Kí ló le mú kí ìyá máa tọrọ ikú fún ọmọ rẹ̀ lábẹ́ òfin? Ohun táa mọ rèé

Aworan Nirmala Rana ati ọmọ rẹ, Harish

Oríṣun àwòrán, BBC/Rana family

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

“Bawo ni eeyan yoo ṣe maa beere fun iku ọmọkunrin rẹ?” ibeere ti Nirmala Rana, ẹni ọgọta ọdun n beere ree, nibi to jokoo si lẹgbẹ bẹẹdi ọmọ rẹ, Harish.

Lọdun 2013, Harish, to jẹ akẹkọọ to kẹkọọ nipa iṣẹ imọ-ẹrọ jade lori aja kẹrin ile kan to wa ni ilu Chandigarh, ẹkun Ariwa ilẹ India, to farapa, koda to tun fi ori farapa.

Latigba naa lo ti wa lori bẹẹdi lọsibitu, ti ko si le sọrọ tabi ni imọlara ohunkohun fun ọdun mọkanla – ipo ti awọn dokita pe ni “baaku-baala” (vegetative state).

“A gbe e lọ kaakiri – a gbẹ lọ sile iwosan aladani ati tijọba, ṣugbọn pabo lo ja si,” Ashok to jẹ baba rẹ lo sọ eyi.

“A gbọ, bẹẹ la si n ka nipa iṣẹ iyanu, sibẹ, ati adura ati oogun ni ko ṣiṣẹ kankan fun wa.”

Agogo kan wa lori ikọ lara ogiri, bẹẹ si ni onka ẹsin kan naa lori ikọ lara ogiri. Bi agogo naa ṣe n yi, agogo naa ko ṣiṣẹ latigba ti ijamba yii ti waye.

Awọn ti wọn wa ni ipo “baaku-baala” yii ni awọn to wa lagbede meji ọrun ati aye, kii ṣe pe wọn ku, ṣugbọn wọn ko mọ ohun to n lọ nitori pe ọpọlọ wọn ko ṣiṣẹ.

Bo ṣe jẹ ọsan to, oju Nirmala tutu bi ẹni to ṣẹṣẹ ji nitori pe ko tii jẹ ounjẹ aarọ. Gbogbo aye rẹ ti wa lara aisan ọmọ rẹ fun ọpọlọpọ ọdun, bii pipaarọ aṣọ, ati fifọ awọn aṣọ ati awọn ohun ti yoo nilo lojoojumọ.

Harish to maa n ṣe ere idaraya lati jẹ ki ẹya ara rẹ tobi, ko wa dabi ọmọ ọgbọn ọdun mọ - oju rẹ ti wunjọ, ẹya ati egungun ara rẹ ti wa gbẹ kọja sisọ.

O ti wa ni ọgbẹ nla to ti fa oriṣiriṣi aisan ati arun miran sii lara lori ibusun to wa.

Oju nikan lo fi n sọrọ lori ibusun to wa bayii.

“Mo ti gbagbe imọlara ohun ti ẹkun jẹ,” iya rẹ lo sọ eyi.

Aworan Nirmala Rana, 60, pẹlu ọmọ rẹ Harish.

Oríṣun àwòrán, BBC/Rana family

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ko wa si ibi kankan ti wọn ti le ri owo mọ, bi wọn ti ṣe na owo fun ọpọlọ ọdun, lọdun to kọja, awọn obi rẹ rawọ ẹbẹ fun iranwọ ti yoo jẹ ki wọn tọju rẹ, ko si gbadun kuro ninu irora, eyi ti wọn pe ni ‘Euthanasia’.

‘Euthanasia’ jẹ igbesẹ lati gbẹmi eeyan lati le jẹ ki irora to n jẹ dawọ duro, eyi to jẹ pe oogun ni awọn akọṣẹmọṣẹ yoo fun un labẹ ofin.

“Mo ti kanlẹ. Bi ohunkohun ba ṣẹlẹ si mi, taani yoo tọju mi?” iya naa sọ bẹẹ.

