Ó ti pé ọgbọ̀n ọdún tí mo ti ń sùn lábẹ́ afárá l’Eko - Sa'adu ṣàlàyé

 Liya’u Sa’adu labẹ afara niluu Eko
    • Author, Mansur Abubakar
    • Role, BBC News, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Pẹlu bo ti ṣe lo idaji ninu igbesi aye rẹ labẹ afara nipinlẹ Eko to jẹ ọkan lara awọn ilu to tobi julọ ni Naijiria, Liya’u Sa’adu ṣi n ri ara rẹ gẹgẹ bi ‘alabojuto’ fun ọpọ awọn alainile ti wọn ti darapọ mọ ọn.

Awọn to le ni ọgọta ni wọn ti wa n gbe nikorita ati abẹ afara Obalende nibi ti ariwo ti n lọ ni gbogbo igba – pẹlu bi owo ile sisan ṣe jẹ iṣoro fun wọn.

Ọgbẹni Sa’adu gba awọn to ṣẹṣẹ n bọ – pupọ wọn to jẹ ọdọ - ti wọn wa lati ilu tabi abule to jinna – nipa bi wọn ṣe le ṣi ọpọlọ kalẹ bi wọn ba fẹẹ gbe l’Eko, nibi to rọrun lati ko sinu iwa ọdaran ati lilo oogun oloro.

“Ọmọ ọgọta ọdun ni mi, ti mo si ni awọn ọmọ kekeeke ti wọn jẹ ọdọ ti wọn debi loṣu ati ọdun diẹ sẹyin. Mo rii gẹgẹ bi ojuṣe mi lati tọ wọn sọna,” o sọ fun BBC.

“O rọrun pupọ lati ṣiṣe l’Eko nibi, paapaa fun awọn ọmọde nitori pe wọn ko ni mọlẹbi lati wo igbesẹ ti wọn n gbe.”

Bii pupọ ninu awọn to n gbe labẹ biriiji, o sọ lede Hausa, ede kan ṣoṣo to gbajumọ julọ lẹkun Ariwa ilẹ Naijiria.

Ilu kekere kan to n jẹ Zurmi nipinlẹ Zamfara lo ti kuro lọdun 1994 – ṣugbọn pupọ awọn to ba ṣọre nigba to de lo ti ku, ti awọn miran si ti pada silu ati abule ti wọn ti wa.

Tukur Garba, toun naa bẹrẹ sii gbe labẹ biriiji lọdun marun-un sẹyin sọ pe awọn amọran ti Ọgbẹni Sa'adu n fun awọn wulo gidigidi, ti ko si ṣee ṣa danu, eyi to jẹ ko maa gba ọwọ gba lati ọdọ awọn ti wọn wa ọjọ iwaju rere wa s’Eko.

Ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn naa lo wa lati ilu Kaduna to jẹ ẹgbẹrun kan kilomita sipinlẹ Eko.

“Niṣe lo dabi ẹgbọn wa agba nitori pe o ti wa nibi lati ọdun to ti pẹ sẹyin. A si nilo awọn ọrọ amọran ati ọlọgbọn lati ọdọ rẹ nitori pe o rọrun pupọ lati ko sinu wahala l’Eko,” o sọ eyi di mimọ.

Awọn eeyan labẹ afara pẹlu Liya’u Sa’adu
Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan labẹ afara pẹlu Liya’u Sa’adu
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbegbe naa ni wọn ti wa sọ lorukọ miran ti wọn pe ni "Karkashin Gada" ni ede Hausa, eyi to tunmọ si “Labẹ biriiji” ni Yoruba.

“Awọn to n wa sibi mọ awọn to ti n gbe nibi tẹlẹ tabi awọn to ni ibaṣepọ pẹlu awọn to n sọ fun wọn nipa Karkashin Gada,” Ọgbẹni Sa'adu lo sọ eyi.

“Nigba ti mo de ibi, awọn ti mo ba ko to mẹwaa.”

Adamu Sahara to ti gbe nile kan to sunmọ Karkashin Gada fun ọgbọn ọdun le diẹ sọ pe ainile lori tubọ n peleke sii nipinlẹ Eko.

“Aisi eto aabo [to fi mọ ikọlu awọn ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Jihadist] ati eto ọrọ aje ti ko ṣe deedee ti jẹ ki ọpọ awọn eeyan sa kuro ni ẹkun Ariwa Naijiria,” Ọgbẹni Sahara lo sọ bẹẹ.

“Awọn alakoso Naijiria ni lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, ki wọn le mọ bi wọn ṣe maa yanju iṣoro ọhun, nitori pe ko si eniyan to yẹ ko maa gbe abẹ afara.”

Awọn to ti pẹ ni Karkashin Gada ko ni ipinnu tabi erongba kankan lati pada si Zamfara pẹlu bi eto ọrọ aje ṣe tubọ n dẹnu kọlẹ nibẹ nipa ni ijinigbe ati ikọlu loriṣiriṣi ṣe n gbilẹ sii.

Eyi ti jẹ ki ọpọ pa iṣẹ, okoowo ati oko ti wọn da silẹ, pẹlu ibẹru kiko sọwọ awọn ti yoo mu wọn ni igbekun lati beere owo.

Lati mu ki igbe aye rọrun fun un, Ọgbẹni Sa’adu ti ra ibusun, ati awọn ibi to le tọju nnkan pamọ si, to fi mọ aawọn apẹfọn.

O ti gbe ibusun naa sori pako to n tọju nnkan si, ibẹ si lo n sun si lojoojumọ.

