Bobrisky tún lulẹ̀ níwájú àjọ EFCC tó rán an lẹ́wọ̀n oṣù mẹ́fà

Àwòrán EFCC àti Bobrisky

Oríṣun àwòrán, BOBRISKY/EFCC/FACEBOOK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àppọ̀ tó fi ìlú Eko ṣe ibùjókòó ti da ẹjọ́ tí gbajúmọ̀ orí ayélujára, Okuneye Idris Olanrewaju tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky pè tako àjọ tó ń rí sí ìgbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) nù.

Bobrisky wọ́ EFCC lọ sílé ẹjọ́ pé wọ́n ń tẹ ẹ̀tọ́ òun mọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọnìyàn tò sń bèèrè fún igba mílíọ̀nù náírà (N200m) fún àwọn nǹkan tí ojú òun rí lọ́wọ́ wọn.

Bákan náà ló ń bèèrè fún bílíọ̀nù kan náírà (N1bn) lọ́wọ́ ilé aṣòfin Nàìjíríà pé wọn kò fún òun láàyè láti gbọ́ tẹnu òun tó sì jẹ́ títẹ ẹ̀tọ́ òun lójú mọ́lẹ̀.

Ó tún ń bèèrè pé kí ilé ẹjọ́ nfòfin de EFCC àti ilé aṣòfin láti yé tàbùkù òun, fi òun sí àhámọ́ tàbí kéde òun bíi ẹni tí wọ́n ń wà.

Ẹ ó rántí pé láti bíi oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni awuyewuye ti ń wáyé lórí ọ̀rọ̀ Bobrisky lẹ́yìn tí Martins Otse Vincent tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí VeryDarkMan gbé fọ́nrán kan jáde níbi tí Bobrisky ti fẹ̀sùn kan pé àwọn òṣìṣẹ́ EFCC kan gba mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún náírà lọ́wọ́ òun láti yí ẹjọ́ tí wọ́n pè tako òun padà.

Ní oṣù Kẹrin ni àjọ EFCC fẹ̀sùn kan Bobrisky pé ó ṣe owó náírà bí kò ṣe tọ́ àti pé àwọn kan ń lo iléeṣẹ́ rẹ̀ BobExpress láti fi kó owó lọ́nà àìtọ́ tí iye rẹ̀ tó ọgọ́sàn-án mílíọ̀nù náírà (N180m).

Àmọ́ níbi ìgbẹ́jọ́ tó tẹ̀le ni EFCC sọ nílé ẹjọ́ pé àwọn kò ba ṣe ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn kejì mọ́ tí ilé ẹjọ́ sì sọ Bobrisky sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́fà nígbà tó gbà pé òun jẹ̀bi ṣíṣe owwó náírà bí kò ṣe yẹ.

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lórí ẹjọ́ tí Bobsriky pè, Adájọ́ Alexander Owoeye ní ẹjọ́ tí Bobrisky pè tako EFCC kò ní ẹsẹ̀ nílẹ̀ àti pé kò rí ẹ̀rí gidi fi gbe àwọn ẹ̀sùn náà lẹ́sẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale fi síta lọ́jọ́ Ẹtì ló fi fìdí ìròyìn náà múlẹ̀.

Adájọ́ Owoeye ní gbogbo ẹ̀rí tí Bobrisky gbé síwájú ilé ẹjọ́ kò ní gbòǹgbò rárá.

Èyí ló mú Adájọ́ náà da ẹjọ́ náà nù tí kò sì ní kí EFCC san owó ìtanràn kankan fún Bobrisky.