'Àrùn tó lé ní 80 ni dókítà lè fi ìwọ́ àti olubi ọmọ wò'

Aworan ọmọ ikoko pẹlu ìwọ́

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

A o ni i rohun gbe sọnu bi ko ṣe ibi ọmọ ni Yoruba maa n wi, nitori igbagbọ wọn ni pe ọjọ ta a ba ribi ni ibi gbọdọ wọlẹ.

Ibi tabi olubi ọmọ jẹ ohun keji to maa n ba ọmọ waye lọjọ ikunle alaboyun, bi wọn ba si ti n gbe ọmọ tuntun to jẹ ire kuro ninu ẹjẹ ni wọn yoo maa bo ikeji rẹ to jẹ ibi mọlẹ.

Eyi ri bẹẹ nitori ọpọ eeyan gbagbọ pe ibi ko wulo laye, inu iya nikan lo ti wulo lati fun ọmọ ni eemi Oxygen, kọmọ si maa gba ibẹ jẹun.

Ṣugbọn iwadii ijinlẹ awọn dokita oniṣegun oyinbo ti fidi ẹ mulẹ, pe ohun to yẹ ka tọju, ṣe lọjọ nilana ti ko fi ni i bajẹ ni olubi ọmọ jẹ.

Wọn ni iwosan nla lo n bẹ lara ibi ti a n ri mọlẹ, bo ṣe le wo warapa lo le wo aisan foniku-fọla dide, rọpa-rọsẹ, giri ati awọn aisan aṣekupani ọlọdun gbọọrọ.

Alaye ree lẹnu Dokita Ogunleye Toluwalope, ẹni to yannana ohun ti olubi ọmọ le ṣe nilana ti wọn pe ni stem cell, pẹlu ìwọ inu ọmọ.

'Iwosan to kun fọfọ wa lara ibi ìwọ́ ọmọ'

Dokita Ogunleye Toluwalope
Àkọlé àwòrán, Dokita Ogunleye Toluwalope

''Ìwọ́ ati olubi ọmọ yẹn, a le fi tan aarun to le ni ọgọrin (80).

''Ko too di asiko yii, a ri i pe wọn maa n sọ olubi ọmọ nu ni, paapaa nilẹẹ Yoruba.

''Ṣugbọn nitori pe imọ sayẹnsi n dagba si i, a ṣawari kinni kan ti a n pe ni Stem cell, kinni naa wa lara, o maa sọ ara di ọtun ni, ara yoo si ṣe daadaa.

''Sayẹnsi ti waa jẹ ka mọ pe olubi ati iwọ ọmọ jẹ ọkan lara awọn ọna to kun fọfọ ju lati ri stem cell yii.

'' Mudunmudun inu eegun la maa n lo tẹlẹ lati ri stem cell, ṣugbọn a ti waa ri i pe olubi ati iwọ ọmọ lo kun ju .

''Oriṣi stem cell yii meji lo wa, a n pe kan ni embryonic stem cell, ikeji ni adult stem cell.

Embryonic yii, ofin iṣẹ wa ko gba wa laye lati lo o, ṣugbọn ti Adult yẹn, a le lo o. O dẹ daa, nitori yatọ si iya ati ọmọ ikoko, wọn le lo o fun ẹbi to ku naa, bii aburo, wọn le lo o fawọn ẹgbọn, wọn le lo o fun mọlẹbi gan-an.''

Dokita Ogunleye sọ pe awọn ti fi ilana yii wo aisan foniku-fọla dide mẹẹẹdogun ni Naijiria.

O ni mọlẹbi le fi iwọ ati ibi ọmọ pamọ fun ọdun mẹẹẹdogun, ẹyọkan ti wọn ba si tọju naa yoo ṣiṣẹ fun gbogbo wọn.

Lára àwọn àìsàn tí olubi ọmọ lè wò

Bi Dokita Ogunleye ṣe sọ, lara awọn aisan ti ibi ọmọ le wosan ni

  • Leukemia(Jẹjẹrẹ inu ẹjẹ)
  • Lymphoma (Jẹjẹrẹ ara)
  • Sickle cell(Foniku-fọla dide)
  • Autism (Aisan to n mu ki ọmọ ma da ṣaka lọpọlọ)
  • Stroke( rọpa-rọsẹ)
  • Cerebral Palsy (Aisan to n sọ ọmọ di akanda ẹda)
  • Type 1 Diabetis( Oriṣi itọ ṣuga)
  • Oju fifọ
  • Eti didi
  • Aileṣe deede ọmọkunrin lọdọ abo
  • Giri
  • Warapa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Dokita Ogunleye gba awọn to ba ni ẹni ti eyikeyi aisan yii n da laamu lati ma ṣe wo wọn niran.

O ni anfaani leyi fun wọn lati fun awọn eeyan naa ni igbe aye alaafia lẹẹkan si i lai gbe wọn lọ soke okun fun itọju.

Olubi pẹlu iwọ ẹẹkan ṣoṣo le ṣiṣẹ fun gbogbo mọlẹbi, bi wọn ba gbe e gba ilana itọju ti yoo jẹ ko wa bẹẹ fun ọdun gbọọrọ.

Dokita Ogunleye Toluwalope ló ṣalaye bẹẹ