"Gbogbo owó tí Nnaji mínísítà tó kọ́wé fipò sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn lílo ayédèrú ìwé ẹ̀rí ló yẹ k'íjọba gbà padà"

Aworan Uche Nnaji

Oríṣun àwòrán, X/Chief Nnaji

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Minisita fun imọ Sayẹnsi ati imọ ijinlẹ, Uche Nnaji ti kọwe fipo silẹ lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o lo ayederu iwe ẹri lati fasiti orilẹede Naijiria Nsukka, UNN.

Nnaji ni b'oun ṣe kọwe fipo rẹ ki i ṣe pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun pe ayederu ni iwe ẹri fasiti ati iwẹ ẹri fun agunbanirọ oun.

O si n tenu mọ pe oun kawe gboye lati fasiti UNN lọdun 1975, ti iroyin kan si ni ile ẹkọ naa ko le fidi iwe ẹri naa mulẹ.

BBC News Yoruba ba minisita tẹlẹ ri, Wole Oyelese, sọrọ lori ohun to yẹ ki eeyan ni ṣaaju ko to di minisita ati igbesẹ to yẹ ki ijọba gbe lori ọrọ naa.

Oyelese ni Nnaji ko sẹ si ofin lasan, ṣugbọn ko tun huwa Omoluabi pelu awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

"A wa ko ri iru nnkan bayii ri lasiko ti wa, gẹgẹ bii agbẹjọro, ẹni ti wọn ba fẹ fun ni oye minisita ni igbagbọ wa pe iru eeyan bẹ jẹ olotitọ eeyan, to ni ibọwọ fun ofin.

"O rọrun lati di Gomina lai ni iwe ẹri ju ki eeyan fẹ di minisita lai si iwe ẹri.

O fi han pe o ti lọ kaakiri lati wa ojutuu si ọrọ iwe ẹri rẹ.

O se ni laanu ṣugbọn otitọ da bi oyun, o ko le fi bo rara."

Oyelese ni o ṣe koko ki ijọba gbe igbesẹ lori ọrọ naa lati le jẹ ki o jẹ ẹkọ fun awọn eeyan mii to fẹ yi iwe ẹri wọn lati fi gba ipo lọwọ ijọba.

"Ti o ko ba ni iwe ẹri, ma dibo, ma gbiyanju lati yi iwe, akoko si wa lati pada lọ si ile ẹkọ lati lọ gba iwe ẹri yii.

"Ijiya wa fun yiyi iwe ẹri, ko da ti o koba sipo, jẹ ẹsun nla lorilẹede Naijiria, to si le gba ibẹ ri ẹwọn he.

"O yẹ ko san gbogbo owo oṣu to ti gba pada fun ijọba lẹyin to ba fojuba ile ẹjọ."

Wo awọn oloṣelu to ti padanu ipo nitori iwe ẹri

  • Kemi Adeosun

Ni ọdun 2018, Ijọba apapọ orilẹede Naijiria kede pe minisita fun eto isuna lasiko naa, Kemi Adeosun kọwe fipo silẹ lẹyin ọdun mẹta ni ọfiisi.

Idi ti Adeosun fi kọwe fipo silẹ ni iwadii fi han pe ayederu ni iwe ẹri agunbanirọ ti o lo fi gba ipo minisita.

Lasiko naa, Aarẹ ana to di oloogbe, Muhammadu Buahari lo wa ni ipo, to si ni oun gbe igbesẹ nitori ẹsun naa le ṣe akoba fun saa keji aarẹ ati eto idibo ọdun 2019.

Ni oṣu Kẹsan an ọdun 2018, Aarẹ Buhari tẹwọ gba lẹta ifiposilẹ naa.

Ẹsun ti wọn ka si Adeosun lọrun ni pe o lo ayederu iwe ẹri ṣugbọn o yege ayẹwo ile igbimọ aṣofin lasiko ti wọn fẹ yan gẹgẹ bii minisita.

  • Salisu Buhari

Iṣẹlẹ yii mi titi lorilẹede Naijiria lọdun 1999, nigba ti Salisu Buhari ko sinu kaṣala iwe ẹri.

Salisu Buhari ni olori ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja lasiko naa, to jẹ asọfin laarin ọdun 1999 si 2000.

Kete to de si ọfiisi naa ni wahala bẹrẹ nipa ọjọ ori rẹ ati iwe ẹri to lo jẹ ayederu.

O ni oun lọ si ilẹ ẹkọ fasiti Toronto, to si kawe gboye ṣugbọn iwe ẹri diploma lo ni dani, eyi lo si fa a to fi kọwe fipo rẹ silẹ.

  • Biobarakuma Degi-Eremienyo

Ni ọdun 2019, ile ẹjọ giga kan ni Abuja wọgile igbakeji oludije gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Sẹnẹtọ Biobarakuma Degi-Eremienyo pe ko ni anfani lati kopa ninu eto idibo gomina to waye ninu oṣu kọkanla ọdun 2019.

Idi ti ile ẹjọ fi wogile Degi-Eremienyo ni pe gbogbo ohun to fi ṣe iforukọsilẹ pẹlu INEC lati dije ipo naa lo jẹ ayederu

Degi-Eremienyo jẹ akẹgbẹ David Lyon, ti wọn jọ fẹ di gomina ati igbekeji gomina nipinlẹ Bayelsa

Nigba ti Lyon bori ninu eto idibo tan, ile ẹjọ kede pe igbakeji rẹ lo ayederu iwe ẹri.