Kí ni ìdí tí wọ́n fi ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ìbejì tí Ooni Ile Ife bí wọ ààfin lẹ́yìn oṣù márùn ún tí wọ́n bí wọn?

Aworan Ọọni ati awọn ibeji rẹ.

Oríṣun àwòrán, Ọọni ati awọn ibeji rẹ/Otunba Moses Olafare

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lọjọ Aiku ni wọn ko awọn ibeji Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọjaja keji wọ inu aafin fun igba akọkọ lẹyin ti wọn bi wọn loṣu karun un sẹyin.

Ọmọọba Adesina ati Ọmọọbabinrin Adesewa ni orukọ awọn ibeji ọhun ti wọn jẹ ọkunrin ati obinrin, eyi ti Olori Tobi Phillips-Ogunwusi bi ninu oṣu kẹta, ọdun 2024.

Ninu atẹjade ti agbẹnu sọ fun Ọọni ile Ifẹ, Otunba Moses Olafare fi sita, lo ti sọ pe apẹẹrẹ rere ni ibeji ọhun jẹ fun itẹ Ọọni, nitori pe igba akọkọ ree ti ibeji yoo wọnu aafin Ile-Ifẹ latigba ti wọn ti n jẹ Ọọni.

Aworan Olori Tobi Phillips-Ogunwusi ati awon ibeji

Oríṣun àwòrán, Otunba Moses Olafare

Awọn mọlẹbi ọba, awọn ọbalaye kaakiri, awọn agba oye gbogbo, awọn oluawo atawọn eekan laafin ni wọn wa nikalẹ lati tẹwọ gba awọn ọmọọba ibeji Adṣina ati ọmọọbabinrin Adeṣẹwa Ogunwusi si aafin Oodua nilu ile ifẹ pẹlu ijo ati ayọ.

Araba Awodotun Aworemi to jẹ Araba Agbaye, ati Obadio ilu Ile-Ifẹ to tun jẹ alakoso igbalẹ Oduduwa, Oloye Obadio Farotimi Faloba ni wọn dari eto gbigbe awọn ibeji oriade naa wọ aafin Oodua nilu Ile ifẹ.

nigba ti eto gbogbo to, Ọọni funra rẹ lo gbe awọn ibeji naa wọ inu Ile-Igbo, iyẹn yara ti Oduduwa gbe nigba to wa laye lati gba adura lẹnu awọn alalẹ Ifẹ fun awọn ibeji naa.

Awon alejo

Oríṣun àwòrán, Otunba Moses Olafare

Lọwa Adimula Ile-Ifẹ to jẹ igba kẹta si Ọọni ile Ifẹ, Oloye Adekola Adeyeye to lewaju awọn ibeji naa lọ sinu Ile Oduduwa ṣe gbogbo eto to yẹ ni ibamu pẹlu ilana iṣẹmbaye. Bakan naa lo gba adura gbogbo to yẹ

Bakan naa ni Ọbalufẹ tile Ifẹ to tun jẹ olootu ijọba ilẹ Ifẹ, Ọba Idowu Adediwura wa pe gbogbo awọn alalẹ lati daabo bo awọn ibeji naa, ko si jẹ ki wọn pe laye.

Ọba Adediwura nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe itan manigbagbe ni Ọba Ogunwusi fi lelẹ. O ni Ọọni Ogunwusi ni Ọọni akọkọ ti olori rẹ yoo bi ibeji latigba ti wọn ti bẹrẹ sii jẹ Ọọni ni ẹgbẹẹgbẹrun ọdun sẹyin.