Ìdí rèé tí N29m táwọn sẹ́nẹ́tọ̀ ń gbà lóṣù kò fi tó ná - Sẹ́nẹ́tọ̀ Abbo

Aworan Elisha Abbo

Oríṣun àwòrán, Senator Ishaku Abbo - SIA/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Sẹnẹtọ Elisha Abbo, to ti figba kan ri jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja nibi to ti ṣoju ẹkun Ariwa ipinlẹ Adamawa ti jẹ ko di mimọ pe owo ti awọn aṣofin n gba loṣooṣu kii ṣe owo to pọ .

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu awọn aṣofin lori owo gọbọi ti wọn n gba loṣu.

Ṣugbọn ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Arise laipẹ yii, Sẹnetọ Abbo sọ pe ori iwe ni owo naa ti pọ, nitori pe ko too na fun awọn adojukọ ọfiisi ti wọn di mu.

Abbo sọ ọ di mimọ pe miliọnu mẹrinla aabọ (N14.4m) naira loun n gba lọ sile loṣu lasiko toun fi wa nipo sẹnetọ, ṣugbọn to ni awọn to wa nibẹ bayii ti n gba miliọnu mọkandinlọgbọn naira lọ sile loṣu.

Ninu ọrọ rẹ, Abbo ni “nigba ti mo wa nipo aṣofin, apapọ owo ati ajẹmọnu ti mo n gba loṣu jẹ miliọnu mẹrinla ataabọ naira.

Ẹ maa gba owo bii aṣọ, mọto ati awọn miran, apapọ rẹ to fi mọ owo oṣu miliọnu kan naira jẹ miliọnu mẹrinla aabọ.

“Owo naa ti to bii miliọnu mọkandinlọgbọn bayii. Miliọnu mọkandinlọgbọn naa tobi loju iwe.

“Mo n sọ eyi gẹgẹ bi olotitọ eeyan ti mo jẹ. Mi o gbiyanju lati kin awọn aṣofin lẹyin, ati pe mo ti jẹ ọmọ ile igbimọ ọhun fọdun marun ri.

Mi o duro pẹlu wọn, ṣugbọn mo ni lati sọ otitọ to wa nibẹ.”

O sọ siwaju pe niṣe loun tun toṣi sii nigba toun fi iṣẹ oun silẹ lati di aṣofin.

“Mo ni lati fi ileeṣẹ ti mo gbe kalẹ silẹ, nibi ti mo ti jẹ alakoso ati oludasilẹ, ki n to lọ darapọ mọ oṣelu nigba ti mo bori idibo.

“Mo ni lati bẹrẹ sii ja gbogbo bi mo ṣe n na owo tẹlẹ wa silẹ nitori pe gbogbo owo ti wọn n ya sọtọ fun ọfiisi mi ko to nnkan bi mo ba wo awọn ipenija to n doju kọ ipo ti mo di mu lojumọ.

“Mo ni iṣẹlẹ ẹnikan ti mo gbe lọ si ile iwosan; miliọnu mẹrinla naira ni mo na le e lori.

“Loṣooṣu, kaakiri ipinlẹ Adamawa ati awọn ipinlẹ yooku, niṣe ni ọfiisi mi maa n kun fun awọn to nilo iranlọwọ.

“Niṣe ni mo ni lati bẹrẹ pe awọn gomina ipinlẹ kan lati ba mi ṣe iranwọ fun awọn to n wa iranlọwọ wa ba mi,'' Sẹnẹtọ Abbo lo sọ bẹẹ.

Ki lo ṣẹlẹ sẹyin?

Laipẹ yii ni aarẹ Naijiria tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ sọ pe ko tọna fun awọn aṣofin lati maa sọ iye owo ti yoo maa ba wọn lọ sile loṣu.

“Ko yẹ ko jẹ pe ẹyin lẹ ma maa ṣagbekalẹ iye owo to n ba a yin lọ sile; ojuṣe ajọ Revenue Mobilization Allocation and Fiscal Commission (RMAFC) ni.

Obasanjo sọ pe “mo fi tọwọtọwọ sọ pe, ẹyin naa mọ pe ohun ti ẹ n ṣe ko dara; ko tọna lati jẹ pe emi ni ma maa sọ iye owo ti mo n gba funra mi; ko ba iwa ọmọluabi mu, ẹ si n ṣe e, ile igbimọ aṣofin naa n ṣe e.”