Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ dúnkokò ìyanṣẹ́lódì bí ọlọ́pàá bá kọ̀ láti fi olórí wọn Ajaero sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, BBC Pidgin/Facebook
Awọn alakoso ẹgbẹ oṣiṣẹ lorileede Naijiria, NLC ti fẹsun kan ijọba apapọ wi pe o n dunkooko mọ awọn olori wọn nipa ibanilorukọjẹ, ati pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi bi ileeṣẹ ọlọpaa ba ti alaga awọn, Joe Ajaero mọle.
Ipinnu ẹgbẹ NLC ree lẹyin ipade pajawiri ti wọn ṣe ni olu ile ẹgbẹ wọn to wa niluu Abuja laarọ ọjọ Iṣẹgun.
Ninu abajade ipade pajawiri ti awọn alakoso ẹgbẹ NLC ṣe, eyi ti igbakeji alaga, Kọmureedi Adewale Adeyanju buwọlu, lo ti sọ pe awọn yoo gun le iyanṣẹlodi bi ọlọpaa ko ba tete tu ọga awọn silẹ.
Awọn alakoso NLC sọ pe oru oni ni iyanṣẹlodi ọhun yoo bẹrẹ, bi ohunkohun ba fi ṣẹlẹ si aarẹ ẹgbẹ awọn.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Aje to kọja yii ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria fi iwe pe Joe Ajaero lati wa sọ tẹnu rẹ lori ẹsun ṣiṣagbatẹru awọn agbesumọmi, igbimọ ọtẹ ati awọn iwa ọdaran miran.
Nigba ti wọn sọrọ ninu abajade ọhun, NLC sọ pe iwe ipe ti wọn fi ranṣẹ pe alaga wọn ni ọwọ oṣelu ninu pẹlu awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
NLC sọ pe kaka ki ijọba Naijiria ati ileeṣẹ ọlọpaa tọrọ aforiji lori ikọlu ti wọn ṣe si olu ile ẹgbẹ awọn, niṣe ni wọn bẹrẹ si n dunkoko mọ awọn, ti wọn si n ba awọn lorukọ jẹ.
Bakan naa ni NLC jẹ ko di mimọ pe igbesẹ lati pa awọn alakoso ẹgbẹ naa to n ṣiṣẹ takuntakun lẹnu mọ ni, to si tako iwe ofin Naijiria ati iwe ofin ajọ oṣiṣẹ lagbaye, ILO.
Koko pataki to wa ninu abajade ipade NLC
NLC sọ pe awọn yoo bọwọ fun iwe ipe ọhun
“Gẹgẹ bi ẹgbẹ to mọ ohun to n ṣe, titẹle ofin ati ilana jẹ wa logun, NLC yoo bọwọ fun iwe ipe lati ọdọ ileeṣẹ ọlọpaa, ati pe a n fẹ asiko sii nitori pe iwe ipe naa tiya ju. Ṣugbọn sibẹ, eyii ko fidi rẹ mulẹ pe awọn ẹsun ti wọn fi kan olori wa jẹ otitọ.”
NLC bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba
“Igbimọ iṣakoso ẹgbẹ yii bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe n dunkooko mọ awọn olori wa ati awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ miran ni gbogbo igba. A ri ohun to n ṣẹlẹ yii gẹgẹ bi ipinnu lati da eto ati agbekalẹ ẹgbẹ wa ru, eyi to ti wa nipa jija fun ẹtọ araalu.”
NLC ni ki ijọba dẹyin lẹyin awọn
“Igbimọ iṣakoso NLC ṣe ikilọ fun ijọba lati dawọ ipinnu aburu wọn duro, ki wọn si dẹyin lati maa dunkooko mọ awọn olori ẹgbẹ wa. Ẹgbẹ yii ko niii jokoo lati fọwọ lẹran nigba ti wọn ba fi ẹtọ awọn olori ati ọmọ ẹgbẹ dun wọn nipa ijẹgaba ijọba.”
