Pẹ̀lú ẹ̀sùn ayédèrú ìwé ẹ̀rí tó ń kun Mínísítà Uche Nnaji báyìí, wo àwọn olóṣèlú tí ẹnu ti kùn lórí ọ̀rọ̀ ìwé ẹ̀rì nígbà kan rí

Awroan Nnaji Buhari, Tinubu ati Jonathan

Oríṣun àwòrán, Uchenna Nnaji/ facebook/getty images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lati igba ti iroyin ti n kaakiri nipa minisita fun imọ ẹrọ ati sayẹnsi lorilẹede Naijiria, Uche Geoffery Nnaji pẹlu ahesọ ọrọ nipa ẹsun pe ayederu iwe ẹri fasiti lo gbe kalẹ lati gba iṣẹ sipo minisita to wa lọwọ; ọpọ eeyan lo ti n beere pe ṣe otitọ ni ọrọ yii abi bawo?

Nigba ti BBC gbe ina woju ọrọ naa, paapaajulọ ohun ti fasiti orilẹede Naijiria, UNN, Nsukka sọ nipa iwe ẹri rẹ ọhun ati ohun to ṣẹlẹ gan ko to di eyi ti gbogbo eeyan n gba bi ẹni n gba igba ọti.

Iwe iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria, Premium Times lo kọkọ jade pẹlu iroyin ayederu iwe ẹri naa lẹyin ti wọn ni awọn kọwe si awọn alaṣẹ fasiti UNN lati mọ boya lootọ ni Minisita naa kẹkọ gboye ni fasiti ọhun.

Orukọ Uche Nnaji ko si ninu iwe awọn to kawe jade ni fasiti wa o – UNN

Fasiti Naijiria, UNN, Nsukka ti sọ wi pe orukọ Minisita imọ ẹrọ ati Sayẹnsi, Uche Geoffrey Nnaji ko si ninu iwe orukọ awọn to kẹkọgboye ni fasiti naa.

Gẹgẹbi awọn alaṣẹfasiti naa ṣe sọ, Fasiti Naijiria, Nsukka ko fun Ọgbẹni Nnaji ni iwe ẹri to n lo lọwọ.

Giwa agba fasiti naa, Ọjọgbọn Simon Ortuanya gbe atẹjade kan sita ninu eyi to ti sọ pe fasiti naa ni ẹri to daju pe pe Ọgbẹni Uchenna Geoffrey Nnaji wọle si fasiti naa lọdun 1981, amọṣa orukọ rẹ ko si lara awọn to kẹkọgboye tabi gba iwe ẹri ni ile ẹkọ giga naa.

Baw oni iwadii naa ṣe bẹrẹ?

Fasiti UNN ṣalaye pe omilẹgbẹ ibeere latọdọ awọn eeyan kan lo mu ki wọn ṣe iwadii lori boya ojulowo ni iwe ẹri Nnaji tabi ayederu.

Ọjọgbọ̀n Ortuanya ṣalaye pe "ọkan lara awọn lẹta ti wọn kọ si fasiti naa lati ọdọ ajọ gbohungbaroye araalu," wọn lọwọ ni ọjọ kẹtala oṣu karun un ọdun 2025.

"Idi niyi ti a fi bẹrẹ iwadii lati ṣe ayẹwo finifini lori awọn iwe wa lati mọ boya fasiti UNN lo fun un ni iwe ẹri naa."

Akọwe agba ile ẹkọ giga naa, Arabinrin F.G. Achiuwa sọ pe iwe iforukọsilẹ akẹkọọ ti wọn fun Nnaji lati bẹrẹ ẹkọ rẹ jẹ 1981/30725.

Ileẹjọ kọ lati da UNN lọwọ kọ lori iwe ẹri Nnaji

Minisita imọ ẹrọ lorilẹede Naijiria, Uche Nnaji.

Oríṣun àwòrán, Uchenna Nnaji/ facebook

Nigba ti fasiti naa ti jade pẹlu atẹjade rẹ lori ọrọ yii ni Nnaji ti gba ile ẹjọ giga nilu Abuja lọ lati ka fasiti naa lọwọ kọ pe ko gbọdọ fi awọn iwe to nii ṣe pẹlu eto ẹkọ rẹ ni fasiti sita fun ẹnikẹni.

Ile ẹjọ ti wa ṣalaye pe oun ko lee ṣe bẹẹ.

Onidajọ Hausa Yilwa to gbe idajọ kalẹ lọjọ kejilelogun oṣu kẹfa, ọdun 2025 da ẹjọ Nnaji nu.

Ta ni Uche Geoffrey Nnaji?

