Àwọn ọ̀dọ́ l'Oyo ṣèwọ́de tako rira epo láti ilẹ̀ òkèèrè, béèrè ààbò fún iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote

Awọn ọdọ ti ọpọ ninu wọn jẹ akẹkọọ niluu Ibadan ṣe iwọde alaafia lati fi aidunnu wọn han si bii ẹgbẹ oṣiṣẹ PENGASAN, DAPPMAN ati NUPENG ṣe n ta kangbọn pẹlu ileeṣẹ ifọpo Dangote.
Awọn ọdọ naa pejọ ni agbegbe Iwo road pẹlu orisiirisii ilewọ ti wọn ko ọpọ ọrọ bii "ile iṣe Dangote pese iṣe fun awọn ọdọ, ẹ ma pa ile iṣe ifọpo Dangote'' si ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Iwọde naa to bẹẹrẹ lati opopona Iwo road ni awọn ọdọ naa gbe lọ si ileeṣẹ ijọba Ipinlẹ Oyo to wa ni agbegbe Agodi niluu Ibadan.
Ninu ọrọ rẹ, Benedict Adetunji to jẹ aladari ẹgbẹ awọn akẹkọọ to ṣe iwọde naa, sọ pe lati igba pipẹ ni awọn ẹgbẹ kan ti n gbiyanju lati ma ṣe jẹ ki ileeṣẹ ifọpo Dangote siṣẹ.
O tẹsiwaju wi pe pẹlu igbese ẹgbẹ PENGASAN, DAPPMAN ati NUPENG, o ti fi han wi pe awọn kan fẹ ki awọn ọmọ orile-ede Naijiria maa jiya.
Adetunji ni bii epo robi ṣe pọ to lorileede Naijiria, ko yẹ ki awọn ọmọ orile-ede naa maa jiya ki wọn to ri epo bentiroolu ra.
O fikun ọrọ rẹ pe ọpọ ọdọ orile-ede Naijiria ni ile iṣe Dangote ti gba ṣíṣe.
Ọgbẹni Adetunji wa rọ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati ri wi pe ileeṣẹ ifọpo Dangote n ri epo rọbi ra, ki Aarẹ si mu opin ba rira epo bentiro lati oke okun.
Ninu ọrọ tiẹ, Sunday Odukoya to jẹ amugbalẹgbẹ Gomina Seyi Makinde lori ọrọ to nise pẹlu aabo rọ awọn ọdọ naa lati ma se jẹ ki awọn janduku gba iwọde naa mọ won lọwọ.
O wa ṣeleri lati fi iwe ti wọn kọ ransẹ si Gomina Ipinle Oyo jiṣẹ fun un.
Ti ẹ o ba gbagbe, ede-ai-yede bẹ silẹ laarin ẹgbẹ PENGASSAN ati ileeṣẹ ifọpo Dangote ti ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC, sì ke si awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati maa mura silẹ fun iyanṣelodi.
Amọ, awọn asoju ijọba apapọ ati awọn oṣiṣẹ ti gbiyanju lati yanju ọrọ naa.