“A fẹẹ fi awọn ẹya ara rẹ tọrẹ - awọn eyi ti ko ṣiṣẹ foun mọ yoo ṣiṣẹ fun ẹlomiran to nilo rẹ,” o tun fi kun ọrọ rẹ. “A maa ri ọmọ wọn lara wọn, ṣugbọn o maa ri isinmi.”

Ile-ẹjọ Delhi kan kọ ẹbẹ wọn.

Ile-ẹjọ naa sọ pe “si wi pe ẹni to kọ iwe ẹbẹ yii ko si laye nitori awọn iranlọwọ kan, to si le daabo bo ara rẹ lai ni iranlọwọ inu ati ti ita.”

“Ẹni naa n gbe, ko si sẹni kankan to fi mọ oniṣegun to ni aṣẹ lati gbẹmi ẹlomiran nipa yiyan oogun kan labẹ ofin – bo ba tilẹ jẹ pe oogun naa ni yoo yọ ọ kuro ninu irora.”

Awọn ohun to ṣe pataki

Lọdun 2011, ile-ẹjọ agba foju winna loriṣiriṣi nigba to kọ jalẹ lati gbọ ẹsun ẹnikan to ni iru aisan ‘Euthanasia’ naa fun Aruna Shanbaug, nọọsi to ti lo ọpọlọpọ ọdun lori baaku-baala lẹyin ti wọn ṣe ikọlu si lọdun 1973.

Ile-ẹjọ sọ pe awọn ẹri ile iwosan fi han pe kii ṣe pe ọpọlọ Shanbaug ti ku, ti wọn si gbọdọ gba a laaye lati maa gbe ile aye.

Ipo ọhun ni Shanbaug latigba naa titi di ọdun 2015 to jade laye.

Sibẹsibẹ, idajọ ọdun 2011 ti wa id ohun to n fidi mulẹ lati jẹ ofin to de gbia ẹmi eeyan tabi tẹni.

Tẹlẹ, oniruuru aisan euthanasia ni ko ba ofin ilẹ India mu, ṣugbọn ninu idajọ to gbooro, ile-ẹjọ sọ pe gbigba ounjẹ ẹnu alaisan naa le jẹ ohun agbeyẹwo lawọn idi kan ni pataki.

Lọdun 2018, sọ pe awọn to ba wa lori aisan yii le wa labe aabo ti baaku-baala, ki wọn si maa gba itọju.

O ṣalaye pe iwe ẹsun lori aisan yii gbọdọ gba ile-ẹjọ kọja, ati pe akọṣẹmọṣẹ dokita gbọdọ fi ontẹ lu.

Iṣẹlẹ yii ti wa dide fun Harish Rana, ti awọn mọlẹbi rẹ n gbero lati gbẹmi rẹ nipa lilọ sile ẹjọ to ga julọ ni India lẹyin ẹbẹ wọn ko jẹ itẹwọgba nile ẹjọ kekere.

Pẹlu ijakulẹ, mọlẹbi naa nigbagbọ wo pe awọn yoo ri idajọ ododo gba nileẹjọ nla.

Lọwọlọwọ bayii ofin India faaye gba a wi pe ki wọn jẹ ki alaisan naa ku lai ni iranlọwọ nipa biba a gba ẹmi rẹ nipa oogun tabi abẹrẹ.

“Ile-ẹjọ sọ pe ko si ohun agbẹmi duro kankan to gbe ẹmi rẹ durp,” Manish Jan to jẹ agbẹjọro to n duro fun Ranas lo sọ bẹẹ.

“Ṣugbọn ṣa, ọpa to n gbe ounjẹ lọ sikun naa tun jẹ ohun agbẹmi duro,” o fi kun un.

“Gbogbo ohun ti a le ṣe ni lati gba ile ẹjọ agba lọ.”

Lọjọ naa ninu oṣu Kẹjọ

Irọlẹ ọjọ karun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2013 ni Ashok Rana gba ipe wi pe ọmọ rẹ ti “farapa”.

