Kò sí oníṣẹ̀ṣe tó ń pe Ògún, Èṣù ní Ọlọ́run bí àwọn ẹlẹ́sìn kan ṣe ń yára sọ ènìyàn di ọlọ́run wọn – Ifaleke, adarí ìjọ Ọ̀rúnmìlà

Àkọlé fídíò, Ìjọ Ọ̀rúnmìlà
Kò sí oníṣẹ̀ṣe tó ń pe Ògún, Èṣù ní Ọlọ́run bí àwọn ẹlẹ́sìn kan ṣe ń yára sọ ènìyàn di ọlọ́run wọn – Ifaleke, adarí ìjọ Ọ̀rúnmìlà

Njẹ o mọ pe awọn oniṣẹṣe naa ni ile ijọsin, ọjọ ijọsin ati awọn ilana eto ijọsin gẹgẹ bi awọn ẹsin miran bii Kristẹni ati Islam?

Lara awọn ohun ti oju BBC to laipẹ yii niyi lasiko irinajo lọ si ilu ikorodu. Olori Oluwo ati Aṣaaju ijọ Ọrunmila, Ifagbemi Adedọtun Fajọbi ṣalaye ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba idi ti wọn fi n ṣe isọji itagbangba ati isin ọjọ Aiku, ti ọpọ gbagbọ titi di asiko yii gẹgẹ bi ọjọ isinmi fun awọn ẹlẹsin Kristẹni.

Oloye Adedọdun tun ṣalaye pe bi awọn Kristẹni ṣe ni Bibeli, ti awọn Islam naa ni Kuran ni awọn oniṣẹṣe naa ni iwe mimọ ti wọn n pe ni “Iwe mimọ Olodumare.

O ni iwe mimọ yii pẹlu sọrọnipa ọrun rere ati ọrun apaadi gẹgẹ bi oju ti ẹsin abalaye fi n wo o.