Uche Geoffrey Nnaji ni minisita fun imọ ẹrọ ati sayẹnsi lorilẹede Naijiria. Ipinlẹ Ẹnugu, lẹkun ila oorun gusu orilẹede Naijiria lo si ti wa.

Idile Obed Nnaji, ni ilu Akpugo ni ijọba ibilẹ Nakanu West ni wọn bi i si ni ipinlẹ Enugu.

Oun ni akọbi ọmọ mẹrin ti baba ati iya rẹ bi, ki o to gba ile ẹkọ alakọbẹrẹ Santa Maria Primary School (to ti di Ziks Avenue Primary School,) lọ ni ipinlẹ Enugu.

O ka iwe ẹkọ girama rẹ ni ilẹ ẹkọ girama St Patrick's College, to w ani ilu Emene.

Amọṣa eto ẹkọ iwe ẹri ẹkọ giga rẹ lo di ariwo lọwọ bayii

Awọn oloṣelu to ti ni wahala pẹlu iwe ẹri wọn nigba kan ri

Aworan Buhari, Tinubu ati Jonathan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lorilẹede NAijiria, ọrọ iwe ẹri ko ṣẹṣẹ maa ko awọn oloṣelu sinu hilahilo.

  • Aarẹ Muhammadu Buhari

Aarẹ ana lorilẹede NAijiria, Muhammadu Buhari naa ti wẹ ninu agbami ẹsun ayederu iwe ẹri nigba kan ri nigba ti ẹgbẹ oṣelu PDP beere idi ti ko fi si iwe ẹri idanwo aṣegba girama nini iwe ẹri rẹ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe o papa bori ibo ọdun 2015 nigba naa, amọ lẹyin awijare rẹ, ajọ WAEC fun un ni iwe ẹri miran lati rọpo eyi to sọ pe o sọnu lati fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni Buhari gba iwe ẹri naa lọdun 1961.

  • Aarẹ Bọla Tinubu

Aarẹ Tinubu naa foju wina ẹsun ayederu iwe ẹri lasiko ti awọn kan fi gbe iroyin jade pe ko lọ si ile ẹkọ giga fasiti Chicago state University to n mu iwe ẹri rẹ kiri pe oun lọ. koda oludije ẹgbẹ oṣelu alatako nigba naa, Atiku Abubakar tilẹ lọ si ile ẹjọ lati fi idi eyi mulẹ ki o to di pe ile ẹjọ ati awọn alaṣẹ Fasiti naa sọ pe lootọ ni Tinubu lọ si ile ẹkọ giga Fasiti naa.

  • Dino Melaye

Sẹnetọ Melaye pẹlu ti la iriri ẹsun iwe ẹri ayederu kọja ri lọdun 2017 nigba ti iwe iroyin abẹle kan ni Naijiria, Sahara Reporters fi ẹsun kan an pe ko kẹkọgboye ni fasiti Ahmadu Bello to sọ pe oun lọ

Amọṣa Fasiti naa jade sita lati sọ pe akẹkọjade awọn ni Dino Melaye bi o tilẹ jẹ pe wọn ni awọn aidọgba kan jẹyọ ninu iwe esi idanwo ile ẹkọ giga naa.

Bi o tilẹ jẹ pe Fasiti Havard ati London School of Economics ni kii ṣe akẹkọgboye fasiti awọn nigba naa.

  • Goodluck Jonathan

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan pẹlu ti la agbami ẹsun ayederu iwe ẹri kọja nigba ti aarẹ tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ kede ni gbangba pe Jonathan ko pari ẹkọ oye ọmọwe to n fi kun iwe ẹri ẹkọ rẹ, amṣa fasiti ilu PortHarcourt ti sọ ọ lemọlemọ pe akẹkọgboye imọ ijinlẹ akọkọ, ikeji ati ti ọmọwe ni fasiti awọn ni Jonathan

  • Kemi Adeosun, minisita fun eto iṣuna 2015 - 2018

Lara awọn to ti ni iriri yii ni minisita fun eto iṣuna nigba kan ri, Kemi Adeosun lọdun 2018 nigba ti iroyin jade pe o lo ayederu iwe ẹri agunbanirọ lati gba iṣẹ gẹgẹbi minisita labẹ ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

Lẹyin ọpọ awuyewuye lo kọwe fi ipo silẹ nigba naa.

Stella Oduah

Sẹnetọ ni Stella Oduah ni ile igbimọ aṣofin agba Naijiria ki o to di pe ọrọ iwe ẹri rẹ di ariwo.

Stella Oduah sọ pe oun gba iwe ẹri imọ iṣiro ow oni fasiti St. Paul's College to w ani Virginia lorilẹede Amẹrika laarin ọdun 1978 si 1982 ki aṣiri to tu pe ko lọ rara.