'Àwọn darandaran ti lé wa kúrò l'óko, kò dín ní èèyàn méjì tí wọ́n n pa l'ọ́sẹ̀'

Àkọlé fídíò, 'Àwọn Fulani ti lé wa kúrò l'óko, kò dín ní èèyàn méjì tí wọ́n n pa lójújọ́'
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn olugbe abule Ala, ilu kan to wa ni ijọba ibilẹ Akure North nipinlẹ Ondo, ti kegbare lori bi awọn afurasi Fulani darandaran ṣe n kọlu wọn, ti wọn ko si jẹ ki wọn o ṣe iṣẹ oko mọ.

Eyi jẹyọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti awọn araalu naa ṣe pẹlu BBC Yoruba.

Ṣaaju ifọrọwanilẹnuwo naa ni awọn araalu ti ọrọ kan, ṣe iwọde lọ si ọfiisi gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, lati fi ẹhonu wọn han lori ipenija wọn.

Nibi iwọde naa ni wọn ko oku awọn eeyan kan ti awọn afurasi naa ṣẹṣẹ pa.

Ẹnikan to jẹ aṣoju ilu, Arakunrin Oluwasina Ajisegbede, sọ pe lati bi ọdun marun un ni awọn darandaran naa ti wa ni agbegbe naa.

"Lati igba naa ni wọn ti n fi ẹran wọn jẹ oko wa, gbogbo ẹbẹ wa si ni wọn kọ eti ikun si."

Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Arakunrin Ajisegbede sọ pe laipẹ ni wọn fi ọgbọn tan awọn araalu kan to fẹ ẹ ra maalu wọ inu oko, ti wọn si pa gbogbo wọn.

"Pẹlu awọn ọlọpaa lati fi ri oku wọn ko kuro nibi ti wọn pa wọn si, ti a si gbe wọn lọ sileewosan ijọba to wa niluu Akure."

O fi ẹsun kan pe lati bi ọdun meji sẹyin ni rogbodiyan naa ti l'agbara si i, ti gbogbo ariwo fun iranlọwọ lati ọdọ ijọba ipinlẹ Ondo, ko si so eso kankan.

Bakan naa lo sọ pe ibẹru ko jẹ ki ẹnikẹni lọ si oko mọ, ti awọn si ti fi ilu, to jẹ oriirun awọn silẹ.

"Nigba miran ti a ba fẹ ẹ lọ sinu oko, a nilo lati lọ papọ lẹẹkan naa, ti ao si gbe ọkada bii mẹwaa si mẹẹdogun dani."

Monday Eyo, ọkan lara awọn ti afurasi darandaran yinbọn mọ
Àkọlé àwòrán, Monday Eyo, ọkan lara awọn ti afurasi darandaran yinbọn mọ

Ẹnikan lara awọn ti awọn afurasi darandaran naa yinbọn mọ nibi ikọlu to waye kẹyin, Ọgbẹni Monday Eyo sọ pe inu oko ni oun ati awọn akẹẹgbẹ rẹ to jẹ oṣiṣẹ wa, nibi ti wọn si ti n lọ wa ounjẹ ti wọn o jẹ ni wọn ti ko sọwọ awọn afurasi ọhun.

"Bi wọn ṣe ri wa ni wọn beere pe ọga wa nkọ. Mo da wọn lohun pe ọga wa ko wa si oko.

"Bẹẹ ni wọn gbe ibọn, ti wọn si yin lu mi, pẹlu ikilọ pe awọn ko fẹ ẹ ri ẹnikẹni ninu oko naa mọ."

Lasiko ti a ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun Monday Eyo, oju ọgbẹ ti wọn ti yọ ọta ibọn ṣi wa ni ẹgbẹ ikùn rẹ. Bakan naa ni wọn fi bandeeji so apa rẹ kan to kun fun ẹjẹ.

Ki lo ṣẹlẹ nibi iwọde to waye niluu Akure?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ogunlọgọ awọn olufehonuhan lo yabo ọfiisi gomina ni Alagbaka n'ilu Akure lori iku awọn agbẹ marun-un latọwọ awọn darandaran.

Eyi waye ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2025.

Awọn olufehonuhan naa sọ pe iha ko kan mi, ati aibikita Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa lori iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe lagbegbe Ala nijọba ibilẹ Ariwa Akure lati bi oṣu meji sẹyin lo mu ki wọn yabo ọfiisi rẹ.

Awọn olufehonuhan naa gbe oku awọn marun-un ti wọn pa naa dani pẹlu sibi iwọde wọn.

Awọn agbẹ yii ni wọn pa ni idaji ọjọ naa latọwọ awọn afurasi darandaran to seku pa agbẹ ti ko din ni ogun ni abule mẹrin nijọba ibilẹ kan naa nibi ọsẹ meji sẹyin.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ Ọgbẹni Jayeoba Francis to jẹ ọkan lara awọn olori agbegbe naa sọ pe, wọn wa si ọfiisi gomina nitori awọn ikọlu to n waye ni agbegbe Ala, paapaa julọ bi awọn afurasi darandaran tun ṣe pa awọn marun-un miran lowurọ ọjọ naa.

O sọ pe wọn gbe oku naa wa a lati fi han gomina ko le ri pe ootọ ni awọn sọ.

Ọgbẹni Jayeoba salaye pe saaju asiko yi, oriṣiriṣi ikọlu ni wọn koju, ti awọn afurasi darandaran si n ba awọn nnkan oko wọn jẹ.

O sọpe Igbakeji Gomina Olayide Adelami ti seleri pe ni kete ti gomina ba pade de lati irinajo, wọn yoo gbe igbese lori ọrọ naa

Bákan naa, Oloye Ayọ Fadare sọ pe lati bi ọsẹ meji ni awọn darandaran ti ba aba wọn jẹ ti gbogbo awọn olugbe aba Otọpe si ti sa asala fun ẹmi wọn.

Iyaafin Fadare sọ pe awọn ajinigbe naa ji awọn ọmọ wọn meji gbe lọ ti wọn si n bere fun miliọnu mẹwaa naira fun itusilẹ wọn.

O rọ ijọba lati ma ṣe faaye gba awọn afurasi ọhun lati maa da awọn maalu wọn ni awọn igbo ọba nipinlẹ Ondo ni ibamu pelu igbese ti gomina tẹlẹ, oloogbe Rotimi Akeredolu, gbe.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Kini ijọba ipinlẹ Ondo ati ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Lasiko to n ba awọn eniyan naa sọrọ niwaju ọfiisi gomina n'ilu Akure, Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Olayide Adelami, sọ pe iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe lagbegbe naa jẹ eyi ti ko bojumu ti ijọba yoo si ri daju pe opin de ba a.

Adelami wa pasẹ fun ajọ Amọtẹkun lati sagbekale oriko wọn si agbegbe naa lojuna ati le jẹ ki alaafia o jọba.

Igbakeji gomina sọ pe wọn yoo ba awọn asoju mẹwa lati agbegbe naa ṣe ipade lati le wa ojutuu si iṣẹlẹ naa.

Bakan naa Kọmisọna Ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Wilfred Afolabi, sọ pe wọn ti n ṣiṣẹ takuntakun lati ri daju pe ọwọ tẹ awọn ọdaran to n domi alaafia ipinlẹ Ondo ru.

Kọmisọna naa salaye pe ki awọn ara ilu fọkanbalẹ ki wọn ma si faaye gba awọn kọlọransi ẹda lati raaye ṣiṣẹ laarin wọn.

O seleri pe alaafia yoo jọba ni agbegbe naa laipẹ.