Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọtí Pẹlẹbẹ lè gé ẹ̀mí rẹ kúrú, ó sì tún lè gba ojú lọ́wọ́ rẹ? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Other
- Author, Daniel Gallas, Thomas Pappon & Julia Braun
- Role, BBC News Brasil
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Ijọba orilẹede Brazil ti ṣe ikilọ fun araalu wi pe ki wọn yago fun mimu ọti vodka atawọn ọti lile mii ti ọpọ eeyan mọ si pẹlẹbẹ ni Naijiria.
Iwadii n lọ lọwọ lori bi mimu irufẹ ọti yii ti ṣe okunfa iku eeyan meje kan ṣaaju ọjọ kẹta oṣu Kẹwaa ọdun yii.
Ọpọ eeyan ni iwadii ti fi han pe wọn mu ọti lile to ti ni idọti papaa julọ niluu Sao Paulo to fi mọ ilu Pernambuco ati ẹkun ijọba apapọ lorilẹede Brazil, eyi si ti bẹrẹ lati ọjọ keji oṣu Keji ọdun 2025 yii.
Minisita fun eto ilera ni Brazil, Alexandre Padilha, sọ pe ko si ewu kankan ninu ki eeyan sa fun ọti lile pẹlẹbẹ.
''Kii ṣe nnkan ti o wulo tabi nnkan to le doola ẹmi eeyan la n sọ nipa rẹ.''
Iwadii ti fidi rẹ mulẹ pe kaakiri agbaaye ni ọti lile yii ti n ṣakoba fun ilera awọn eeyan.
Njẹ eeyan le sa fun ọti yii - ati pe ki ni o le ṣe ti o ba ti mu un?

Oríṣun àwòrán, Isaac Fontana / EPA / Shutterstock
Iku ti n pa ni diẹ diẹ
O maa n to ọjọ bii meloo kan ki ọti 'methanol' to pa eeyan.
Itọju ti ko gara le jẹ mimu ọti igo diẹ diẹ pẹlu imọran lati ọdọ onimọ iṣegun loorekoore.
Gbiyanju lati ri dokita ti o ba mu ọti lile ''methanol.''
O ni iye iwọn ti ẹjẹ ẹni to ba n mu ọti lile ''methanol'' gbọdọ wa , eyi lo maa jẹ ki ọti naa kuro ninu agọ ara tan.
Amọ, ọna kan ti wọn maa n ṣaba lo julọ kaakiri gbogbo agbaaye ni fifọ ẹjẹ eyi tawọn oloyinbo maa n pe ni ''kidney dialysis.''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apẹẹrẹ ati ayẹwo
Akoba ti ọti lile pẹlẹbẹ n ṣe ninu agọ ara le ma pọju ti ẹni to n mu un ba tete bẹrẹ itọju ara rẹ.
Eyi si tun le dena iku tabi ki iru ẹni bẹẹ fọ loju tabi ko larun ọpọlọ.
Ọti lile ''methanol'' maa n pa eeyan diẹ diẹ ni,'' gẹgẹ bi Dokita Hovda ti ṣalaye.
Awọn to n mu ọti yii kii tete ri apẹẹrẹ, o maa n to bi ọjọ meloo kan lẹyin ti eeyan ba mu ọti naa tan ki apẹẹrẹ to maa foju han.
Awọn to ba ti mu ọti lile yii yoo gan an kii mọ akoba to n ṣe ninu agọ ara wọn, lẹyin bii ọjọ meji ti wọn ba ti mu ọti naa tan ni wọn ṣẹṣẹ maa mọ ọn lara.
Nnkan miran ni pe apẹẹrẹ ti ẹni ti o ba mu ọti lile ''methanol'' ba n ri fara jọ apẹẹrẹ awọn aisan mii.
Bakan naa lo maa n dabi ẹni pe o kan rẹ eeyan ni.
Wọnyi lawọn apẹẹrẹ ti ẹni to ba mu ọti lile ''methanol'' maa n kọkọ ri:
- Ki inu maa dun eeyan
- Aya riro
- Ailemi daadaa
Awọn apẹẹrẹ mii bii airiran daadaa to fi mọ ki eeyan fọ loju patapata le jẹ jade to ba ya.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi eeyan ṣe le sa fun mimu ọti lile ''methanol''
Ileeṣẹ to n pọn ọti ni Brazil ti pin awọn imọran yii:
- Ri wi pe o ra ọti nibi to ni igbẹkẹle ninu wọn
- Fura ti iye ti wọn ba n ta ọti ba ti lọ ilẹ ju
- Yago fun ọti to ba ni idọti ninu
- Beere fun iwe ọja ti o ba ti ra ọja tan lati mọ nipa ibi ti wọn ti n ra ọja
- Wo ẹnu igo ọti naa bo ya wọn ti ṣi i, o ṣee ṣe ki idọti wa nibẹ

