Lẹ́yìn tó san ìdá gọbọi àwọn oníbárà Heritage Bank tówó wọ́n há, Ajọ NDIC ṣàlàyé bí àwọn oníbárà yókù ṣe lè gba owó wọn

Aworan NDIC

Oríṣun àwòrán, NDICNigeria/X - HeritageBank/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ adojutofo ile ifowopamọsi ni Naijiria, iyẹn Nigeria Deposit Insurance Corporation, NDIC ti jẹ ko di mimọ pe ohun ti san ida mẹrindinlaadọrun (86%) owo awọn onibara ile ifowopamọ Heritage to kogba wọle laipẹ yii.

NDIC sọ pe igbesẹ ṣi n lọ lọwọ lati san ida mẹrinla (14%) to ku, fun idi eyi, wọn ni ki awọn onibara ile ifowopamọ Heritage fọkan wọn balẹ.

Alakoso agba ajọ NDIC, Ọgbẹni Bello Hassan lo sọ eyi di mimọ nibi ipagọ fun awọn ọmọ ile ibimọ aṣofin to n ri seto adojutofo, Insurance and Actuarial Matters, eyi to waye nipinlẹ Eko.

Hassan sọ pe ki awọn onibara to ku maa reti lati gba owo wọn, paapaa awọn ti apo aṣuwọn wọn ni PND lori, yala nipasẹ aṣẹ ile-ẹjọ tabi ileeṣẹ alabojuto kan.

Ipagọ ọpun ti wọn pe akori rẹ ni ‘Strengthening Financial Stability and Deposit Insurance Frameworks for Economic Resilience’ ni Aṣofin Ahmed Usman Jaha jẹ alaga rẹ.

Hassan ti ọkan lara awọn alakoso ẹka ajọ naa, Emily Osuji ṣoju fun jẹ ko di mimọ pe agbeyẹwo to waye laipẹ yii fi gege le iye owo ti ajọ naa le san lori owo awọn onibara to wa fun eto adojutofo ọhun wa laarin \idaji miliọnu kan naira si miliọnu marun naira labẹ eto ti wọn pe ni Deposit Money Banks (DMBs), Payment Service Banks (PSBs) ati Mobile Money Operators (MMOs).

O fi kun ọrọ rẹ pe lẹyin iwadii ọdun 2023 ni wọn gbe ipinnu ọhun kalẹ lati le sọ iye owo ti awọn to kowo pamọ si banki le gba labẹ eto adojutofo.

“O yẹ lati sọ ọ jade pe agbeyẹwo to wa lori DMB faaye silẹ fun ida mejidinlọgọrun le ni mejidinlọgọrun (98.98%) apapọ owo ati ida marundinlọgbọn le ni mẹtadinlogoji (25.37%) apapọ iye ti owo ọhun jẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Bakan naa, agbeyẹwo naa tun faaye ṣagbekalẹ sisan ida mọkandinlọgọrun le ni ẹtadinlọgbọn (99.27%), ida mọkandinlọgọrun le ni ẹrinlelọgbọn (99.34%) ati ida mọkandinlọgọrun le ni ọkandinlọgọrun (99.99%) gbogbo ow to wa laṣuwọn, ati pẹlu ida mẹrinlelọgbọn le ni ẹtadinlogoji (34.43%), ida mọkanlelogun le ni mẹrin (21.04%), ati ida mẹtalelogoji le ni mẹwaa (43.10%) iye ti owo ọhun jẹ ni MFBs, PMBs ati PSBs, respectively,” o ṣalaye.

O tẹsiwaju pe titete san owo awọn to kowo saṣuwọn nile ifowopamọ jẹ awọn logun pupọ lati mu ẹka eto iṣuna duro digbi.

“Si eyi, ajọ yii tun ti wa ṣe agbeyẹwo miran lati rii pe wọn wa ọna abayọ miran si ọna ti wọn yoo gba lati san owo awọn to wa ni ile ifowopamọ Haritage to kogba wọle.

“Lori itọni ti a gba la ti maa sọ pe, ajọ yii ti wa gba nọmba idanimọ banki, iyẹn BVN lati ọdọ ajọ Nigeria Inter Bank Settlement System (NIBSS), eyi to fun wọn lanfaani lati wo ile ifowopamọ miran ti awọn onibara tun n lo, lati le san owo wọn sibẹ laarin ọjọ mẹrin.

Alaga igbimọ naa nile igbimọ aṣoju-ṣofin naa ti wa sọ pe ki awọn ọmọ Naijiria ti wọn lowo lawọn ile ifowopamọ lọ fọkan balẹ, nitori pe ko sewu lẹgbẹrun ẹkọ.

Bawo lo ṣe le gba owo rẹ pada?

Ajọ NDIC, ninu atẹjade ti wọn gbe jade soju opo ‘X’ wọn lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ṣalaye lori bi awọn onibara ṣe le ri owo wọn gba pada lai daamu jinna.

NDIC sọ pe oju opo kan ti wọn ṣagbekalẹ rẹ ni ki awọn onibara lọ, yala fun ibeere tabi ẹsun.

Wọn ni awọn ti bẹrẹ sii san owo awọn onibara ile ifowopamọ Heritage pada fun awọn onibara ti idaniloju wa pe wọn ni owo nibẹ.

“Lori bi ile ifowopamọ agba ṣe gba iwe aṣẹ idokoowo lọwọ ile ifowopamọ Heritage, a ti bẹrẹ sii san owo awọn onibara ti a le fọwọ sọya le lori.

“Bi o ba ti fi orukọ silẹ fun gbigba owo rẹ pada, ti o ko si tii ri owo gba, o ni lati mọ awọn nnkan wọnyi;

Fun apo aṣuwọn ileeṣẹ, asopọ, ọmọ tabi ti Estate: Ẹ rii daju pe ẹ ni eyikeyi apo aṣuwọn to wa ni ipele yii

Fun apo aṣuwọn aladani: Rii daju pe o ni apo aṣuwọn miran to ni orukọ kan naa pẹlu eyi ti o n lo, to si tun so papọ mọ BVN rẹ.

Fun ẹyin onibara ti ẹ ni apo aṣuwọn nibẹ tẹlẹ: Ẹ rii daju pe ẹ fi ilana bi owo ṣe n wọle-jade ni banki Heritage lọwọ tabi awọn ẹri miran to le fidi rẹ mulẹ pe ẹyin lẹ ni apo aṣuwọn ọhun.

Ẹ ni lati ni ẹrọ ibanisọrọ to n gba atẹjiṣẹ bi owo ba wọle: Ẹ rii daju pe ẹni ẹrọ ibanisọrọ ti ẹ le fi mọ nigba ti owo ba wọle. Bi ẹ ko ba le yẹ owo yin wo lori foonu, ẹ rii daju pe ẹ lọ sile ifowopamọ yin lati ṣe iwadii.

Njẹ owo ti yin ko tii wọle?

Lati le mọ nipa bi ẹ ṣe maa gba owo yin, ẹ tẹle awọn ilana wọnyi:

Ẹ fi orukọ yin to wa lori apo aṣuwọn ati nọmba apo aṣuwọn yin silẹ.

Ile ifowopamọ miran: Ẹ fi orukọ apo aṣuwọn nile ifowopamọ miran ti ẹ n lo silẹ, nọmba apo aṣuwọn ọhun ati BVN

Bakan naa ni ki ẹ tun fi ẹrọ ibanisọrọ ati imeeli yin silẹ pẹlu

Gbogbo awọn ohun wọnyi lẹ maa fi silẹ loju opo ayelujara ti ajọ NDIC gbe jade loju opo ‘X’ wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post