Ìjọba Naijiria yóò gba abẹ́rẹ́ àjẹsára ‘Mpox’ lọ́sẹ́ tó ń bọ̀

Doctors and nurses treating patients with mpox in DRC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Makuochi Okafor
    • Role, BBC News
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Orilẹede Naijiria yoo gba ipele akọkọ abẹrẹ ajẹsara ti ajakalẹ arun ‘mpox’ laarin ọjọ meloo kan si asiko yii, lati le ran awọn oniṣegun oyinbo lọwọ nipa didaabo bo awọn araalu lati maṣe lugbadi rẹ.

Ileeṣẹ eto ilẹra Naijiria lo fidi iroyin ọhun mulẹ nipasẹ ajọ eleto ilera ti National Primary Health Care Development Agency (NPHCDA).

NPHCDA sọ pe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ni wọn yoo gba awọn abẹrẹ ajẹsara ọhun ti wọn pe ni JYNNEOS (Imvanex).

Dokita Garba Ahmed Rufia, to jẹ alakoso agba fun ẹka to n ṣabojuto ajakalẹ arun ati abẹrẹ ajẹsara ni ẹka NPHCDA jẹ ko di mimọ pe ẹgbẹrun mẹwaa abẹrẹ naa ni wọn n ko bọ ni Naijiria.

Dokita Rufai ṣalaye pe ijọba ilẹ Amẹrika, nipasẹ ajọ USAID ni wọn fi awọn abẹrẹ ajẹsara ọhun ta wọn lọrẹ, fun lilo awọn eeyan lawọn ipinlẹ ti arun naa ti n ja.

Ilẹ Naijiria tun n ṣiṣẹ lati rii pe wọn gba awọn abẹrẹ ajẹsara miran sii, lati le pin-in sawọn ẹnubode to wọ ilẹ naa.

“Eyi kii ṣe opin abẹrẹ ajẹsara to n bọ ni Naijiria. A tun n ṣe ipalẹmọ lati rii pe a gba awọn abẹrẹ ajẹsara miran, pẹlu bi a ṣe n ṣagbeyẹwo awọn miran ti yoo tun nilo rẹ.,” Dokita Rufai sọ bẹẹ.

Lọwọlọwọ, awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni Naijiria ni wọn ti n gba idanilẹkọọ lati da arun naa mọ ati awọn ohun to le jẹyọ nipa rẹ, bẹẹ si ni eto ilera ti wọn naa jẹ wa logun.

Pẹlu ajọṣepọ awọn ajọ bii NCDC, WHO, ati awọn miran, NPHCDA tyi da awọn ibudo pajawiri silẹ fun itọju arun mpox.

Awọn ibudo yii ni yoo ṣe ipolongo kaakiri nipa arun naa, itankalẹ, ọna lati dena rẹ ati itọju awọn to ba ti lugbadi rẹ.

Naijiria ti wa gbe oriṣiriṣi eto ayẹwo ati amojuto kalẹ lawọn ẹnubode ori omi ati ilẹ lati le tete gbe igbesẹ lati dena rẹ.

Dokita Rufai fidi rẹ mulẹ pe didaabo bo awọn oṣiṣẹ eleto ilera ati awọn araalu jẹ wọn logun pupọ, nipasẹ ipolongo ati idanilẹkọọ kaakiri Naijiria, lori ọna ti awọn eeyan le gba dena rẹ, ati bi wọn ṣe le daa mọ.

Itankalẹ ajakalẹ arun naa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Mpox, ti a mọ tẹlẹ si arun to jẹyọ lati ara ọbọ (monkeypox) lo tan kalẹ nipa isunmọra pẹkipẹki bii ibalopọ, fifi ara kanra ati sisunmọ ara bi a ba n sọrọ, ati mimi si ẹlomiran lara.

Ko din ni eeyan irinwo-le-lọgọta (450) ti wọn ti jade laye lẹyin ti wọn lugbadi arun yii lorileede olominira Congo, ti arun naa si tun ti n tan kaakiri ẹkun aarin gbungbun ati ila-oorun ilẹ Afrika.

Arun naa lo n jẹyọ lara bii kokoro maa jade lagọ ara, ki agọ ara maa wu, to si burujai, ti mẹrin ninu iṣẹlẹ bii ọgọrun si ti gbabẹ ku.

Awọn agbegbe bii tropical rainforests, nibi ti arun ati aisan maa n pọ ju si lọdọọdun ni arun yii ti n jẹyọ ju.

Ṣugbọn sibẹ, ọpọ irufẹ arun mpox lo n tan kalẹ ni ṣisẹ-n-tẹle, to si jẹ pe ohun ti wọn pe ni Clade 1b lo n fa a, eyi ti wọn ṣakiyesi ninu oṣu Kẹsan, ọdun to kọja.

Latigba ti wọn ti ṣakiyesi mpox Clade 1b fun igba akọkọ lorileede Congo, wọn tun ti gburo rẹ lawọn orileede bii Burundi, Kenya ati Rwanda, to si jẹ pe lẹnu ọjọ meloo kan sẹyin, Sweden tun ti pẹlu.