Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ n'Ibadan, 17 dèrò àtìmọ́lé

Aworan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ awọn akẹkọọ ilẹ ẹkọ nipa iṣẹ ọwọ, Government Technical College niluu Ibadan fun ẹsun iwa jaduku ati biba dukia jẹ.

Mẹtadinlogun ninu awọn akẹkọọ naa lọ wa ni ahamo ileeṣẹ olopaa nipinlẹ Oyo ti wọn yoo si f'oju ba ile ẹjọ laipe

Ohun taa ri gbọ nipe awọn awọn akẹẹkọ ile ẹkọ Government Technical College yaabo ileẹkọ Ibadan christ Apostolic School to wa ni agbegbe Aperin, ti wọn si baa awọn dukia ati awọn ferese ile ẹkọ naa jẹ patapata.

Iṣẹlẹ naa waye ni Ogunjọ Oṣu Kẹta ọdun 2025, lẹyin igba ti awọn akẹẹkọ ile ẹkọ Ibadan Christ Apostolic School ti lọ si ile wọn

Nigba ti o n sọrọ lori iṣẹlẹ naa Komisona fun ileeṣẹ olopaa nipinlẹ Oyo, Johnson Adenola ti bu ẹnu atẹ lu iwa ọdaran naa, o si ti ṣe ni kilo pe ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ko ni fi aye gba iwa ọdaran bẹẹ, ti igbese siti bẹrẹ lati mu opin baa iwa jagidijagan ni ipinlẹ naa .

Adenola tesiwaju pe iyalẹnu lọ jẹ nigba ti oun ṣe ifọrọwanilenuwo pẹlu awọn akẹkọọ naa ti iwaadi fihan wi pe nisẹ ni wọn wa ninu ẹgbẹ okunkun.

O ni ileeṣe olopaa yoo saa ipa rẹ lati mu opin baa irufẹ iṣẹlẹ naa nipinlẹ Oyo nipa lílọ si awọn ileẹkọ kakakiri ipinlẹ Oyo, ti wọn yoo si ba awọn akẹkọọ sọrọ nipa ewu to ninu didarapomo ẹgbẹ okunkun.

"O je nkankan ibanuje wi pe awọn ọmọ ọdun mokanla si ọdun mẹrindinlogun ni awọn ọmọ to wu iru iwa ibaje yii.

"A wa gẹgẹ bi ile iṣe olopaa, awa naa mura lati ri wi pe a un ba awọn ọmọde yii sọrọ laipe laijina amama lọ si awọn ile iwe yii nitori wi pe awọn ọmọde yii ọmọ ni wọn jẹ fun wá.

"Taba ko lati kọ wọn, awọn ni wọn ni jẹ ki awọn ọmọ wa taako gbadun ".

Ninu ọrọ rẹ Komisona fun ẹtọ, sayẹnsi ati imọ ẹrọ nipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Salihu Adelabu rọ awọn obi lati maa tọju awọn ọmọ wọn daadaa, ki wọn si kọ awọn ọmọ naa ni eko ile to yẹ. O fi kun un pe gbe igbese to yẹ lori iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ.

Adelabu ni, ofin Ipinlẹ Oyo to nisẹ pẹlu ijiya fun ọmọde ni awọn yoo lo lati fiyaje awọn akẹkọọ ti wọn ba jẹbi ẹsun naa.

O ni Ipinlẹ Oyo ko ṣetan lati ba aye awọn ọmọ naa jẹ, sugbọn awọn yoo saa ipa wọn lati ri wi pe awọn ọmọ naa fimu Kasa ofin.

"Ofin to de to sọ kini a gbodo fi ọmọ kekere ṣe ofin yẹn ni wọn bawa gbọn yebeyebe lati mo ohun ti ao ṣe gẹgẹ bi ijọba ".

Aworan