NLC pe fun iyanṣẹlodi kaakiri Naijiria
Wayi o, ẹgbẹ oṣiṣẹ ti wa paṣẹ fun gbogbo awọn olori rẹ kaakiri awọn ipinlẹ to wa nilẹ Naijiria lati sọ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ wọn lati gun le iyanṣẹlodi.
NLC sọ pe “a ko nii kawọ gbera lati gbe igbesẹ to yẹ, lara eyi ti a maa bẹrẹ ifẹhonuhan ati iyanṣẹlodi, lati le daabo bo ohun ti ẹgbẹ naa duro fun.
“Bi ohunkohun ba ṣẹlẹ si aarẹ tabi eyikeyi ninu ọmọ ẹgbẹ wa lori ẹsun ti ko jẹ itẹwọgba eyi ti wọn fi kan wọn; igbimọ iṣakoso ti sọ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati gun le iyanṣẹlodi, bẹrẹ lati agogo mejila oru oni,” wọnyi lohun ti wọn buwọ lu.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní kí ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC Ajaero wá sọ tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ṣíṣe ágbatẹ̀ru fàwọn agbésùmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, NLC
Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti kọwe ranṣẹ pe aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC, Joe Ajaero lori ẹsun ṣiṣe agbatẹru awọn agbebọn, aṣekupani.
Yatọ si ṣiṣe agbatẹru awọn agbebọn, ọlọpaa tun sọ pe Ajaero lọwọ ninu iwa jibiti ori ayelura ati oniruuru iwa ọdaran miran.
Iwe ipe ti wọn kọ ranṣẹ si Ajaero lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, eyi ti igbakeji ọga ọlọpaa lẹka PIR, ACP Adamu Muazu buwọ ni wọn ti sọ pe ki alaga NLC naa wa sọ tẹnu rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe bi Ajaero ba kọ lati yọju si wọn gẹgẹ bi wọn ṣe fiwe pe e gẹgẹ bi ọmọluabi, awọn yoo fi kele ofin gbe e.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ ninu iwe ipe ti wọn ṣọwọ si Ajaero pe “ileeṣẹ ọlọpaa n ṣe iwadii lori ẹsun gbigbimọ iwa ọdaran, ṣiṣagbatẹru agbebọn, iwa ọdaran nla, igbimọ ọtẹ, lilo ipo lọna aitọ, ati jibiti ori ayelujara, eyi ti wọn ti darukọ rẹ.''
Ọlọpaa sọ pe Ajaero ni lati yọju si ọfiisi awọn logunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ni deedee agogo mẹwaa owurọ, ni Abuja.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun fidi rẹ mulẹ pe Ajaero ni lati mọ daju pe bi o ba kọ lati bọwọn fun iwe-ipe naa, wọn kele ofin lawọn yoo fi gbe e jade.
NLC naa sọrọ lori bi ileeṣẹ ọlọpaa ti pe Ajaero
Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC funra rẹ ti wa jẹ ko di mimọ pe lotitọ lawọn gba iwe-ipe naa lati pe alaga apapọ wọn, ati pe bi wọn ṣe pe Ajaero ko ṣẹyin bawọn ọlọpaa ṣe wa kọlu ileeṣẹ awọn.
Ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin fun ẹgbẹ NLC, Benson Upah gbe jade, o sọ pe ejo lọwọ ninu.
“O foju han pe, a ko tii gbọ ohun to gbẹyin nipa bi wọn ṣe wa kọlu olu-ileeṣẹ NLC,” Upah lo sọ bẹẹ.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ bu ẹnu atẹ lu ileeṣẹ ọlọpaa lori awọn to farapa lasiko iwọde 'ebi n pa wa' to lọ.
Ẹwẹ, igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, NEC ti pe ipade pajawiri lori bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ni ki Ajaero wa sọ tẹnu rẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Laarọ ọjọ Iṣẹgun ni igbimọ NEC fi ipade pajawiri ọhun si eyi ti wọn ti kepe gbogbo awọn ti ọrọ kan lati wa nibi ipade naa.















