Òṣìṣẹ́ Custom, ìyàwó àti ọmọ mẹ́rin pàdánù ẹ̀mí wọn sínú iná l'Osun

ọmkunrin to duro nibi ina to n jo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Omije bọ loju ọpọ ni owurọ ọjọ Aje nigba ti ijamba ina ṣekupa oṣiṣẹ ajọ asọbode, Tijani Kabiru, ẹni to n sisẹ ni ẹka aṣobode Oyo/Osun, iyawo rẹ ati awọn ọmọ mẹrin ni agbegbe Akankan niluu Ede nipinlẹ Osun.

Ijamba ina to waye ni oru ti sọ agbegbe naa si inu ibanujẹ, to si jẹ ọpọ wọn lo ji ba iṣẹlẹ naa.

Ọkan ninu awọn eeyan to n gbe agbegbe naa ti o pe orukọ ara rẹ ni Kola sọ fun awọn akọroyin pe, oun ko le sọ pato ibi ti ina naa ti wa, "a kan ṣadede ri eefin ni aago mẹta oru".

“Awọn oṣiṣẹ panapana tete de ṣugbọn nnkan ti bajẹ pupọ ki wọn to pa ina naa. Kabiru, iyawo ati ọmọ mẹrin ni wọn jona kọja idamọ. Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ naa ye."

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ panapana nipinlẹ Osun, Ibraheem Adekunle, ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin, s pe awọn ara adugbo fi iṣẹlẹ naa to awọn leti ni deede ago mẹta kọja isẹju mọkanlelogun ni oru ti wọn si sare gba ibẹ lọ.

“Agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye ni Tijani Kabiru Road, ni Akankan ni ijọba ibilẹ ariwa Ede.

“Agbegbe ọhun ni wọn sọ ni orukọ oloogbe naa, ẹni to jẹ oṣiṣẹ aṣọbode.

Ọjọ ori oloogbe wa bi ogoji ọdun, pẹlu awọn ọmọ mẹrin- ọkunrin mẹta ati obinrin kan ti ọjọ ori wọn wa laarin ọmọ ọdun mẹta si mẹwaa.

“Gbogbo ohun to jona ni ile naa lo le ni igba milọnu naira.

“Ọkan ninu awọn ọmọ naa, ọmọ ọdun mẹtala nikan ni ori ko yọ.”