Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Adunni Ade táwọn èèyàn fi ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ayélujára? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Adunni Ade@Facebook
Adunni Adewale, gbajumọ oṣerebinrin Yoruba ti ọpọ eeyan mọ si Adunni Ade, ti fi idunnu rẹ han lori ẹjọ ti kootu da laipẹ yii, eyi to ni oṣere naa ko ni ifẹ ikọkọ kankan pẹlu Senetọ Dino Melaye, gbajumọ oloṣelu Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe ọdun keji ree ti ẹjọ naa ti wa ni kootu, Adajọ I.O. Harrison, ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko ti da a bayii, pe Adunni Ade ko si lara awọn oṣerbinrin mẹfa kan ti wọn ni Dino Melaye n ba da ọrẹ ikọkọ.
Ẹka iroyin NaijaNews.com titled, lo gbe iroyin kan jade nigba naa, ninu eyi to ti ni Adunni Ade naa wa lara awọn oṣere tiata ti Seneto Melaye n ba ṣe ere ifẹ.
Iroyin naa lo bi Adunni Ade ninu to fi gbe igbesẹ ofin, to gba kootu lọ.
Oṣere ọmọ Yoruba ti wọn bi si ilẹ America ọhun sọ nigba naa, pe irọ pata ni iroyin yii.
O ni o le ṣi eeyan lọna, o si tun n mu inu bi eeyan yatọ si pe o tẹ ẹtọ oun loju mọlẹ bii ọmọniyan.
Adunni Ade sọ pe iroyin naa ko ibanujẹ ati irẹwẹsi ọkan ba oun, awọn to si gbe e jade ko ṣe iwadii tabi beere ohunkohun lọwọ oun ki wọn too gbe e jade lati fi wa ero si oju opo wọn.
Lati oṣu kin-in-ni ọdun 2023 naa ni ọrọ ọhun ti wa ni kootu, ti igbẹjọ si n waye lori rẹ titi ti adajọ fi pada da a.
"Mo jàre ẹjọ́ mi''

Oríṣun àwòrán, Adunni Ade@ Facebook
Nigba to n kede ijawe olubori rẹ lori ẹjọ naa lọjọ Iṣẹgun loju opo Instagram rẹ, Adunni Ade kọ ọ sibẹ pe:
"Mo jare ẹjọ mi, wọn kọ iroyin irọ nipa mi, ṣugbọn ododo leke. Idajọ yii tun fidi ẹ mulẹ pe ko yẹ ki eeyan maa nagi imu si ọrọ ọlọrọ, ati pe pataki ni jijẹ ọmọluabi.
" Bi idajọ tiẹ pẹ ko too waye, ko tumọ si pe ko ni i de lọjọ kan."
Bakan naa ni Adunni Ade dupẹ lọwọ lọọya rẹ to gba ẹjọ naa ro fun un to fi jare.
Bẹẹ lo sọko ọrọ si oṣerebinrin ẹgbẹ rẹ kan ti ko darukọ.
" Si iwọ oṣerebinrin bii temi, to o sọ ohun ti ki i ṣe otitọ fun Cutie Jules, ko buru, laipẹ aye yoo mọ iru ejo ti o jẹ.
"Ikorira ati inunibini n gbe inu rẹ. Ikupani ni ẹ! O jọ pe o ti gbagbe ohun ti o fi han mi ninu yara mi?"
Ọpọ awọn ololufẹ oṣerebinrin naa lo ti n ba a yọ lori are to ba bọ ni kootu naa, wọn ni bi irọ ba lọ logun ọdun, ọjọ kan ṣoṣo ni otitọ yoo ba a.