“Dokita sọ fun wa pe irinṣẹ kan ninu ọpọlọ rẹ ti gbẹ,” baba rẹ lo sọ bẹẹ.

Fun ọdun mẹwaa, ọpa ni wọn fi n gbe ounjẹ lọ sinu ikun rẹ - igbesẹ to n na wọn to ẹgbẹrun mẹẹdogun owo India “Rs 15,000” loṣooṣu ($179). Owo ti wọn n na loṣu wa laarin ẹgbẹrun marundinlọgbọn si ẹgbẹrun lọna ọgbọn owo India “Rs 25,000-30,000 ($357)”.

Lati le maa ri owo na, awọn obi rẹ ta ile wọn to wa ni Delhi, wọn si ko lọ sinu yara meji kan to wa lẹyinku olu-ilu naa.

ṣugbọn sibẹ, wọn ṣi n tiraka lati maa san owo naa lọ.

Owo ifẹyinti Rs 3,600 ti Ashok Rana n gba loṣu ko fẹẹ ka iye ti wọn n na ninu ile, depodepo itọju Harish. Lati le maa ran wọn ọwọ, Ashok tun ti bẹrẹ sii ta awọn ohun jijẹ lawọn ile idaraya lawọn opin ọsẹ.

Bi ile-ẹjọ ba kọ lati gbọ ẹbẹ wọn, awọn mọlẹbi Harish yoo fi silẹ lati jẹ ki ile-iwosan maa tọju rẹ lọ nipasẹ iranlọwọ ijọba, wọn ko si nii da sii mọ.

Aworan Ashok Rana, 63,

Oríṣun àwòrán, BBC/Rana family

Àkọlé àwòrán, Ashok, baba Harish n tiraka lati san owo itọju nile iwosan

Iranlọwọ awọn orileede bii Switzerland, Spain, Australia ati ipinlẹ mọkanla ni ilẹ Amẹrika faaye gba aisan naa labẹ ofin.

Ṣugbọn ṣa, ko ba ofin mu lawọn orileede kan.

Ofin kaakiri ilẹ Amẹrika, bi apẹẹrẹ lati maa beere fun iranlọwọ lati gbẹmi eeyan nipasẹ itọju – bo tilẹ jẹ abadofin kan ṣi n lọ lọwọ lorileede Scotland lati ran eeyan lati ku.

“Awọn eeyan nigbagbọ pe Ọlọrun lo n fun ni lẹmi, to si lagbara lati gba ẹmi naa,” RR Kishore, to jẹ dokita ati olulanilọyẹ lo sọ eyi.

Kishore ni aarẹ fun Indian Society for Health and Law Ethics.

“Ko tii si aridaju to fẹsẹ mulẹ, nitori pe ẹni to wa ni baaku-baala lonii, le pada dide to ba di ọla.

“Ṣugbọn, bi a ba gba ẹmi eeyan, a tun ti gba gbogbo ọna anfaani lati ye ni. Ṣisẹ-n-tẹle ni.

“Ni ti Haris, mo nigbagbọ pe yoo sara lati gbe igbimọ eleto ilera dide, leyi ti awọn akọṣẹmọṣẹ bii cardiologist, physiologist, general physician yoo ti mọ boya iranlọwọ yoo wa tabi ki wọn yọ ọ kuro.

“Ohun to ṣẹlẹ si ni pe ile-ẹjọ ko ni ẹri kankan lati mọ ipo ti alaisan naa wa.”

Nirmala Rana ti figba kan nigbagbọ pe ọmọ oun yoo gbadun lọjọ kan, ṣugbọn ọjọ ti n gori ọjọ, ti ọsu si n gori oṣi, ti ọdun tun n gori ọdun, ọjọ naa ko tii de.

“Mo ranti rẹ nigba to maa n yika ile, to si ni igbagbọ ati afojusun ninu ere idaraya ara. O maa wa ba mi lati wọn ibadi rẹ,” iya rẹ lo ranti eyi.

Ni bayii, iku ọmọ rẹ lo n duro de lati gbọ.