Ǹjẹ́ o mọ̀ pé gbígbọ́ ariwo lè fa ikú òjijì fún èèyàn?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, James Gallagher
- Role, LOUD presenter, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ọpọ nnkan abami to ju buru jai, tii a ko le fi oju wa lasan ri lo yi wa ka. Awọn nnkan wọnyi lo ni ọpọ ijamba, to si n gba ẹmi awọn eeyan.
Awọn nnkan wọnyi n fa aisan ọkan, itọ suga, koda iwadii to jade laipẹ yii ni, o tun n fa aisan ki eeyan o maa gbagbe nnkan, eyi ti wọn n pe ni Dementia ni ede Gẹẹsi.
Ki ni ẹ ro pe a n sọrọ nipa?
Ariwo pipa, ijamba rẹ buru ju ki eti di lasan lọ.
"Isoro eto ilera nla ni, ti a si ti ri ọpọ eeyan ti wọn ti lugbadi ijamba rẹ," Ọjọgbọn Charlotte Clark ti fasiti St George niluu London ṣalaye.
O ni o jẹ iṣoro nla ti awọn eeyan ko kọ bi ara si, ti a ko si sọrọ nipa rẹ rara.
"Mo n se iwadii nipa bi ariwo se lewu to, t imo si n ba awọn eeyan to ti lugbadi ijamba rẹ sọrọ pẹlu erongba pe, ọna abayọ yoo wa ni ile-aye ti ọpọ ariwo ba dinku.
Mo ṣe abẹwo si Ọjọgbọn Clark, a gbera lati lọ wo bi ara awa eeyan se n gba ariwo, mo mu ẹrọ kan dani, eyi to da bi ago.
Ẹrọ kekere kan ni wọn fi ṣe ayẹwo ọkan mi ati iye aagun to n jade lara mi.
Iwọ naa le se eyi ti o ba ni ẹrọ yii,ti wọn fi si ẹ leti. Iwọn naa wa ri bi ara rẹ yoo se ri ti o ba gbọ awọn ariwo naa."

Ariwo to kọmilominu ju ni ariwo ọkọ niluu Dhaka, lorilẹede Bangladesh, eyi ti wọn ti ṣapejuwe gẹgẹ ilu to pariwo ju lagbaye. Bi mo ṣe n gbọ, o da bi pe mo wa laarin oju opopo pẹlu ṣunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.
Mo ri bi ariwo naa ṣe n sa kiri ago ara mi, ifunpa mi si n lọ soke, ti aagun si n bọ lara mi.
"Eri wa pe ariwo apaju n ṣakoba fun ilera eeyan,"Ọjọgbọn Clark ṣalaye.
Ariwo ti mo nifẹẹ si ju ni ti ibi iṣere awọn ọmọde, o mu ọkan mi balẹ. Ariwo aja ati ariwo lati ibi ariya ko dun lati gbọ rara.
Bawo ni ariwo se n mu ayipada ba ago ara?
"O ni iha ti ara eeyan ma n kọ si eyikeyi ariwo ti wọn ba gbọ," Ọjọgbọn Clark sọ.
Ti ariwo ba wọ inu eeyan lati eti, yoo lọ si ọpọlọ, ti yoo si ransẹ si awọn agọ ara yooku, jẹ nnkan ti a n pe ni amygdala. Eyi ni yoo sọ bi agọ ara yoo ṣe fesi si ariwo to ba gbọ.
O ni awọn igbesẹ kan ti yoo tẹlẹ lẹyin ti ariwo ba fi atẹjisẹ ransẹ si ọpọlọ.
"Ti eeyan ba lo ọpọ ọdun lati ma fi gbọ ariwo to pọ, o ṣeeṣe ki wọn lugbadi aisan ọkan, ifunpa to ga, rọparọsẹ ati itọ suga," Ọjọgbọn Clark sọ.

"Ariwo jẹ ohun ti ọpọ ko nifẹẹ si. Lilọ-bibọ ọkọ, reluwe, ati ọkọ ofurufu wa lara awọn nnkan to n fa ariwo. Nnkan ti eeyan kan n ṣe fun igbadun ara rẹ le jẹ ariwo ni eti eeyan miiran."
Mo pade Coco ni ile rẹ to wa ni Vila de Gracia niluu Barcelona lorilẹede Spain.
Lati ẹnu ọna rẹ, o le ri gbogbo ilu. Eyi fihan pe Coco n gbadun ara rẹ pupọ ṣugbọn bayii o n pinnu lati parọ ile naa.
"Ariwo pọ nibi bayii… a ma n pariwo gan an," Coco ṣalaye. O fikun pe o ni ibi kan ti wọn ma n de aja si, to si jẹ pe oun ma n gbọ gbigbo aja ni bi ago meji ooru
O mu foonu rẹ jade lati kọ orin, ariwo to fẹ le wo ile lo jade .
O ti dero ile iwosan ni igba meji ọtọtọ fun aya riro , ti wọn si jẹ ko di mimọ pe, ariwo lo n sokunfa iṣoro fun ilera rẹ.
Dokita Maria Foraster ti n kọ ẹkọ nipa ariwo lati ajọ eleto ilera agbaye, WHO, ni o le ni eeyan 300 to n ni ikọlu aya ni ọdun kan ni Barcelona, ilu kan ni orilẹede Spain, ti ọgbọn ninu wọn si n padanu ẹmi wọn.
Iṣoro ariwo pipa yii lo n ti n di lemọlemọ nitori bi awọn eeyan ṣe n lọ si awọn ilu to tobi nibi ti ariwo pọ si.
Dhaka, Bangladesh, jẹ ọkan lara ilu to n gbooro l'agbaye. Eyi lo fa a ti ọpọ eeyan fi n lọ si ilu naa, ti ariwo si n pọ.
Momina Raman Royal ni tiẹ ma n gbe akọle soke loju opopona lati pe akiyesi awọn araalu si pataki fifopin si ariwo pipa niluu naa.
Ni ojoojumọ, o ma n lo isẹju mẹwaa loju opopona lati da awọn awakọ lẹkọọ lori ijamba to wa ninu ariwo pipa.














