Tinubu kéde ìlú ò fararọ ní Rivers, yan alákòsóo torí kí ìpínlẹ̀ náà má baà gbiná ni - Fagbemi

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ijọba apapọ ti sọ pe ko si ohun to buru ninu ikede ilu o fararọ ti Aarẹ Bola Tinubu kede nipinlẹ Rivers, ati pe igbesẹ naa waye ki ipinlẹ ọhun ma ba a daru.

Adajọ agba Naijiria, Lateef Fagbemi, lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin nile ijọba to wa niluu Abuja.

Fagbemi sọ pe "Ki ni ẹyin ro pe o yẹ ko ṣe? Se o gbọdọ duro titi ti gbogbo nnkan yoo fi dojuru ni? Mi o ro bẹẹ o.

"Mo gbagbọ pe Aarẹ gbe igbesẹ to yẹ lasiko to yẹ, o ti fun gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lasiko to to lati yanju aawọ aarin wọn. O ti pe wọn tẹlẹ, o ti gbiyanju lati pari aawọ naa.

"Bi mo ṣe sọ tẹlẹ, igbesẹ akin ni Aarẹ gbe, gbogbo wa la wa nibẹ nigba to n sọrọ, o si ṣalaye gbogbo bi ọrọ naa ṣe jẹ lati ibẹrẹ titi de opin."

"Wọn ti n kọlu ọpa epo ni Rivers to jẹ ikoko ọbẹ gbogbo Naijiria, Aarẹ gbọdọ pa ina rogbodiyan naa, bi gomina se kawọ gbera"

Nigba ti awon akọroyin bere lọwọ rẹ boya ikede ilu o fara ni ọrọ kan fun ipinlẹ Rivers bayii, adajọ agba naa ni igbesẹ ọhun ṣe patakai lati pana rogbodiyan to n rugbo bọ ni Rivers.

O ṣalaye pe awọn ẹgbẹ ọmọ ogun Niger Delta ti n kọlu ọpa epo to wa ni Rivers, eyii to jẹ ikoko ọbẹ gbogbo Naijiria, nitori naa ko si ohun to kan ju ki Aarẹ gbe igbesẹ lati pa ina rogbodiyan naa niwọn igba ti gomina ipinlẹ ọhun kawọ gbera.

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni Aarẹ kede ilu o fararọ nipinlẹ Rivers, to si ni ki gomina Siminalayi Fubara, igbakeji rẹ Ngozi Odu, ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lọ rọọkun nile fun oṣu mẹfa gbako.

Ninu ọrọ ti Aarẹ ba araalu sọ lalẹ ọjọ naa, o ni eredi igbesẹ oun ko ṣẹyin gudugbẹ to ṣeeṣe ko ja lulẹ ni bẹ.

Wahala bẹrẹ ni Rivers lati igba ti fa ki n fa ti n waye laarin gomina ipinlẹ ọhun ati gomina tẹle, to tun jẹ minisita fun FCT bayii, Nyesom Wike, amọ ọrọ naa ti ta ba gbogbo araalu ipinlẹ naa bayii.

Ẹwẹ, ọpọ ọmọ Naijiria, ẹgbẹ alatako atawọn agbẹjọro lo ti bu ẹnu atẹ igbesẹ Aarẹ Tinubu ọhun.

Wọn ni ko ba ofin mu bi Tinibu ṣe kede ilu o frarọ nib ẹ ati bo ṣe da gomina ti ilu dibo yan duro.

Àkọlé fídíò, "Aya méjì, ọmọ méje ni alága darandaran tí wọn yìnbọn pa ní, ìjọba ẹ ṣàánú lórí ìtọ́jú wọn"

Ìkéde ìlú kò fararọ ní Rivers tako òfin, kò sì tọ̀nà - Atiku, NBA, PDP àtàwọn míì sọ̀rọ̀

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale

Ni bayii ti Aarẹ Bola Tinubu ti kede ilu o fararọ nipinlẹ Rivers, to si fi alakoso tuntun to jẹ ọlọgun rọpo gomina Siminalayi Fubara, ati igbakeji rẹ, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori igbeṣe naa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ohun ti Aarẹ ṣe ko bojumu, lawọn mii n sọ pe igbesẹ naa tọ lati pana rogbodiyan to n rugbo bọ nipinlẹ ọhun lasiko yii.

Lara awọn to ti sọrọ soke ni ẹgbẹ oṣelu PDP, igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, ajafẹtọọmọniyan, Omoyele Sowore, ẹgbẹ awọn agbẹjọro, NBA atawọn araalu mii.

Lara awọn ohun ti wọn n sọ ree.

Tinubu ti fi ijọba awarawa yi ẹrẹ - Atiku

Nigba to n sọrọ loju opo X rẹ lẹyin ikede Aarẹ, Atiku Abubakar ti oun funra rẹ ti fi ọpọ igba du ipo naa ri sọ pe ohun ti Tinubu ṣe ko daa to.

Atiku ni igbesẹ Tinubu ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu idagabsoke ijọba awarawa ati ilọsiwaju ipinlẹ Rivers.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ijọba Tinubu wa lara awọn to ṣokunfa rogbodiyan ipinlẹ Rivers, nitori naa, niṣe lo yẹ ko gba ẹbi rẹ dipo ko maa mọọmọ fi iya jẹ awọn eeyan ipinlẹ ọhun.

