Ọmọ mi ọkùnrin kanṣoṣo kú lójijí, mo máa ń sunkún tí mo bá ti rí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ - Lola Idije

Oríṣun àwòrán, Instagram/Lola Idije
Gbajugbaja oṣere tiata, Toyin Afolayan, ẹni ti ọpọ mọ si Lola Idije ni ọkan oun ma n kun fun ibanujẹ, ti oun ba ranti ọmọ oun ọkunrin kan soso to di oloogbe.
Lasiko to n ṣe ifọrọwerọ lori ikanni Talk2Dunnis TV ni Afolayan ti tan imọlẹ si igbesi aye, iṣẹ rẹ ati awọn ohun to la kọja gẹgẹ oṣere tiata ati abiyamọ.
O ni iṣẹ tiata ko fi igba kankan jẹ nkan to wu oun lati ibẹrẹ.
Afolayan ni oun ni nifẹẹ si okoowo siṣe ṣugbọn ẹgbọn rẹ, AdeLove, lo fa wọ ninu iṣẹ naa
"AdeLove ko ipa nla ninu aye mi, to si jẹ oun lo jẹ ki lọ kọ iṣẹ tiata.
Mo n si dupẹ lọwọ rẹ titi di asiko yii, ki Ọlọrun ba mi tẹ si afẹfẹ rere."
"Mo bi ọmọ ọkunrin ri ṣugbọn ọmọ ọkunrin mi ku lai ro tẹlẹ, ṣugbọn mo dupẹ pe awọn obinrin wa"
Agba oṣere naa ṣalaye ohun to la kọja lẹyin to padanu ọmọ rẹ ọkunrin kan soso.
O ni ọpọ igba ti oun ba ri awọn ọrẹ ọmọ rẹ ni omije ma n jabọ loju rẹ.
"Mo bi ọmọ ọkunrin ri ṣugbọn ọmọ ọkunrin mi ku lai ro tẹlẹ, ṣugbọn mo dupẹ pe awọn obinrin wa.
"Obinrin ni awọn ọmọ mi, awon ọmọ mi lo ṣẹṣẹ n bi ọkunrin fun mi bayii.
"Gẹgẹ bii abiyamo, ti mo ba n ri awọn sawawu rẹ, mo n wo pe to ba jẹ pe lagbaja wa laye ni, mi o mọ ohun to ma da, ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun."
Ta a ni Lola Idije?
Wọn bi Lola Idije ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹsan an ọdun 1959.
O di ilumọka pẹlu sinima Deadly Affair, nibi to ti ṣe Madam Adisa lọdun 1995.
Toyin Afolayan jẹ ọmọ bibi ilu Agbamu nipinlẹ Kwara.
O jẹ aburo fun Adeyemi Afolayan, ẹni ti ọpọ mọ si AdeLove, toun naa jẹ gbajumọ osere tiata nigba aye rẹ.
Bakan naa lo tan mọ awọn ọmọ AdeLove ti wọn jẹ agba oṣere bi Kunle Afolayan, Gabriel Afolayan, Aremu Afolayan ati Moji Afolayan.















