Aráàlú rọ òjò òkúta lé ọkọ̀ tó gbé ààrẹ nítorí yíyọ owó ìrànwọ́ orí epo 'subsidy'
Aráàlú rọ òjò òkúta lé ọkọ̀ tó gbé ààrẹ nítorí yíyọ owó ìrànwọ́ orí epo 'subsidy'
Awọn eeyan ju okuta lu ọkọ to n gbe aarẹ orilẹede Ecuador, Daniel Noboa kọja.
Aarẹ naa atawọn to n ba a kọwọrin n kọja laarin igboro ni nigba ti awọn aaraalu kan ti wọn to ẹẹdẹgbẹta bẹrẹ si ni ju okuta lu ọkọ to wa pẹlu awọn ti wọn jumọ kọwọ rin.
Ọkan lara awọn minisita ninu iṣejọba aarẹ Noboa tilẹ ṣalaye pe wọn tilẹ tun ri oju ibọn lara ọkọ naa.
Minisita naa ṣapejuwe iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bi igbimọran lati pa aarẹ naa ni.
Amọṣa awon onimọ ti BBC ba sọrọ ko le fi idi eyi mulẹ rara.
Nibayii, Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ eeyan marun un lara awọn to ju okuta lu Araẹ Ecuador naa
Ikọlu naa waye lasiko wahala ati iwọde lori ipinnu ijọba orilẹede naa lati yọ owo iranwọ lori epo diesel.



