Agboolé Akọni: Ààrẹ Latoosa, Adẹ́mu ìlú Ilora, to padà di olórí ogun Ibadan, Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfò ilẹ̀ Yorùbá

Àkọlé fídíò, Aarẹ Latoosa
Agboolé Akọni: Ààrẹ Latoosa, Adẹ́mu ìlú Ilora, to padà di olórí ogun Ibadan, Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfò ilẹ̀ Yorùbá

Lara awọn akinkanju to ti rin lori oke erupẹ ilẹ Yoruba ni Aarẹ Latooṣa, ilunIbadan lo si fi ṣe ibujoko.

Agboole Bantu Obudu Oje ni wọn ti bi Ọyatooṣa to yi pada wa di Aarẹ Latooṣa. Oyun ati ibi rẹ jẹ eyi to lagbara pupọ lẹtin ti iya rẹ ko tete rii bi.

Iṣẹ akọpẹ ati adẹmu ni Ọyatooṣa yan laayo.

Orukọ abisọ Aarẹ Latoosa gangan ni Ọbadoke Aṣubiaro Ọyatooṣa. ṣugbọn nigba to darapọ mọ ẹsin Musulumi, lo fi Muhamadu kun un.

Bawo ni Latooṣa ṣe di jagunjagun Ibadan?

Iṣẹlẹ kan lo ṣẹ ni ilu Ilọra to mu ki Latooṣa fi ilu naa silẹ wa si ilu Ibadan.

Nigba to de ilu Ibadan, o tẹsiwaju pẹlu iṣẹ akọpẹ ati ẹmu dida rẹ. Amọṣa, niluu Ibadan, o n da ẹmu, o si n tẹwo fun awon jagunjagun ilẹ Ibadan ko to di wi pe ọkan lara awọn ọrẹ rẹ to sọrọ sii pe iran ẹṣọ kii ta ẹmu, ogun lẹṣọ ja.

Ọrọ yii lo mu Latooṣa darapọ mọ awọn ologun labẹ Bashọrun Ogunmọla.