Imisi, ọ̀dọ́mọbìnrin to jáwé olúborí ni BBNaija Season 10, ohun táa mọ̀ nipa rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Big Brother Naija
Imisi, ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Opeyemi Ayanwale lo jawe olubori ninu eto Big Brother Naija Season 10, to si mu owo to ọgọtọ milọnu naira lọ si ile ati ọpọlọpọ ifẹ lati ọdọ awọn ololufẹ rẹ kaakiri orilẹede Naijiria ati lagbaye.
Aṣeyọri rẹ ni wọn kede lasiko eto aṣekagba to waye ni alẹ ọjọ Aiku, Ọjọ karun un oṣu kẹwaa ọdun 2025.
Idaṣaka ẹni ọdun mẹtalelogun jẹ ọkan gboogi idi ti ọpọ awọn eeyan fi fẹran rẹ pupọ, ti wọn si fi tun dibo fun gẹgẹ olubori, eyi to sọ di eeyan to bori ti wọn ṣe ayẹyẹ fun julọ.
Akọle ọdun yii ni wọn pe ni "10/10", ni apapọ eeyan mọkandinlọgbọn kopa laaarin ọsẹ mẹwaa lati fi dije.
Imisi fidi akẹgbẹ rẹ Dede janlẹ si ipo keji ati koyin si ipo kẹta lati gba idije naa, to si di obinrin kẹrin ati eeyan keji to kere ju ti yoo bori idije naa lẹyin Ilebaye Odiniya, ẹni to gba ni ẹni ọdun mejilelogun.
Eyi ni awọn nnkan to yẹ ko mọ nipa Imisi
- Orukọ rẹ ni Opeyemi Ayanwale ṣugbọn ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ n pe ni Imisi.
- Ọdun 2002, ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni ni wọn bi Imisi.
- Imisi wa lati ipinlẹ Oyo, to si ọpọ fihan pe ọmọ Yoruba ni oun ninu iwa ati imurasi rẹ lasiko idije naa.
- Ṣaaju ko to bọ sinu idije, Imisi kawe gboye lati fasiti ilu Ibadan.
- O jẹ tun tailor to kọsẹmọsẹ, to si ti da ileeṣẹ rẹ silẹ ṣaaju ko to darapọ mọ idije Big Brother Naija.
- O n gbero lati darapọ mọ agbo sinima lorilẹede Naijiria, to si fi ọpọ ami han pe o ṣe daada to b ani anfani.
- Imisi ṣalaye pe oun koju ọpọ ipenija lasiko to n ba awọn akẹgbẹ rẹ sọrọ ninu idije. O ṣalaye ọpọ nnkan to ti padanu ati bi o ṣe ṣe ọkan akin lori awọn iṣẹlẹ.
- Imisi ko ni oluwa gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye pe oun ko ni ọrẹkunrin, to si jẹ pe o n gbajumọ idagbasoke ara rẹ lasiko yii.











