Tani iṣẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles yóò já mọ́ lọ́wọ́ nínú Janne Andersson àti Herve Renard?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbẹsẹ ijọba Naijiria lati gba akọnimọọgba tuntun fun ikọ agbabọọlu rẹ ti fẹ ẹ dopin bayii amọ eeyan meji pataki lo ṣeeṣe ki ipo naa ja mọ lọwọ.
Lati igba ti Finidi George ti fi ipo naa silẹ ninu oṣu karun un, ọdun yii ni ikọ naa ko ti ni akọnimọọgba mọ, botilẹ jẹ pe adehun ọdun meji ni George buwọlu.
Finidi wa lara ikọ to gba ife ẹyẹ Afcon fun Naijiria lọdun 1994.
Lasiko ti Finidi fi jẹ adari ikọ Super Eagles, ifẹsẹwọnṣe kan ṣoṣo lo bori ninu mẹrin to gba, to si lulẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta to ku, ṣugbọn asiko rẹ pin lẹyin ti Benin lu Naijiria ni amo ayo 2-1.
Ni bayii ti Naijiria n wa akọnimọọgba tuntun, ọmọ orilẹede Sweden, Janne Andersson ati ọmọ ilẹ France, Herve Renard lo wa loju ọpọn.
Ẹnikẹni ti ipo naa ba ja mọ lọwọ ninu awọn mejeji ni yoo ko Naijiria lọ fun awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn yoo ti mọ awọn ti yoo dije ninu Afcon 2025 ti yoo bẹrẹ lọjọ keje, oṣu Kẹsan an.
Ta ni Janne Andersson?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn onimọ nipa ere idaraya gbagbọ pe Andersson tọ fun Naijiiria nitori awọn ohun to ti ṣe ṣeyin.
Lọdun to kọja ni ẹni ọdun mọkanlelọgọta naa fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bii akọnimọọgba Sweden lẹyin ọdun meje gbako.
Laarin ọdun meje naa lo ṣaṣeyọri to lamilaka ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2018 ati European Championship ti ọdun 2020.
Amọ ṣa, lẹyin awọn aṣeyọri naa, o kuna lawọn ọdun to tẹle kọ to kọwe fi ipo rẹ silẹ lẹyin to kuna lati ko awọn ọmọ ikọ re de idije ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2022 ati idije Euro 2024.
Yatọ si Sweden, Andersson ko tii ṣe akọnimọọgba fun orilẹede mii, o si ti ṣe awọn aṣeyọri kan labẹle.
Amọ ṣa, awọn kan n ṣiyemeji nipa ọkunrin ọhun latari bi saa rẹ gẹgẹ bii akọnimọọgba Sweden ṣe dopin, ṣugbọn ajọ NFF gbagbọ pe o mọ iṣẹ naa daadaa.
Ṣe owo NFF le ka Renard?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu awọn mejeji to n du ipo yii, aṣeyọri Renard pọ ju ti Anderson lọ.
Ọkunrin naa ti ṣe ọpọlọpọ aṣeyọri ninu ere bọọlu afẹsẹgba nilẹ adulawọ, oun si ni akọnimọogba kan ṣoṣo to gba ifẹ ẹyẹ bọọlu ilẹ Afrika fun orilẹede meji ọtọtọ.
Renard lo ko Morocco ati Saudi Arabia lọ si idije ifẹ ẹyẹ agbaye lọdun 2018 ati ọdun 2022, ti ikọ rẹ si fi oju Argentina gbole ninu idije naa.
Oun kan naa lo ko ikọ obinrin France lọ idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2023 ati idije Olympics ọdun 2024 yii.
Lọwọ yi, a gbọ pe orilẹede Egypt nifẹ si ọkunrin ọhun, wọn si n fi owo ti iye rẹ jẹ $2m lọ ọ lọdun gẹgẹ bii akọnimọọgba orilẹede naa, eyii to jẹ owo ti ọwọ Naijiria le ma ka.
Wayi o, ọkan lara awọn adari NFF ti sọ pe iye owo ti ọkunrin naa n bere lọwọ Naijiria ti pọ ju ṣugbọn ireti wa pe o ṣeeṣe ko jẹ oun ni iṣe naa yoo ja mọ lọwọ latari aṣeyọri rẹ atẹyinwa.