Ajọ MSF, awọn dokita to maa n ṣiṣẹ kaakiri agbaaye fidi rẹ mulẹ pe akọsile sọ pe ọti methanol ti pa ẹgbẹrun mérinla eeyan lagbaaye.
Bakan naa tun ni ẹgbẹ awọn dokita sọ pe eeyan to le lẹgbẹrun lọna ogoji lo ni akọsilẹ awọn eeyan ti mimu ọti ''methanol'' n da laamu.
Orilẹede Indonesia lo lawọn eeyan to n ṣaisan latari mimu ọtim lile pẹlẹbẹ pẹlu eeyan 334.
Ọkan lara awọn dokita ajọ MSF, Knut Erik Hovda, to jẹ dokita ọmọ orilẹede Norway ti ṣe iwadii lori aisan ti majele inu ọti methanol fun ogun ọdun.
O sọ fun BBC wi pe o ṣe pataki lati maa sọ fawọn eeyan nipa ọti ti idọti ti wa nibẹ, ki wọn le tọju ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Stringer / AFP via Getty Images
O le ni ẹgbẹrun kan eeyan to dero ile iwosan lọdun 2013 ni Libya lẹyin ti wọn mu ọti pẹlẹbẹ methanol tan.
Mọkanlọgọrun un lo lo ku ninu awọn eeyan yii.
O le ni aadọrin eeyan to ku ni Russia loṣu Kejila ọdun 2016.
Ni orilẹede Kenya:
.Eeyan 126 lo ku latari aisan to ṣe eeyan 467 léyin ti wọn mu ọti pẹlẹbẹ.
'Lọdun 2005, ọpọ eeyan lo tun padanu ẹmi wọn lẹyin ti wọn mu ọti ti methanol wa ninu rẹ.
Lọdun 2000, eeyan 140 lo ku ti ogun ko si riran mọ ninu awọn 400 to dero ile iwosan lẹyin ti wọn mu ọti lile naa tan.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Itọju
Ẹgbẹ awọn dokita kaakiri agbaye, MSF, n fawọn dokita ni idanilẹkọọ lori ọna ati ṣe itọju fawọn to ba mu ọti methanol to ni majele.
Wọn maa n pin fidio ti wọn fi n rọ awọn eeyan lati wa itọju ti ọti ti wọn ba mu naa ba ti n yọ wọn lẹnu.
Dokita Hovda sọ pe ''ọpọ eeyan to ba tete wa itọju laarin ọjọ kan ti wọn bẹrẹ si ni ri apẹẹrẹ ailera latari ọti pẹlẹbẹ ti wọn mu ni yoo ri iwosan.
Awọn naa si le ru u la laarin ọjọ meji si mẹta ti wọn ba ri apẹẹrẹ yii.
Iye igba ti ọti yii le lo ninu ara eeyan ki o to le ṣakoba fun ara niyẹn.''

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Nnkan to n ṣiṣẹ lodi
Dokita Hovd ni oogun to n ṣiṣẹ tako ọti lile yii ninu ara, fomepizole, ko din ni $1,200 fun eyi ti eeyan le lo lẹẹkan pere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ awọn dokita MSF lagbaaye fi oogun fomepizole sara awọn oogun ti ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO, ka kun ko ṣee ma ni kawọn eeyan le maa ri i ra kaakiri gbogbo agbaye.

Oríṣun àwòrán, Isaac Fontana / EPA / Shutterstock
Ọti pẹlẹbẹ ti ko wọn
Bi wọn ti n ko ọti lile mẹthanol kaakiri agbaye ti pọ si i, tori wọn maa n lo o fun epo latari wi pe o dara fun ayika je epo bẹntiroolu ati disu lọ.
''Awọn eeyan maa n po ọti methanol pọ mọ awọn ọti mii lati ri owo gọbọi.
Ti o ba da omi pọ mọ ọti ti o si gbe e sori tabili, iwọ gan an maa ri pe iyapa yoo wa laarin nnkan mejeeji.
Ṣugbọn o ko le ri iyapa laarin methanol ati ọti miran, bakan naa lo maa n run pẹlu ọti mii.
Nitori naa, o nira fun ẹni to ba mu un lati mọ nnkan ti o n mu,'' Dokita Hovda lo sọ bẹẹ.