O ni "Ẹnikẹni to ba n tẹle ohun to n ṣẹlẹ ni Rivers yoo mọ pe Bola Tinubu lọwọ ninu rogbodiyan oṣelu to waye nibẹ latari bo ṣe kọ lati tete gbe igbesẹ lati pana wahala ọhun.

"Yatọ si ọrọ oṣelu, ojuṣe Aarẹ ni lati yanju eto abo to dagẹgẹ nibẹ ko to di pe wọn n ba dukia ilu jẹ.

"O jẹ ohun ibanujẹ pe lasiko Tinubu ni wahala tun bẹ silẹ lagbegbe Niger Delta bii asiko ijọba Umaru Yar'Adua."

Atiku pari ọrọ rẹ pe kii ṣe ikede ilu o fararọ ni Rivers lo kan, o si yẹ ki gbogbo ọmọ Naijiria bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ọhun.

Ko ba ofin mu lati dede yọ gomina nipo lai ṣe pe ogun bẹ silẹ – Ẹgbẹ awọn agbẹjọro, NBA

Ninu atẹjade kan lọjọ Iṣẹgun, ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA, ti kede pe ko ba ofin mu ki Aarẹ ṣadede kede ilu o fararọ ni ipinlẹ kan ko si yọ gomina ibẹ nipo.

Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Mazi Afam Osigwe, SAN, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

Atẹjade ọhun sọ pe "Yiyọ nipo gomina Fubara, igba igbakeji rẹ ati idaduro ile igbimọ asọfin lodi si ofin, igbesẹ naa si lewu fun ijọba awara ni Naijiria."

NBA ni Aarẹ ko le kede ilu o fararọ ayafi ti ogun ba bẹ silẹ, ti ogun ba n kan ilẹkun lati ilẹ okere tabi ti rogbodiyan ba bẹ silẹ silẹ eyii to le da omi alaafia Naijiria ru nikan ni Aarẹ le kede ilu o fararọ.

Ẹgbẹ ọhun sọ pe niwọn igba ti awọn nnkan wọnyii ko tii ṣẹlẹ, ko lẹtọọ fun Aare Tinubu lati kede ilu o fararọ ko si ni ki gomian lọ maa sinmi nile.

Ẹwẹ, ọpọ araalo lo ti n sọ pe ikede ilu o fararọ ni Rivers, kaka bẹẹ niṣe lo yẹ ki awọn ọmọ Naijiria funra wọn kede ilu fafarọ lori iṣejọba Bola Ahmed Tinubu.

Àkọlé fídíò, Ìṣesí wọn nílé aṣòfin àgbà dà bí ilé ẹgbẹ́ awo - Natasha Akpoti

Tinubu kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers, fòfin de gómìnà, igbákejì rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà

Ààrẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ààrẹ Bola Tinubu ti kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers látàrí làásìgbò òṣèlú tó ń wáyé níbẹ̀.

Níbi ọ̀rọ̀ tí ààrẹ bá àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sọ ní àṣálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹta ló ti sọ̀rọ̀ náà.

Tinubu ní làásìgbò òṣèlú tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà láti bíi oṣù mélòó kan sẹ́yìn ń kọ òun lóminú.

Ó ní gbogbo ìgbìyànjú òun láti ri pé ìfaǹfà náà wá sópin ló já sí pàbó.

Lẹ́yìn tí ààrẹ kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ náà ló ní kí gómìnà Siminalayi Fubara àti igbákejì rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ngozi Odu lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà.

Bákan náà ló ní gbogbo àwọn tí wọ́n dìbò yàn sílé aṣòfin ìpìnlẹ́ náà lọ rọ́kún nílé lóṣù mẹ́fà.

Ààrẹ ní nǹkan ìbànújẹ́ ló jẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers wo ilé aṣòfin láti bíi ọdún kan àbọ̀, tí wọn kò sì rí nǹkankan ṣe si títí di àsìkò yìí.

Ó ní láti ìgbà tí wọ́n ti ń bá ara wọn fa ìfaǹfà ni kò tis í ìlọsíwájú kan gbòógì ní ìpínlẹ̀ náà nítorí wọn kò jẹ́ kí àwọn ará ìlú jẹ múkùndún ìjọba àwaarawa.

Ó ní òun kò lè máa wòran, gẹ́gẹ́ bí ààrẹ, kí nǹkan máa bàjẹ́ ní orílẹ̀ èdè òun, èyí ló sì mú òun láti tẹ̀lé ìwé òfin tó fi ààyè gba òun láti kéde ìlú ò fararọ.

Ta ni yóò máa ṣe àkóso ìpínlẹ̀ Rivers báyìí?

Gẹ́gẹ́ bí ìkéde ààrẹ, Vice Admiral Ibokette Ibas ni yóò máa ṣe àkóso ìpínlẹ̀ Rivers láti alẹ́ yìí lọ.

Tinubu ní ìkéde òun yìí kò kan ẹ̀ka ìdájọ́, tí ẹ̀ka náà sì ní àǹfàní láti máa bá iṣẹ́ wọn lọ.

Ó ní alákòso ìpínlẹ̀ Rivers tuntun yìí, kò ní àǹfàní láti ṣe ]ofin tuntun kankan fún ìgbà tó bá fi wà nípò àmọ́ tó lè gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ èyí tí ìjọba àpapọ̀ nílò láti buwọ́lu.