí tako ara wọn

Abdulrahman ati awọn afurasi yoku nile ẹjọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbẹjọ Abdurahman Bello to pa Afsot Lawal ni ilu Ilọrin tẹsiwaju loni ogunjọ osu yii .

Nigbati igbẹjọ naa bẹrẹ loni, adajọ ile ẹjọ naa, S. B Muhammad beere orukọ awọn agbẹjọro.

Lọsẹ to kọja ni agbọ wi pe awọn ọlọpaa ti gbe afurasi Abdurahman Bello ati awọn mẹrin to ku lọ si ilu Abuja.

BBC Yoruba wa nile ẹjọ giga tilu Ilorin loni, abọ ohun to waye nibẹ ree.

"DSS gba akoso iwadii ẹjọ Abdulrahman, o ni iwadi ọlọpa lori isẹlẹ naa ko kun to"

Agbẹjọro ijọba Isa Sakare sọ fun ile ẹjọ pe, ajọ eleto aabo otẹlẹmuyẹ DSS ti gbakoso iwadii iṣẹlẹ naa, nitori pe iwadii ti ajọ ọlọpaa se lori iṣẹlẹ naa ko kun to.

O fikun ọrọ rẹ pe, ki ile ẹjọ fun ajọ DSS laye lati sewadi lẹkunrẹrẹ, ki igbejọ to le tẹsiwaju, ki wọn si da awọn afurasi naa pada si ihamọ ajọ eleto abo ọlọtẹmuyẹ DSS.

Ninu ọrọ ti ẹ, agbẹjọro fun awon afurasi mẹta to ku ti wọn n jẹjọ ati agbẹjọro ẹni kẹrin rọ ile ẹjọ lati jẹ ki ẹjọ naa o tẹsiwaju ni Ile ẹjọ giga.

O ni awọn ti ṣaaju ri iwe gba pe ẹjọ yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹrin ọdun yii.

Awọn agbẹjọro naa duro wi pe ajọ ọlọpaa ti pari iwadii wọn, lo mu ki wọn gbe awọn afurasi naa wa ile ẹjọ.

Abdulrahman ati awọn afurasi yoku nile ẹjọ

Baba oloogbe ni ki iwadii le kun dada, ni ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe gba ẹjọ naa lọwọ ajọ ọlọpaa

Lasiko to n da ẹjọ naa, adajọ ile ẹjọ ohun S B muhammad da ibeere awọn agbẹjọro naa nu.

Adajọ ni ẹjọ naa yoo tẹsiwaju ni ile ẹjọ naa titi wọn yoo fi ri iwe aṣẹ gba ni Ile ẹjọ giga.

Adajọ wa sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹsan oṣu kẹrin ọdun yii fun itẹsiwaju gbigbọ ẹjọ naa.

Lasiko to n ba Akọroyin BBC Yoruba sọrọ, agbẹjọro awọn obi ọmọ ti wọn seku pa, Hussein Sadam ni ki iwadii naa le kun dada, ni ajọ eleto abo ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe gba ẹjọ naa lọwọ ajọ ọlọpaa.

O fidi ẹ mulẹ pe, wọn ko gbe Abdurahman Bello lọ Abuja, o si wa ni Ilọrin ṣugbọn ọọfisi ajọ eleto abo otẹlẹmuyẹ DSS ló wa bayi .

Tẹ ẹ ba gbagbe pe, Abdurahman Bello lo pa Afsot yetunde Lawal sinu ile rẹ losu to kọja, to si kun oku rẹ wẹlẹ wẹlẹ.