Ta ni Christopher Kolade, àgbàọ̀jẹ̀ aláàkóso, agbóhùnsáfẹ́fẹ́, tó jáde láyé tí Tinubu, àwọn èèkàn lágbáyé ń dárò?

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ Bola Tinubu ti darapọ mọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati se idarọ, agbaọjẹ agbohunsafẹfẹ, Dokita Christopher Kolade.
Tinubu ṣapejuewe Kolade, ẹni to jade laye lẹni ọdun mejilelaadọrun, gẹgẹ bii ọkunrin to daraju ninu awọn ọkunrin
Ninu atejade ti agbanusọ aarẹ, Bayo Onanuga fi sita, Tinubu kan ṣara ti Kolade, to si oun gbe iroyin iku rẹ pẹlu ibanujẹ ọkan.
Aarẹ ni Kolade sin orilẹede Naijiria pẹlu gbogbo ọkan rẹ ati agbara, to si gba ni adura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.
"Mo gba iroyin iku agbaọjẹ agbohunsafẹfẹ, Dr Christopher Kolade, ọkan ninu awọn ọmọ orlẹede Naijiria to ni ọpọlọ pipe pẹlu ibanujẹ ọkan.
"Dr Kolade, 92, jẹ ọkan gboogi ninu itan wa, paapa ni ẹka ijọba ati titọ eeyan sọna. O tun jẹ eeyan nla ni ile ẹkọ Lagos Business School.
"Ọ jẹ ọkunrin kan to dara ninu awọn ọkunrin. O mọ iwe, to si tun ni ọpọlọ pipe pẹlu iwa irẹlẹ.
Mo nipa Dr Christopher Kolade to di oloogbe
Ninu atẹjade ti mọlẹbi oloogbe gbe sita, wọn ni awọn dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbesi aye Oloogbe, Dr Christopher Kolade.
Atẹjade naa ni oloogbe naa jade laye ni Ọjọru, Ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹwaa ọdun 2025.
Wọn bi Oloogbe ni Ọjọ kejidinlọgbọn ni ilu Erin Oke nipinlẹ Osun, Dr Kolade jẹ eeyan to peyege ni ọpọ nnkan lasiko igbesi aye rẹ.
O jẹ onigbagbọ ti ijọ Anglican, to si lọ si ile ẹkọ girama, Government College niluu Ibadan lẹyin to kuro ni Fourah Bay College, Freetown lorilẹede Sierra Leone.
O gba oye dokita lati fasiti McPherson (2016), Fasiti Sierra Leone (1976) ati bẹẹ lọ.
Kolade siṣẹ ni ọpọ ẹka, bẹrẹ lati jijẹ agbaọjẹ ninu igbohunsafẹfẹ, to si fi igba kan jẹ ọga agba fun ileeṣẹ ijọba Nigerian Broadcasting Corporation (NBC).
Bakan lo tun jẹ alaga ileeṣẹ Cadbury Nigeria Plc, to si tun di ipo Kọmisana Naijiria lọ si orilẹede United Kingdom.















