Bàlúù ọmọogun Nàìjíríà tó já ní Benue, ohun tí a mọ̀ rèé

baluu ọmọogun NAijiria kan

Oríṣun àwòrán, nigeria airforce hq/facebook

Baluu ikọṣẹ ti ileeṣẹ ọmọogun ofurufu ilẹ Naijiria kan ja nilu Makurdi, olu ilu ipinlẹ Benue lẹkun aringbungbun ariwa Naijiria.

Gẹgẹ bi iroyin to jade, ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ ijamba naa wayelasiko ti wọn n fi baluu naa ṣẹ ẹkọṣẹ gẹgẹ bi ìṣe rẹ.

Alukoro fun ileeṣẹ ọmọogun ofurufu Naijiria, Ọgagunofurufu Edward Gabkwet fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni baluu ti nọmba idanimọ rẹ jẹ FT-7NI naa ja.

O ṣalaye pe awakọ baluu mejeeji to wa ninu rẹ lori ko yọ, ti wọn si n gba itọju nileewosan ologun kan bayii.

O fi kun un pe ko si ẹmi tabi dukia kankan to ba iṣẹlẹ naa lọ ni I ti balu naa jabọ si.