EFCC gbẹ́sẹ̀ lé 753 ilé lọ́wọ́ èèkàn òṣìṣẹ́ ìjọba kan ṣoṣo ní Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, EFCC/X
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, EFCC ti sọ pe awọn ti ṣe aṣeyọri nla ti ko wọpọ lati igba ti wọn ti da ajọ naa kalẹ, ati pe iwuri nla lo jẹ fun awọn.
Ninu atẹjade ti EFCC gbe jade soju opo awọn ikanni ayelujara wọn lọjọ Aje, wọn ni dukia olowo iyebiye ti oṣiṣẹ ijọba kan, ti wọn ko darukọ rẹ fi owo jibiti ko jọ lawọn ti gba.
EFCC sọ pe ile-ẹjọ lo paṣẹ pe ki awọn gba dukia naa to wa ni Plot 109 Cadastral Zone C09, Lokogoma District, ilu Abuja fun wọn ninu ẹjọ ti wọn gbe lọ.
Ajọ naa ninu atẹjade wọn sọ pe eyii ni yoo jẹ dukia to pọ ju ti awọn yoo gba latigba ti wọn ti da a silẹ lọdun 2003.
Onidajọ Jude Onwuegbuzie lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 2024 wi pe ki ajọ EFCC gba iṣakoso awọn dukia naa to wa lori ilẹ to to ‘150,500 square metres’.
Awọn ile nla ti apapọ rẹ jẹ 753 kan n ẹni naa n kọ fun tita fun araalu ni ajọ EFCC gbe lọ siwaju ile-ẹjọ.
Wọn ni owo ti oṣiṣẹ ijọba naa ji ko lo fi ko dukia naa jọ, ti wọn si lawọn ko nii laju silẹ lati faaye gba iwa ajẹbanu lati ọdọ ẹnikẹni, lai nii ṣe pẹlu ipo onitọhun.
“Fun apẹẹrẹ, ajọ yii gbojule abala kẹtadinlogun ninu iwe ofin to tako iwe ajẹbanu ni oju-iwe kẹrinla ti ọdun 2006, ati abala kẹrinlelogoji (ipin keji) ninu iwe ofin ilẹ Naijiria la fi gbe ẹjọ naa,” EFCC sọ ninu atẹjade ọhun.
“Ninu idajọ lati gba awọn dukia naa, Onidajọ Onwuegbuzie jẹ ko di mimọ pe oṣiṣẹ ijọba naa ko sọ idi pataki naa ti wọn ko fi gbọdọ gba awọn dukia ọhun lọwọ rẹ, eyi to ti fi han pe ọna eru lo gba ko wn jọ funra rẹ.”
EFCC ni awọn bẹrẹ igbesẹ lati gba awọn dukia ọhun lọjọ kinni, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 niwaju onidajọ kan naa yii, nitori pe oṣiṣẹ ijọba naa lawọn ti bẹrẹ iwadii rẹ tipẹ lori ẹsun jibiti.

Oríṣun àwòrán, efcc/x

Oríṣun àwòrán, efcc/x

Oríṣun àwòrán, efcc/x
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












