Àwọn ọ̀dọ́ méjì tó já bàálù gbà lọ́dún 1993 torí ìbò June 12 bá BBC sọ̀rọ̀

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀dọ́ méjì tó já bàálù gbà torí ìbò June 12 bá BBC sọ̀rọ̀
Àwọn ọ̀dọ́ méjì tó já bàálù gbà lọ́dún 1993 torí ìbò June 12 bá BBC sọ̀rọ̀

Ni osu kẹwa ọdun 1993, awọn ọdọkunrin mẹrin ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹrindinlogun si mejidinlogun ja baalu Naijiria gba .

Idi ti wọn fi se bẹẹ ni lati fi ẹhonu wọn han lori bi ijọba Ologun labẹ ọgagun Ibrahim Badamosi Babangida se wọgile ibo June 12 eyi to gbe Oloye MKO Abiola wọle.

Laipẹ yii si ni Babangida si asọ loju eegun nipa ibo June 12, to si tọrọ aforijin fun ipinnu to se lasiko naa pẹlu bo se wọgile ibo ọhun.

Babangida wa gba pe oloogbe Moshood Kasimawo Olawale Abiola lo jawe olubori ninu ibo aarẹ to waye lọjọ kejila osu kẹfa ọdun 1993 naa.

Akọroyin BBC, Mobolaji Olatunde bawọn ọdọ meji to ja baalu naa gba sọrọ, wọn si salaye ohun ti oju wọn ri lati ọdun mejilelọgbọn sẹyin, ti isẹlẹ naa ti waye.

Wọn mẹnuba bi isẹlẹ yii se waye eyi to yii ilana ayanmọ aye wọn pada, eyi to ko jinnijinni ba awọn ero inu baalu naa.

Awọn ọdọ to ja baalu gba

"Ojo ni Babangida bo se gba pe Abiola lo bori ibo aarẹ June 12"

Nigba tawọn ọdọ mejeeji naa n ba BBC sọrọ, wọn ni ojo lasanlasan ni ọga Ologun Babangida bo se sẹsẹ kede bayii pe MKO Abiola lo bori ibo June 12 naa.

"Ọdun mejilelọgbọn lo ti yẹ ki Babangida yọ oju ootọ ọrọ yii sita, ojo nla ni.

Ọkunrin kan soso, tii se Ibrahim Babangida lo ja Naijiria gba nigba naa, ti a si fun ni wakati mejilelaadọrin pere lati Kede pe Abiola lo jawe olubori."

Ilẹ̀ Niger ni awọn ọkunrin mejeeji naa ti ja baalu Naijiria gba, ti wọn si da jinnijinni bo awn ero inu baalu naa eyi to mu ẹmi eeyan kan lọ.

Ile ẹjọ ni Niger sọ wn si ẹwọn ọdun mẹwa, eyi to yi ayanmọ aye wọn pada.