Ìjọba Eko yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ ìwádìí lórí ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá iná ní ilé gogoro tó mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́wàá lọ

Oríṣun àwòrán, @MUBARAK_YSHAU/X
Ìgbìmọ̀ olùwádìí tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná tó ṣekúpa èèyàn mẹ́wàá ní ilé Afriland Tower ní òpópónà Broad Street ti ní àwọn máa bẹ̀rẹ̀ ìjókòó ní ọjọ́ Iṣẹ́gún, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025.
Adájọ́ Atinuke Adetunji tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwádìí náà èyí tí àgbà olùwádìí ìpínlẹ̀ Eko yàn ló fi èyí léde nínú lẹ́ta kan tó kọ ránṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ agbẹjọ́rò Falana & Falana Chambers.
Ìkéde yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ Falana kọ̀wé ránṣẹ́ sí ọ̀gá àgbà olùwádìí ní ìpínlẹ̀ Eko pé kí wọ́n ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná tó wáyé ní iléeṣẹ́ náà lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025.
Lára iṣẹ́ tí ìgbìmọ̀ olùwádìí náà yóò ṣe ni láti gbé ìmọ̀ràn kalẹ̀ lójúnà àti dènà irúfẹ́ ìjàmbá náà lọ́jọ́ iwájú.
Nínú lẹ́ta tí iléeṣẹ́ Falana kọ lọ́jọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 sọ pé gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ tó máa ń dá ààbò bo àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, mú òfin dúró, ló jẹ́ kí àwọn máa bèèrè fún ìwádìí lórí ìjàmbá náà.
Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 ni ìjàmbá ṣẹ́yọ ní ilé ńlá Afriland Tower, ìpínlẹ̀ Eko níbi tí ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ wà.
Ìròyìn ní èèyàn mẹ́wàá ló jáde láyé níbi ìjàmbá náà tó fi mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ tó ń pawó lábẹ́nú fún ìjọba Nàìjíríà, Federal Inland Revenue Service mẹ́rin àti òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ United Capital mẹ́fà.
Àwọn èèyàn náà ni wọ́n há sínú ilé ọ̀hún lásìkò tí iná náà bẹ̀rẹ̀.
Iléeṣẹ́ Falana ní àwọn ń fẹ́ kí ìjọba ṣe ìwádìí lórí ìjàmbá iná náà èyí tó ṣokùnfà ikú òjijì fáwọn èèyàn náà, kí wọ́n sì sọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi lè dènà irúfẹ́ ìjàmbá bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Èyí ló mú kí ìgbìmọ̀ olùwádìí náà wá fèsì pé àwọn ti gbé ẹjọ́ náà sí ilé ẹjọ́ Kẹsàn-án ní Igbosere èyí tó ń jókòó ní Yaba.
Wọ́n ní ọjọ́ Kẹrìnlá ni ìjókòó àkọ́kọ́ máa wáyé ní ilé ẹjọ́ náà bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́sàn-án.















