Wo ìgbà márùn-ún tí wọ́n ti kéde ìlú ò fararọ ní Nàìjíríà

Goodluck Jonathan, Tinubu, Obasanjo

Oríṣun àwòrán, FB/Multiple

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ìkéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni ìgbà karùn-ún tí irú ìkéde yìí ń wáyé ní Nàìjíríà láti ìgbà tí ìjọba ti padà sí alágbádá lọ́dún 1999.

BBC ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti wáyé àti ohun tó ṣokùnfà wọn.

Ìpínlẹ̀ Rivers

Ní àṣálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹta ni Ààrẹ Bola Tinubu ti kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers látàrí làásìgbò òṣèlú tó ń wáyé níbẹ̀.

Tinubu ní làásìgbò òṣèlú tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà láti bíi oṣù mélòó kan sẹ́yìn ń kọ òun lóminú àti pé gbogbo ìgbìyànjú òun láti ri pé ìfaǹfà náà wá sópin ló já sí pàbó.

Lẹ́yìn tí ààrẹ kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ náà ló ní kí gómìnà Siminalayi Fubara àti igbákejì rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ngozi Odu tó fi mọ́ àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ náà lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà.

Gẹ́gẹ́ bí ìkéde ààrẹ, Vice Admiral Ibokette Ibas ni yóò máa ṣe àkóso ìpínlẹ̀ Rivers.

Aáwọ̀ òṣèlú ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Rivers látàrí ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín gómìnà Fubara àti Nyesom Wike.

Ìfaǹfà yìí mú kí àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ gómìnà Fubara nípò.

2) Borno, Yobe àti Adamawa

Ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Karùn-ún, ọdún 2013 ni Ààrẹ ìgbà náà, Goodluck Ebele Jonathan látàrí ìkọlù agbéṣùmọ̀mí Boko Haram sáwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ Borno, Yobe àti Adamawa.

Àmọ́ Jonathan kò fòfin de àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ náà bíkòṣe pe ó kó àwọn ológun lọ síbẹ̀ tó sì kéde òfin kónílé ó gbélé láti dènà ìkọlù.

3) Borno àti Plateau

Ní ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ́n, oṣù Kejìlá, ọdún 2011 ni Goodluck Ebele Jonathan kéde ìlú ò fararọ láwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ Borno àti Plateau nítorí ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí Boko Haram tó ń wáyé nábẹ̀.

Ekiti

Ìjà ta ni yóò jẹ adarí tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Ekiti mú kí Ààrẹ Olusegun Obasanjo kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Ekiti nínú oṣù Kẹwàá, ọdún 2006.

Làásìgbò náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ náà gbìyànjú láti yọ gómìnà Ayo Fayose nípò.

Obasanjo yan Ọ̀gágun Adetunji Olurin gẹ́gẹ́ bí adele gómìnà títí tí làásìgbò náà fi lójútùú.

Plateau

Ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 2004 ni Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí, Olusegun Obasanjo kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Plateau tó sì ní kí gómìnà Joshua Dariye àtàwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ náà lọ rọ́kún nílé.

Obasanjo yan Ọ̀gágun Chris Alli gẹ́gẹ́ bí adelé gómìnà.

Obasanjo ní òun gbé ìgbésẹ̀ náà nítorí gómìnà Dariye kò rí aáwọ̀ àwọn mùsùlùmí àti ọmọlẹ́yìn Kristi tó ń pa ara wọn ní ìpínlẹ̀ náà yanjú lásìkò náà.