Abàmì àjàkálẹ̀ àrùn wọ DR Congo, pa èèyàn 79

Oríṣun àwòrán, AFP
Ko din ni eeyan mọkandinlọgọrin ti wọn sọ pe ajakalẹ arun kan tẹnikẹni ko tii mọ orukọ rẹ bayii ti ṣeku pa lorileede DR Congo.
Ileeṣẹ to n ṣakoso eto ilera lorileede naa sọ pe apa agbegbe guusu-iwọ-oorun ni ajakalẹ arun (flu-like) buruku naa ti n pa awọn eeyan.
Ileeṣẹ eleto ilera sọ pe awọn ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹẹdogun si mejidinlogun lọ ni wọn pọ ju ninu awọn ti arun buruku ọhun ti ran lọ sọrun lojiji.
Wọn jẹ ko di mimọ pe awọn to ti le ni ọọdunrun ni wọn ti lugbadi arun yii, to si jẹ pe apẹẹrẹ arun onigbameji ti a mọ si ‘flu’ ni wọn n ri lara awọn to ti ko o.
Lara awọn apẹẹrẹ naa ni iba, ori fifọ, imu to n da omi, ikọ, aile min daadaa ati awọn miran lo n ṣẹyọ lara awọn to ti ko o.
Wọn ti ran ikọ eleto ilera lọ si ẹkun Kwango, paapaa ẹkun ilera Panzi (Panzi health zone), nibi ti ajakalẹ arun naa ti wọpọ, lati bẹrẹ sii ṣe itọju awọn to ti lugbadi arun naa, pẹlu iwadii lati mọ ohun to ṣokunfa rẹ.
Cephorien Manzanza, olori ẹgbẹ kan sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe ohun to n ṣẹlẹ yii ti n kọ awọn lominu pẹlu bi awọn to n ko arun naa ṣe n pọ si ni gbogbo igba.
“Panzi jẹ agbegbe igberiko ti ilera, fun idi eyi, wọn n dojukọ iṣoro pupọ nipa riri oogun lati fi tọju ara wọn,” o sọ bẹẹ.
Ajọ eleto ilera agbaye, WHO, ẹka tilẹ Afrika sọ fun BBC pe awọn “ti ran ikọ eleto ilera lọ sagbegbe naa lati gba ẹjẹ awọn to lugbadi arun yii fun ayẹwo.”
Awọn alakoso orileede naa ti wa rọ awọn araalu lati fọkanbalẹ, ki wọn si wa ni ikiyesara.
Wọn rọ awọn araalu lati maa fọ ọwọ wọn pẹlu ọṣẹ ni gbogbo igba, ki wọn si dẹkun ikọrajọ, ati pe ki wọn yẹra lati maa fọwọ kan awọn to ti ku lai duro de awọn oṣiṣẹ eleto ilera.
Iroyin kan sọ pe eeyan to to mẹtadinlaadọrin ni wọn ti dubulẹ aisan, ti wọn si ti ku laarin ọjọ kẹwaa si ọjọ kẹrindinlọgbọn ninu oṣu Kọkanla.
“O yẹ ki ẹ mọ pe ile iwosan Panzi ko ni oogun to le ka awọn eeyan to n lugbadi arun yii. A nilo iranlọwọ gidi,” MP lo sọrọ bẹẹ lori redio Top Congo.
Orileede naa la gbọ pe orisiriṣi ajakalẹ arun bii ‘mpox’ ni wọn ti n koju laarin oṣu Kinni si oṣu Keje, ọdun yii, ti wọn si ti ṣakọsilẹ to to ẹgbẹrun mẹrinla aabọ (14,500) awọn to ti lugbadi wọn.
DR Congo tun ti koju ajakalẹ bii Ebola lawọn ọdun diẹ sẹyin.















