Ìdí táwọn oníṣòwò POS ṣe fi N50 kún owó tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn oníbàárà

Aworan ẹrọ POS

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lati ọjọ Aje ọjọ keji oṣu Kejila ọdun 2024 yii lawọn oniṣowo POS ti ṣe afikun owo ti wọn n gba lọwọ awọn onibaara wọn pẹlu N50.

Ọpọ eeyan lo ti n kọminu wi pe ki lo le fa a ti awọn oni POS ṣe fi aadọta naira le owo ti wọn n gba yii lọwọ awọn onibaara to ba ti gba owo ti ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa naira.

Lati ọjọ Aiku ọjọ kinni oṣu Kejila ni awọn banki ori itakun ayelujara ti fi ọrọ naa to awọn onibaara wọn leti wi pe awọn yoo ṣe afikun owo tawọn n gba lori awọn to ba lo oju opo awọn lati gba owo to ba to N10,000 lọ soke tabi lati fi ranṣẹ loju opo ifowo-ranṣẹ awọn.

Alaye lori idi tawọn oni POS ṣe fi N50m le owo ti wọn n gba lọwọ onibaara

Ajọ FIRS to n ri si pipa owo wọle fun ijọba apapọ Naijiria lo gbe alakalẹ naa lelẹ pe awọn banki ori itakun ayelujara bii OPAY, Kuda, Moniepoint, Palmpay ati bẹẹ bẹẹ lọ yoo maa san N50 lori gbogbo owo to ba ti to N10,000 lọ soke.

Eyi lo jẹ kawọn ileeṣẹ naa bẹrẹ si ni sọ fawọn oniṣowo to n lo awọn banki naa nipa alakalẹ ajọ FIRS tuntun lori ati fowo ranṣẹ tabi gba owo lori ẹrọ POS.

Fun apẹẹrẹ, ileeṣẹ banki ori ayelujara Moniepoint kede fawọn onibaara wọn pe ‘’a fẹ ki ẹ mọ pe ajọ FIRS ti sọ pe N50 lawọn yoo maa yọ lori owo to ba ti to N10,000 ti ẹ ba fi ranṣẹ lori ẹrọ ifowo-ranṣẹ ileeṣẹ wa.

Apo ajọ FIRS ni owo yii n lọ, kii ṣe ileeṣẹ Moniepoint lo n gba owo naa.''

Ileeṣẹ Moniepoint tun fidi rẹ mulẹ pe gbogbo owo tawọn onibaara ba fi ranṣẹ tabi gba lori ẹrọ ifoworanṣẹ Moniepoint to ba ti to N10,000 ni ajọ FIRS yoo maa yọ owo yii lori rẹ.

PalmPay naa sọ fawọn onibaara rẹ pe ‘’ni bayii, N50 la o maa yọ lori gbogbo owo ti ẹ ba gba tabi fi ranṣẹ lori ẹrọ PalmPay to ba ti to N10,000 lọ soke.

Eyi wa ni ibamu pẹlu alakalẹ ajọ FIRS to n pawo wọle fun ijọba apapọ.

Lati ọgbọnjọ oṣu Kọkanla ni yiyọ owo ri ti bẹrẹ, ṣugbọn a fẹ ki mọ pe apo PalmPay kọ ni owo yii n lọ.

Apo ijọba apapọ orilẹede Naijiria ni owo yii n lọ, PalmPay yoo tẹsiwaju lati maa fawọn eeyan lanfaani lati maa lo ẹrọ ifowo-ranṣẹ wa lọfẹẹ.

Opay naa ko gbẹyin lẹyin tawọn naa sọ fawọn onibaara wọn pe awọn yoo bẹrẹ si ni maa yọ N50 yii lori gbogbo owo to ba to N10,000 tawọn onibaara awọn ba fi ranṣẹ tabi gba lori ẹrọ ifowo-ranṣẹ awọn lati ọjọ kinni oṣu Kejila yii.