Kí ló dé tí Israel fí fi ọmọ-ọmọ Nelson Mandela sí àhámọ́ tí Ààrẹ Ramaphosa sì ń pàríwo?

Cyril Ramaphosa ati Nkosi Zwelivelile Mandela

Oríṣun àwòrán, Per-Anders Pettersson/Getty Images and Leon Neal/Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ orilẹede South Afrika, Cyril Ramaphosa ti kesi ijọba orilẹede Israel pe ki wọn tu awọn ọmọ orilẹede South Africa ati awọn ọmọ ẹya mii ti wọn nawọ gan lasiko ikọlu Global Sumud Flotilla.

Ninu atẹjade kan ti ọfiisi aarẹ fi soju opo ayelujara Aarẹ lọjọ keji oṣu kẹwaa ọdun 2025, ni Aarẹ Ramaphosa ti ni ikọlu to waye ni agbegbe omi ni Gaza tako ofin agbaye, to si n fa inira fun awọn eeyan Palestine.

Flotilla jẹ ọkọ oju omi ti wọn lọ fi n pese eroja aanu ati ohun iranwọ ti wọn n gbe lọ si Gaza.

Aarẹ Ramaphosa ni awọn ọmọ South Africa wa lara awọn eeyan ti wọn ko ni flotilla, to fi mọ Nkosi Zwelivelile Mandela, to jẹ ọmọ-ọmọ Nelson Mandela; Zukiswa Wanner ati Reaaz Moolla.

O ni awọn ko ti le fidi rẹ mulẹ lori ijinigbe Zaheera Soomar, Fatima Hendricks ati Carrie Shelver".

Ọpọ awọn ajafẹtọ ọmọniyan, to fi mọ lati orilẹede Sweden Greta Thunberg, ni awọn ọmọ ologun Israel ti mọlẹ.

"Ikọlu Global Sumud Flotilla tun jẹ ẹṣẹ nla lati ọwọ ijọba Israel lati ṣe idaduro ohun ti wọn fẹ gbe wọ ilẹ Gaza ati lati ri pe alaafia jọba ni agbegbe naa.

"Pẹlu aṣẹ lati ọwọ ijọba ati orilẹede wa, mo n pe ilẹ Israel lati tu gbogbo awọn ọmọ orilẹede South Africa ti wọn lori omi agbaye silẹ, ki wọn si tun tu awọn eeyan to n gbiyanju lati pese iranlọwọ fun Gaza silẹ," atẹjade naa ṣalaye.

"Igbesẹ yii tako ofin agbaye to faye gba ki iranlọwọ ma wọle lai si ija ni awọn asiko bayii," Aarẹ Ramaphosa.

Ki ni orilẹede Israel sọ?

Ẹwẹ, ileeṣẹ to n risi ọrọ oke okun ni Israel ti ni awọn ti ọwọ tẹ ni Global Sumud Flotilla, ni wọn tig be lọ si ẹnu ibode Israel lati da wọn pada si ilu wọn.

Israel ni awọn ọmọ ogun ori omi sọ fun awọn eeyan yii ki wọn kuro ni agbegbe wọn ṣaaju ki ọwọ to tẹ wọn.

O to eeyan 433 ti wọn ti mọle lati inu ọkọ oju omi, ti wọn si fẹsun kan wọn pẹ wọn kọju ija si wọn.

Israel ni gbogbo awọn ti awọn ko si ahamọ wa ni alaafia.

Israel ni ohun ti awọn n gbiyanju lati se ni pe ki awọn ohun iranwọ naa ma bọ sọwọ awọn ọmọ ogun ikọ Hamas.

Ki ni flotilla?

Flotilla ni awọn ọkọ oju omi ti wọn n ko awọn ohun iranwọ lọ silu Gaza.

O kun fun awọn eeyan to fi ara wọn jin lati ṣe iranwọ yii, bi ajafẹtọ, dokita ati bẹbẹ lọ.

Ọkọ oju omi flotilla kuro ni orilẹede Spain ni oṣu diẹ sẹyin pẹlu ọkọ oju omi ogoji ni ye pẹlu eeyan to le ni 500.

Gẹgẹ bii Aljazeera ṣe ṣalaye, awọn orilẹede kaakiri agbaye lo kopa ninu flotilla yii to fi mọ Australia, Brazil, South Africa ati ọpọ awọn orilẹede Yuroopu.".