Bí aráàlú ṣe le pe aṣòfin padà sílé pé kó má ṣojú wọn mọ́

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti-Uduaghan/Instagram
Ẹgbẹ awọn oludibo kan ni ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Kogi ti pe fun idapada Sẹnetọ to n ṣoju wọn nile igbimọ aṣofin Naijiria, Natasha Akpoti-Uduaghan.
Sẹnetọ yii lo ni ede aiyede pẹlu olori ile, Godswill Akpabio, to si tun fẹsun kan pe o fi ibalopọ lọ oun.
Ẹgbẹ naa ti wọn pe ara wọn ni 'Concerned Kogi Youth and Women' kọ iwe si ajọ eleto idibo ni Naijiria INEC lọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹta.
Akọwe ajọ eleto idibo lo tẹwọgba iwe naa.
Omole Ijese to sọrọ fun ẹgbẹ naa ni, eeyan 250,000 to jẹ oludibo lo tọwọbọ iwe naa ninu eeyan 488,000 to jẹ oludibo ni agbegbe naa. O ni eyi kọja ohun ti INEC n bẹre fun.
Awọn eniyan naa n fẹ ki ajọ INEC rọ Arabinrin Natasha Akpoti-Uduaghan loye gẹgẹ bi sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo wọn.
Ẹwẹ, aṣofin naa ninu ọrọ kan to gbe soju opo ayelujara Instagram ni ko si mimi kankan to le mi oun kuro nipo titi wọ ọdun 2027.
"Ki wọn le pa ohun mi, wọn da mi duro, nibayii wọn fẹ pe mi pada kuro ni ile igbimọ aṣofin.
"Mo ni igbagbọ ninu Ọlọrun pe ma bori, ma si tun jẹ Sẹnetọ to n soju awọn aarin Kogi titi wọ ọdun 2027."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ki lo de ti awọn eeyan fi ni ki wọn gba iṣẹ lọwọ Sẹnetọ Natasha?
Wọn pe akọle iwe naa ni 'Pipe Sẹnetọ Natasha Akpoti-Uduaghan pada nitori a ko ni igbagbọ ninu rẹ mọ'.
Awọn oludibo naa sọ pe igbesẹ awọn wa ni abamu pẹlu iwe ofin ọdun 1999 ati iwe ofin INEC.
Wọn ni ihuwasi Sẹnetọ Akpoti-Uduaghan lo mu wọn pinnu pe awọn ko fẹ ẹ mọ gẹgẹ bii aṣoju.
Wọn ṣapejuwe iwa ti wọn ni o hu, gẹgẹ bi nnkan idojuti si awọn enian ipinlẹ Kogi, paapa ile igbimọ aṣofin ati orilẹede lapapọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ki ni ofin sọ nipa yiyọ aṣofin nipo?
Pipe aṣofin pada si ile lati ile igbimọ aṣofin jẹ anfani fun awọn oludibo lati pe aṣoju ti wọn ko b ani igbagbọ ninu rẹ mọ saaju ki wọn to pari saa wọn.
Igbesẹ mẹta ni Pipe pada naa.
- Akọkọ ni kikọ iwe ransẹ si ajọ INEC, ki ilaji awọn oludibo ni agbegbe naa si buwọlu iwe naa pe awọn ko fẹ aṣoju naa mọ.
- Aridaju
- Ipaẹnupọ
Lẹyin ti INEC ba tẹwọgba iwe naa, ofin ni ki wọn ṣe iwadii ni kikun lati ri i daju pe otitọ ni pe ida idaji awọn oludibo lo fọwọ si iwe naa.
Bakan naa ni lati yẹ ẹ wo boya iwe naa wa ni ibamu pẹlu ofin.
Ti iwe ipe ba bọ si ipele keji, to jẹ aridaju, INEC yoo ṣe idibo laarin gbogbo ilu lati fi ẹnu wọn dibo pe ki wọn yọ aṣofin naa pẹlu "YES tabi NO" idahun.
Ti ọpọ ba dahun pẹlu BẸẸNI, INEC yoo fun aṣofin naa ni iwe ipepada, ti wọn yoo si ṣe eto idibo miran, Bye-Election, lati yan aṣofin tuntun.
Ṣugbọn ti ọpọ ba tako ipe naa, aṣofin naa yoo tẹsiwaju iṣẹ rẹ.
- Ọjọ melo oni igbesẹ yii fi waye?
Ofin ni INEC gbọdọ ṣe iwadii iwe naa laarin aadọrun ọjọ ti wọn ba tẹwọgba iwe naa.
- N jẹ eeyan ti wọn ba yọ le tun gbe apoti ibo?
Ofin o sọ pe wọn ko le tun kopa ninu eto idibo.
Wo awọn aṣofin ti awọn eeyan ti kọ iwe ipada sile fun?
Eyi ki n ṣe igba akọkọ ti awọn eeyan agbegbe yoo dide pe awọn ko fẹ aṣoju wọn mọ ni ile igbimọ aṣofin agba tabi ile aṣoju sofin.
Ọdun 2000 ni igba akọkọ ti iṣẹlẹ yii waye nigba ti awọn eeyan agbegbe Njikoka ti George Okoye n ṣoju fun dide, kọwe ransẹ si INEC.
Lẹyin ọ rẹyin, iyọnipo naa ko pada waye.
Bakan naa ni ọdun 2017, INEC tẹwọgba iwe to pe iyọnipo Dino Melaye kuro ni ile igbimọ aṣofin ṣugbọn ohun naa fidi rẹmi
Farouk Aliyu, Umar Jibril ati awọn mii naa koju iṣoro yii.
Bo ti lẹ ọpọ eeyan n kọminu lori bi ẹgbẹ to kọwe tako Sẹnetọ Natasha Akpoti ṣe ri ọpọ eeyan buwọlu iwe naa.
Awọn eeyan kan ni agbegbe naa ni o ṣeeṣe ki wọn lo magomago pelo awọn eeyan naa.











