Wo ohun tí àwọn èèyàn sọ nípa Aduke Gold níbi ìsìnkú rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì

Àkọlé fídíò, Bí ètò ìsìnkú Aduke Gold ṣe wáyé rèé nílùú Eko
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ ero bẹrẹ lati ori mọlẹ, ọrẹ ati awọn ololufẹ lo yabo agbegbe Ogba nipinlẹ Eko lati bu ọla ikẹyin fun Aduke Ajayi, ẹni ti ọpọ mọ si Aduke Gold.

Ọsé to kọja ni gbajugbaja olorin ẹmi ẹmi naa jade laye ni ile iwosan UCH niluu Ibadan.

Aisan jẹjẹrẹ oju ara lo ṣokunfa iku Aduke Gold.

BBC Yoruba se akojọpọawọn nnkan ti awọn mọlẹbi ọrẹ ati awọn ololufẹ sọ nipa Aduke Gold.

Ẹ wo fọnran yii.

Omijé bọ lójú ọ̀pọ̀ bí wọn ṣe gbé Aduke Gold dé ibí ètò ìsìn ẹ̀yẹ ìkẹyìn Aduke Gold

Aworan ọkọ to n gbe oku Aduke Gold

Ọpọ Mọlẹbi, ọrẹ ati awọn ololufẹ Aduke Ajayi, ẹni tí ọpọ mọ si Aduke Gold bu sẹkun lẹyin ti wọn gbe oku rẹ de.

Aduke Gold, ẹni to jade laye ni ọsẹ to kọja ni ile iwosan UCH niluu Ibadan.

Nigba to n sọrọ, ọkan lara ọmọ lẹyin Aduke, Michael Akande salaye pe gbogbo wọn pada ni mọ nípa ipa nla ti Aduke ko ninu igbesẹ aye.

"Gbogbo wa ni Aunty Aduke fẹ ka ṣe orire.

"O fẹ ka iwe, o fẹ ka gbe igbe aye to dara to sumọ Ọlọrun."

Ẹni tí wọn jọ n gbe ile ni ọpọ awọn ti wọn jọ n gbe ile ni wọn ko mọ pe ilumọka ni nitori o jẹ eeyan to rẹ ara rẹ ni ile.

"A ko mọ pe ilumọka ni nitori ko ri ara rẹ gẹgẹ bii eeyan nla.

"O ni iwa tutu, ti gbogbo wa si nifẹ rẹ

Pasitọ Henry Sinmidele fi ọrọ Ọlọrun bọ awọn eeyan paapa awọn ololufẹ Aduke Gold pe gbogbo ohun to waye lo jẹ akọle, ti ko si ẹnikẹni to le se nnkan.

"Ọlọrun lọ mọ ju, ko dun mọ wa ninu sugbọn Ọlọrun Ọba lo ni gbogbo nnkan.

"Aduke gbe igbe aye to dara, o lo ẹbun rẹ lati yín Ọlọrun to da saye.

"O ko ipa nla ninu awọn eeyan to sun mọ lasiko aye rẹ."

Lónìí ni wọn yóò sin òkú gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí, Aduke Gold

Aworan Aduke Gold.

Oríṣun àwòrán, Aduke gold/facebook

Loni ni wọn yoo sin oku gbajugbaja akọrin ẹmi, Adukẹ Ajayi ti ọpọ mọ si Adukẹ Gold.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ẹbi oloogbe naa fi sita eto isinku fun Adukẹ Gold yoo bẹrẹ pẹlu eto itẹ oku fun igba ikẹyin ati isin idagbere fun oloogbe naa ni owurọ oni ọjọ Ẹti, ọjọ lẹtalelogun oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni ijọ Lagos African Church Grammar School ni College road ni Ogba ni ilu Eko.

Lẹyin eyi ni won yoo gbe oku rẹ lọ si Ogijo, lagbegbe Ikorodu fun isinku.

Gbogbo bi eto isinku naa ba ṣe n lọ ni BBC News Yoruba yoo maa gbe si eti igbọ yin.

‘Àrùn jẹjẹrẹ ojú ara (Cervical cancer) ló pa Aduke Gold’

"Orukọ mi ni Pastor Ajayi Aderounmu, mo jẹ ẹgbọn Aduke, baba kan naa lo bi emi ati ẹ.

Ọdun 1993 ti baba wa ku ni Iya Aduke naa ku, nigba yẹn lo ti di ọmọ orukan, latigba naa lo dẹ ti n gbe lọdọ mi. Emi ni mo kù ni baba fun un.

‘’ Badagry ni wọn bi i si, emi n gbe ni Ifakọ, iku awọn Obi wa lo jẹ ko maa wa gbe lọdọ mi.

‘’Ileẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ lo wa nigba yẹn, mo pada fi i sileẹ̀kọ́ Sanmori Comprehensive High School, Ifako, nigba ti asiko to.

Awọn ẹlẹyinju aanu ni wọn ran an lọ si yunifasiti, LASU lo lọ.

Awọn Ọnarebu Onimọle ati Opeyemi Bamidele, awọn to jẹ baba ẹ gan-an nibi inawo ẹkọ giga niyẹn.

‘’Nipa iku to pa Aduke, Cervical cancer lo pa a loootọ, nitori o han ninu iwe ẹri iku rẹ bẹẹ.

Ta a ni Aduke Gold?

Aduke Gold

Oríṣun àwòrán, Aduke Gold/facebook

Aduke Ajayi, (Aduke Gold) ni ọmọbinrin naa ti wọn bi ni ọdun 1988, ni ilu Badagry, ṣugbọn ọmọ Ilesa, ni ipinlẹ Ọsun ni.

Ọdun 1993 ti baba rẹ ku ni iya rẹ naa jade laye, Aduke ko si ti i ju ọmọde lọ nigba naa.

O tiraka lo ẹbun orin to ni, ogo rẹ si pada buyọ.

O kawe, o si kọ awọn ẹkọ nipa iṣẹ ọwọ ati itọju ọmọde.

Aduke pẹnkẹlẹ ni Oloogbe n jẹ nigba to bẹrẹ orin, ko too yọ penkele kuro to si ni Aduke Gold ni oun yoo maa jẹ, iyẹn lọdun 2008.

Aduke Ajayi jade laye lọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ ọdun 2024, lẹyin aisan jẹjẹrẹ oju ara.