Ibudokọ nla lẹgbẹẹ afara Obalende niluu Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ibudokọ nla lẹgbẹẹ afara Obalende niluu Eko

Nnkan ṣi dara fun Ọgbẹni Sa’adu, pẹlu bi awọn miran to n gbe labẹ biriiji ko ṣe ni nnkan ti wọn le fi sun, to si jẹ pe ẹni ti wọn n tẹ ni pupọ n sun lori rẹ nilẹ.

Ọpẹ lo jẹ pẹlu bi ilọnilọwọgba ati ole jija ṣe dinku nitori pe awọn to n gbe ni Karkashin Gada yii ṣe n wa nibẹ ni gbogbo igba, yala lati maa ṣiṣẹ ni tabi jaye ori wọn.

Ile iwẹ ati ṣalanga kan ṣoṣo ni gbogbo wọn n lo, ti wọn si n san ọgọrun kan naira lasiko ti wọn ba fẹẹ lo o.

Dida ina ounjẹ tabi ṣiṣa ina, paapaa lasiko ẹrun – kii sabaa ṣẹlẹ ni Karkashin Gada nitori pe pupọ awọn to n gbe nibẹ ni wọn n ra ounjẹ jẹ lọwọ awọn olounjẹ, paapaa fun awọn to wa lati ẹkun Ariwa.

“Ibi yii wa lara awọn agbegbe to wa l’Eko ti ọpọ awọn to wa lati ẹkun Ariwa Naijiria pọ ju si, fun idi eyi, Fura ni mo n ta nibi, ti inu mi si n dun wi pe ọpọ awọn eeyan lo n ba mi ra a,” Aisha Hadi to n ta ounjẹ lo sọ fun BBC.

Laarin ọgbọn ọdun to ti lo l’Eko, idagbasoke ti de ba Ọgbẹni Sa’adu lati iṣẹ bata riran to yan laayo si ṣiṣa irin-ta – iyẹn ni pe ṣiṣa irin kaakiri igboro lati ta a fun awọn to nilo rẹ.

Iṣẹ yii lo si n mu ẹgbẹrun marun-un naira wọle fun un lojumọ, bo tilẹ jẹ pe ko too jẹ, ṣugbọn o si yatọ si pe ko ma ri rara.

“Ẹ ma gbagbe pe mo tun ni lati fi owo ranṣẹ si awọn mọlẹbi mi nile ni Zamfara lọsẹ-ọsẹ, idi ree to fi pọn dandan lati tubọ tẹpa mọ iṣẹ,” Ọgbẹni Mr Sa’adu sọ.

 Liya’u Sa’adu ree labẹ afara l'Eko
Àkọlé àwòrán, Liya’u Sa’adu ree labẹ afara l'Eko

Ko tii sẹni to ṣi le sọ pato nipa iye awọn eeyan to n sun labẹ afara niluu Eko, ṣugbọn awọn ajọ ti kii ṣe ti ijọba sọ pe wọn to idaji miliọnu kan.

Ni nnkan oṣu diẹ sẹyin, oriṣiriṣi adojukọ lo ti de ba awọn to n gbe lagbegbe Karkashin Gada lati ọdọ ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n ri sọrọ eto ayika.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ti sọ pe ọna aitọ ni awọn eeyan fi n gbe nibẹ.

Awọn ti ọwọ tẹ ni wọn san ẹgbẹrun lọna ogun naira, owo to jẹ pe pupọ awọn to n gbe labẹ afara ọhun lo n rii laarin ọsẹ kan.

“Nnkan bi agogo kan si agogo meji oru ni wọn de lati ko awọn to n sun nibi. Nibo ni wọn fẹ ka lọ?” Ọgbẹni Garba sọ eyi, to si tun fi kun un pe aarọ kutu ọjọ naa ni pupọ awọn “olugbe” tun ti pada sibẹ.

O rọ ijọba lati boju aanu wo awọn, ati “lati boju wo ọrọ ile gbigbe pẹlu bi ọpọ awọn otoṣi bi awa ko ṣe le ri ibi to dara lati maa gbe”.

Ṣugbọn ni Naijiria, ijọba ko pese ibi aabo fun awọn ti ko nile lori. Tabi ki igbesẹ tilẹ wa lati ṣe iru nnkan to jọ bẹẹ.

Dipo eyi, adojukọ ipinlẹ Eko ni lati maa ṣe iranlọwọ fun awọn ti owo oṣu wọn ko to nnkan – bii agbalẹ, awakọ ati awọn ojiṣẹ lawọn ofiisi kaakiri – lati ra ile gbigbe.

Fun awọn bii Ọgbẹni Sa’adu, ko si iru ile ti owo wọn le ka nipinlẹ Eko – lati gba ile si agbegbe idọti gan-an ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira lọdun kan.

Ile to kere julọ lawọn agbegbe ti awọn eeyan ti n ṣiṣẹ ko din ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun-le-laadọta (N350,000) naira lọdun kan.

Eyi to tun buru ju nibẹ ni pe, ọpọ lanlọọdu ni wọn n beere owo ọdun kan gbako ko to di pe wọn gba eeyan sile, ti ijọba ko si ni eto lati ṣagbekalẹ ilana nipa owo ile sisan, eyi to n fa ki owo ile maa lọ soke loore-koore.

Idi ree to fi jẹ pe awọn bii Ọgbẹni Sa’adu fi gba kamu lati maa gbe labẹ biriiji Obalende.

“Nipa wiwo ohun ti mo n ṣe, o ṣoro lati tọju owo lati fi gba ile,” o sọ eyi bo ṣe dubulẹ sori ibusun rẹ pẹlu ariwo awọn ọkọ to n kọja lọ.

“Ariwo awọn ọkọ to n kọja lọ ti mọ mi lara. Ko di mi lọwọ lati sun, paapaa nigba ti mo ba ti fi ara ṣiṣẹ, to si rẹ mi,” o fi kun ọrọ rẹ.