May Agbamuche-Mbu di adelé alága INEC, wo àwọn nǹkan tó yẹ kóo mọ̀ nípa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, X/INEC
Kọmiṣọna fun ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria INEC, May Agbamuche-Mbu ti gba ipo gẹgẹ bii adele alaga ajọ eleto idibo.
Igbesẹ yii waye lẹyin ti Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, gbe ọpa aṣẹ fun- un, to si lọ fun isinmi.
Ikede yii waye lọjọ Isẹgun ni ọfisi INEC niluu Abuja lasiko ipade pẹlu awọn kọmisana ajọ INEC.
Agbamuche-Mbu jẹ agbẹjọro to ni ọpọ iriri, ti iyansipo si waye lasiko ti orilẹede Naijiria nilo eeyan ti yoo tubọ tukọ itẹsiwaju ajọ INEC.
Ilu Kano ni wọn ti bi Agbemuche-Mbu ṣugbọn o wa lati ipinlẹ Delta. Igbeaye rẹ bẹrẹ ni apa ariwa orilẹede Naijiria, eyi to ṣafihan ifẹ rẹ si isọkan Naijiria
O lọ si ile ẹkọ girama St. Louis niluu Kano, to si tun lọ si fasiti ile ife, ti a mọ si Ọbafemi Awolowo bayii nibi to ti kawe gba oye nipa imọ ofin ni ọdun 1984.
Arabinrin Agbamuche jẹ ọkan lara awọn kọmiṣọna agba lajọ INEC, oun si lo n mojuto awọn ipinlẹ Delta, Edo ati Cross Rivers.
Eekan agbẹjọro ni, bakan naa lo tun jẹ akọroyin to lo ọpọlọpọ ọdun lati kọ awọn iroyin to ba jẹ mọ ofin ati ẹka ofin. O si ti ni iriri to le lọgbọn ọdun lẹnu iṣẹ ofin, akoso ilu.
O kẹkọgboye imọ nipa ofin ni fasiti Ile Ifẹ to ti wa di Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ nilu Ile Ifẹ, ko to gba aṣẹ lati ṣiṣẹ agbẹjọro lọdun 1985 ki o to gba ipo agbẹjọro niwaju ileẹjọ to ga julọ lorilẹede England ati Wales.
Ki o to darapọ mọ ajọ INEC, oun ni ọga agba ileeṣẹ amofin Norfolk Partners ni ilu Eko, bẹẹ lo tun jẹ akọwe fun ajọ awọn akọṣẹ̀mọṣe alagbawi ilẹ UK lorilẹede NAijiria (Chartered Institute of Arbitrators (UK), Nigeria Branch).
Agbamuche-Mbu ni wọn kede gẹgẹ bii Kọmisana fun ajọ INEC ni ọdun 2016, to si ti kopa ribiribi ni ajọ naa lasiko to ti bẹrẹ iṣẹ.
Latigba to ti de INEC, Agbamuche- Mbu ti ṣe alaga ẹka nipa ofin ati gbohungbaroye araalu. Ẹka yii ko ipa ribiribi lori titẹle ofin ilana idibo lẹka oṣelu Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















