Èèyàn mẹ́tàlá kú, àwọn mii farapa lẹ́yìn táwọn afurasí janduku agbébọn ṣe ìkọlù sí ilé ìwòsàn kan

Aworan bi ile iwosan tawọn afurasi janduku sẹ ikọlu si sẹ bajẹ to

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan eeyan mẹtala lo ti padanu ẹmi wọn ni ile iwosan kan ni el-Fasher lorilẹde Sudan lasiko tawọn janduku agbebọn kan ṣe ikọlu sile iwosan ọhun.

Awọn mẹrindinlogun mii ti dokita kan ati nọọsi kan wa lara wọn lo farapa ninu iṣẹlẹ naa.

Ajọ RSF (Rapid Support Forces (RSF) to jẹ ẹṣọ eleto abo alatako lo kọkọ se wọn mọ ile iwosan naa lai moye igba lọjọ Iṣẹgun to kọja.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ eleto ilera kan ṣapujuwe ikọlu naa gẹgẹ bi iwa ọdaran lasiko ogun.

Aworan lati ile iwosan naa ṣafihan ferese ti ado oloro bajẹ ati iho to da lu sara ogiri ile iwosan naa.

Ajọ RSF ti n ṣọ ile iwosan naa fun bii oṣu mẹtadinlogun ti ebi si se ọgọọrọ eeyan mọle.

Ikọ ọmogun ti kii ṣe ti ijọba n kọju ija si ileeṣẹ ologun Sudan lati le maa ṣakoso el-Fasher to jẹ ibudo iko nnkan ogun si to ku ni ẹkun Dafur.

Igba keji ree ti wọn yoo ṣe ikọlu si ile iwosan Saudi Hospital, oṣu kinni ọdun yii ti wọn ni wọn kọkọ wa ti wọn si gbẹmi si ṣeku pa eeyan mẹta ti eeyan mẹta mii si farapa nibẹ.

Lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin bayii ni ajọ RSF tun ti tẹsiwaju ikọlu wọn si el-Fasher.

Igun mejeeji ti jọ ko ipa ri ninu ogun abẹle, nibi ti ẹgbẹlẹ eeyan ti ku.

Lọjọ Iṣẹgun to kọja ni iroyin fidi ẹ mulẹ pe ẹgbẹ RSF ti kọ odi yi el-Fasher ka lati jẹ ko nira fun araalu lati salọ.

Gbogbo ọna nla nla ni wọn ti di pa, awọn arinrinajo si n njẹri wi pe wọn n dawọn lọna, wọn n si n gba oriṣii nnkan lọwọ awọn.

Ija yii naa to n lọ lọwọ lo ti jẹ ki ọpọ oṣiṣẹ ati ileeṣẹ eleto ilera niluu naa maa kogba sile..

Koda, wọn tun dena wọn awọn oṣiṣẹ alaanu to n gbe ounjẹ ati eto ilera bọ.