Àwọn ajínigbé gba owó ìtúsílẹ̀ lórí Emir ní Sokoto, wọ́n pa á, àmọ́ wọ́n tú ọmọ rẹ̀ sílẹ̀

Aworan asia SOkoto

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn agbesunmọmi ti tu ọmọ Emir kan niluu Sokoto, eyi to ku sinu igbekun wọn lọjọ Iṣẹgun to kọja silẹ, lẹyin ti awọn mọlẹbi ti san owo ti wọn n beere fun.

Ẹgbọn ọmọkunrin naa, Surajo Isa lo fidi iroyin ọhun mulẹ fawọn akọroyin lalẹ Ọjọru.

Isa sọ pe ọgọta miliọnu naira ati ọkada marun-un ni awọn agbesunmọmi naa gba ko to di pe wọn fi aburo oun silẹ.

O ni “Nnkan bi agogo mẹjọ aabọ alẹ ni wọn de lati ahamọ awọn agbebọn aṣekupani naa.”

Bakan naa lo tun sọ pe awọn agbebọn naa ni wọn sinku baba awọn si ahamọ wọn funra wọn, lai jẹ ki awọn foju kan oku rẹ.

“Ohun ti aburo wa sọ fun wa ree nigba to de,” o ṣalaye.

Nigba to n fidi rẹ mulẹ, Ọnarebu Aminu Boza to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Sokoto sọ pe Isa ti n gba itọju lọwọ ni ile iwosan awọn olukọni ti Usman Danfodio niluu naa.

“O ṣeni laanu pe, wọn ti sinku Emir to doloogbe naa sinu igbo. A gbọ pe aarọ kutu ni wọn sinku ori ade ọhun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Ọmọ Emir naa, Alaaji Kabir Isa ti wa nibi to ti n gba itọju lọwọ nileewosan Usman Danfodio (UDUTH) ti Sokoto. O ṣeni laanu wi pe a ko tun le rii mọ.”

Ọjọ marundinlọgbọn sẹyin la gbọ pe wọn ji olori agbegbe Gatawa nipinlẹ Sokoto, Isa Muhammad Bawa gbe pẹlu ọmọ rẹ ati aburo rẹ.

Latigba ti iroyin iku naa ti jade sita, ọpọ awọn eeyan ni wọn ti n sọ oriṣiriṣi nipa ohun ti oju wọn to.

Ọkan lara awọn olugbe Gatawa, Mahe Mukhtar, jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ oloogbe naa lo gbe iroyin ọhun jade, ti lẹta ibanikẹdun si ti wa lati ọd]o ọm]o ile igbimọ aṣofin-ṣofin to n ṣoju ẹkun Isa-Sabon Birni.

Mọlẹbi oloogbe naa to jẹ Magajin Garin Sabon Birni, Shuaibu Gwanda Gobir, naa tun fidi iku ọhun mulẹ fun akọroyin.

“lotitọ ni Sarkin ti ku. Ana lo ku ni nnkan bi agogo mẹfa ku iṣẹju meje,” o sọ bẹẹ.

Gẹgẹ bo tun ṣe sọ, gbajugbaja ọba alaye ni Shinkafi naa tun fidi rẹ mulẹ.

“Ọba alaye naa ran eeyan kan lọ si buba awọn agbesunmọmi lati le duna dura pẹlu wọn, ki wọn ba a le tu oun, ọmọ ati aburo rẹ silẹ.

“Nigba to debẹ, oku Sarkin lo ba nilẹ. Idi ree to fi sun sẹyin lati lọ pe ọba alaye ọhun wi pe Sarkin ti ku, ati pe awọn ko nilo lati san owo kankan mọ.

“Awọn ẹgbọn ati awọn aburo wa ni wọn gbe owo naa lọ pẹlu awọn ọkada, gẹgẹ bi ohun ti wọn n beere fun, ṣugbọn ọba alaye naa sọ pe a ko gbọdọ jẹ ki wọn lọ,” o ṣalaye.