Òkùnkùn birimù yóò gbòde láwọn agbègbè kan l'Eko lópin ọ̀sẹ̀ yìí, TCN kéde

Aworan ẹrọ amunawa

Oríṣun àwòrán, X/TCN Nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n risi ipese ina mọnamona lorilẹede Naijiria, TCN ti kede pe ko ni si ina mọnamọna ni awọn agbegbe kan nipinle Eko.

TCN ni ninu atẹjade kan ti wọn gbe soju opo ayelujara wọn ṣalaye pe igbesẹ yii n waye nitori atunṣe si ohun imunawa ti Ajah/Lekki 330kV ti yoo fun wọn ni anfani lati ṣe ifilọlẹ ẹrọ amunawa idabono sori 300MVA 330/132/33kV ni ileeṣẹ amunawa to wa ni Alagbon.

Ndidi Mbah, agbẹnusọ ajọ TCN ni atunṣe yii yoo parọ ọpọ awọn waya lori ẹrọ amunawa Ajah/Alagbon and Ajah/Lekki 330kV.

Ki ni yoo fa okunkun birimu lawọn agbegbe ti ọrọ kan?

Mbah ni lasiko atunṣe yii, ina mọnamọna to n wa lati ileeṣẹ amunawa Alagbon ni wọn yoo gbe lọ si Ijora 132kV line, nigba ti ileeṣẹ to n pi ina ni Akoka ati Oworo ni wọn yoo gbe lọ si Ikeja-West 132kV line.

"Ko ni si ina fun wakati mẹjọ fun awọn agbegbe to n gba ina lati Ajah/Lekki 330kV bẹrẹ lati ago mẹwaa si ago mẹfa irọlẹ ni ọjọ kọkanla oṣu Kẹwaa, ti awọn agbegbe Ajah/Alagbon yoo si waye ni Ọjọ kejila, kejidinlogun ati kọkandinlogun ọdun 2025.

TCN ni awọn tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan agbegbe ti ina mọnamọna yoo ti ṣafẹrẹ ni Lekki We apologize for any inconvenience this may cause electricity customers in Lekki, Jakande, Ikoyi ati awọn agbegbe yooku lasiko yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post