Natasha Akpoti lulẹ̀ lórí ẹjọ́ tó pé tako olórí ilé aṣòfin àgbà nípa oṣù mẹ́fà tó fi ní kó lọ rọọ́kún nílé

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Lẹ́yìn o rẹyìn, idajọ tí jáde lórí ẹjọ́ tó wà láàrin àwọn aṣòfin àti Senatọ obìnrin kan, Natasha Akpoti Uduaghan
Ile ẹjọ́ wọ́gilé ẹjọ tí Natasha Akpoti pè tako bí ilé aṣòfin àgbà àti ààrẹ ilé ṣe ní kò lọ sinmi nílé fún oṣù mẹ́fà
Adájọ́ James Omotosho tile ẹjọ gíga ìlú Abuja tí wọ́gilé ẹjọ́ kan tí Sẹnatọ Natasha Akpoti pe lati tako bí olórí ilé, Godswill Akpabio àti ilé asofin àgbà náà ṣe ni kò lọ rọọkun nílẹ̀ fún oṣù mẹ́fà nítorí aimọ iwa hu.
"Awọn olupẹjọ mẹwẹẹwa kò ní ẹtọ kankan labẹ òfin láti gbé ẹjọ́ náà wà sile ẹjọ"
Ẹjọ́ náà tí ọkùnrin kan Ovavu Illiyasu àti àwọn èèyàn mẹsan miran pe ni adájọ́ yí dànù torí pé wọn kò lẹtọ láti pé ẹjọ́ náà
Ẹjọ́ náà tí nọmba faili rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/654/2025, ní wón pé tako bí ilé ṣe ni kí Senatọ Akpoti lọ rọọkun nile nítorí àwọn ìdí kan.
Àwọn olupẹjọ naa lo rọ ilé ẹjọ́ láti wọ́gilé ìjìyà tile aṣòfin àgbà fun Natasha náà nítorí yóò ṣe àkóbá fún ẹkùn idibo to ń soju.
Nigba to ń gbé ìdájọ́ rẹ kalẹ, adájọ́ Omotosho ni àwọn olupẹjọ mẹwẹẹwa náà kò ní ẹtọ kankan labẹ òfin láti gbé ẹjọ́ náà wà sile ẹjọ.
O wa da ẹjọ́ náà nù nítorí pé kò lẹsẹ nílẹ̀.
Ki
Kí lo wáyé ṣáájú tile aṣòfin àgbà see ni kí Senatọ Natasha Akpoti lọ rọọkun nile fun oṣù mẹ́fà?
Ninu oṣu Keji ọdun 2025 ni ede aiyede ṣẹlẹ ni ile aṣofin agba Naijiria, laarin Aarẹ ile naa, Sẹnetọ Godswill Akpabio ati Sẹnetọ Natasha Akpoti-Uduaghan.
Akpabio paṣẹ lasiko ti ijiroro n lọ pe, ki awọn oṣiṣẹ alaabo gbe e jade lẹyin ti obinrin naa kọ lati joko ni aaye tuntun ti wọn fun, to si sọ awọn ọrọ ibinu.
O fi ẹsun kan Akpabio pe o mọọmọ fẹ pa oun lẹnu mọ ni, to si fẹ gba anfaani ti oun ni lati da si ijiroro ile, lọwọ oun.
Lẹyin gbogbo awuyewuye to waye lọjọ naa, ile aṣofin fi ẹsun kan Natasha pe o tapa si awọn ilana ile naa, pẹlu bo ṣe kọ lati jokoo si aaye ti wọn fun un.
Ọrọ naa de iwaju igbimọ to n ba awọn aṣofin wi, ṣugbọn Natasha kuna lati farahan niwaju igbimọ naa.
Lẹyin rẹ ni wọn kede pe wọn ti da a duro fun oṣu mẹfa.
Ọrọ ọhun pada di ti ile ẹjọ, pẹlu bi igun mejeeji ṣe pe ẹjọ ọtọọtọ lori rẹ.















