Mọ̀ nípa àsè ìgbéyàwó tí ìyá ìyàwó ti máa ń ṣe oríṣìí oúnjẹ 100 fún ọkọ ìyàwó

Oríṣun àwòrán, Anupama Ramakrishna
Airin jina lai ri abuke ọkẹrẹ, ase igbeyawo kan ree ti iya iyawo ti maa n se oriṣii ounjẹ ọgunrun un fun ọkọ iyawo laarin ogoji ọjọ.
O ti to ẹẹdẹgbẹrin ọdun ti tawọn eeyan Mappila lapa guusu orilẹede India ti maa n ṣe eleyii gẹgẹ aṣa wọn.
Sise oriṣiiriṣii ounjẹ nibi eto igbeyawo wọpọ lorilẹede India.
Amọ, ninu gbogbo ase eto igbeyawo ni India, ko si eyi to rinlẹ tabi lamilaaka bii Puyyappla Perukkal, eyi tawọn musulumi Mappila maa n ṣe niluu Keralan ni Thalassery.
Thalassery jẹ ilu kan to wa leti okun ti ọpọ eeyan kii foju si lara.
Bo tilẹ jẹ pe oriṣii aṣa lo maa n jẹyọ nibi eto igbeyawo ni India, amọ, ọtọ ni ti aṣa igbeyawo awọn musulumi Mappila lapa guusu India jẹ.

Oríṣun àwòrán, Anupama Ramakrishna
Eto naa ti wọn n pe ni Puyyappla Perukka (eyi to tumọ si itọju ọkọ ọmọ eeyan), aṣa yii lo maa n jẹ ki ọkọ iyawo gbe nile iya iyawo rẹ nibi ti wọn yoo ti se oriṣii ounjẹ ọgọrun un fun un.
Ogoji ọjọ ni ọkọ iyawo yoo fi wa nile iya iyawo rẹ gẹgẹ bi alejo pataki to wọn n tọju.
Awọn musulumi Mappila maa n ṣe eleyii ki ibaṣepọ to dan mọran le wa laarin ẹbi ọkọ ati ẹbi iyawo.
Ninu aṣa awọn eeyan Mappila, gbigba ọkọ iyawo lalejo jẹ nnkan iyi, ati ogoji ọjọ ninu ẹsin islam tun ṣe pataki laarin awọn musulumi Mappila tori Ibukun lo tumọ si i.
Oniruuru ounjẹ ni wọn maa n gbe fun ọkọ iyawo lati ọjọ keji iyawo.

Oríṣun àwòrán, Alamy
Lẹyin ti ọkọ iyawo ba ti jẹun aarọ tan lo maa n lọ sile rẹ, alẹ lo maa pada lati tun wa jẹ oriṣiiṣii ounjẹ nile iya iyawo rẹ.
Ounjẹ ọsan ati ounjẹ alẹ lo n maa n fẹsẹ mulẹ julọ.
Ti o ba ti di ọsẹ keji, adiẹ yiyan atwọn ounjẹ mii lo maa n pọ ninu ounjẹ alẹ ti ọkọ iyawo maa n jẹ.

Oríṣun àwòrán, Alamy
Bi gbogbo ounjẹ yii ṣe pọ to, wọn kii saba se ẹja ayafi ti ọkọ iyawo funra rẹ ba fi owo diẹ silẹ lati se e loku.
Ọkọ yoo fun iyawo rẹ lowo lati fun mama tiẹ lowo lati le se ounjẹ naa.
Bakan naa, pipo ''tea'' nilo afikun owo lati ọwọ ọkọ iyawo, eyi si jẹ aṣa to tumọ si bibu ọla fun ara ẹni.
Ọgbẹni Khadeeja TC ṣalaye wi pe ọkọ iyawo le binu nigba miran kọ ounjẹ silẹ ti yoo si fi ibinu jade ti ounjẹ naa ko ba tẹ ẹ lọrun.
Amọ, awọn mọlẹbi ni wọn maa da a pada si ile iya iyawo rẹ lati maa n jẹun lọ.
Bo tilẹ jẹ pe laarin awọn eeyan Mappila ni ase igbeyawo ti maa n ṣaba wa sile, awọn arinrinajo naa si le ri iru ounjẹ bẹẹ jẹ.
Yatọ si pe nibi ase igbeyawo ti wọn n pe ni Puyyappla Perukkalat to ti bẹrẹ lati ọdun 1866 ni Thalassery, wọn si tun n ta ounjẹ Mappila yii ni ile ounjẹ bii Paragon niluu Kozhikode, Kochi ati Thiruvanthapuram, to fi mọ UAE, ati Malabar ni London.















