“Gbogbo agbára àwa oníṣẹ̀se la máa fi bá Ọba tí kò bá fi àyè gba ìsẹ̀se jà láti le kúrò lórí ìtẹ́”

Iṣeṣe
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Akori Àjọdun isẹṣe ti ọdun 2024 to waye niluu Osogbo nipinlẹ Osun, ni Àjọṣepọ laarin ipo ọba ati isẹṣe oriṣa.

Okori yii lo mu oniruuru ọrọ jade si awọn Ọba ti ko naani isẹṣe ati aṣa ilẹ̀ Yoruba mọ.

Ọba Adekunle Oyelude Makama, Olowu ti Owu Kuta, ti sọ fun awọn onisẹṣe wi pe, ki wọn maa se dara wọn lamu rara lori ọba toun bu awọn onisẹṣe tabi ti ko ka isẹṣe si.

Ọba Adekunle Oyelude Makama tun fi kun ọrọ rẹ wi pe, ki Gomina Ademola Adeleke ko gbe igbesẹ lori awọn Ọba toun bu awọn onisẹṣe lati kii nilọ, ko ma baa padanu ipo rẹ nitori wi pe, ọba jẹ oriṣa ati pe, ọba ko gbọdọ gbe ẹṣin kankan lori rara tabi maa bu awọn ẹlẹsin kan.

O ni ki awọn onisẹṣe lọ fi ọkan wọn balẹ lati ma ba ọbọ péjọ jawura rara.

Oluseyi Atanda, ẹni to jẹ Aarẹ fun ẹgbẹ onisẹse nipinlẹ Osun ti sọ wi pe, ọba ti ko ba fi aye gba awọn onisẹṣe niluu rẹ tabi nipinle Osun, gbogbo agbara awọn onisẹse ni wọn maa fi ba ja lati le fi ori ìtẹ́ rẹ silẹ.

Ọrọ yii lo waye lakoko ti Aarẹ awọn onisẹṣe nipinlẹ Osun ka ọrọ ikini kaabọ rẹ.

Oluseyi Atanda wa rọ gbogbo awọn to peju pesẹ si ayajọ ọdun isẹṣe ti ọdun yii lati tunbọ gbe isẹṣe ati asa larugẹ ni agbegbe kowa wọn ki idagbasoke le de ba ilẹ Yoruba.

Ayájọ́ ọdún ìṣẹ̀ṣe bẹ̀rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá

Awọn ẹlẹsin abalaye kan.

Ayẹyẹ ọdun iṣẹṣẹ ti bẹrẹ kaakiri ilẹ Yoruba. Paapajulọ lawọn ipinlẹ bii Ọyọ, Eko, Ọṣun, Ogun ati Kwara.

Ogunjọ oṣu kẹjọ ọdọọdun ni ayajọ ọdun iṣẹṣẹ ni ilẹ Yoruba.

Kaakiri awọn ipinlẹ ni ajọdun naa ti bẹrẹ bayii.

Ni ipinlẹ Ogun, agbegbe oke Abola, Oke Aregba Abeokuta ni ayẹyẹ naa ti n waye.

Ni kutukutu owurọ lawọn olujọsin ẹsin abalaye ti bẹrẹ si nii korajọpọ si ibudo naa.

Ogunlogo awon oniṣẹṣe ni ipinlẹ ogun ni wọn ti n ṣe iwure nidi oriṣa ifa ti o wa ni oke Abola ti o wa ni oke Aregba, Abeokuta.

Ọpọlọpọ awọn oloye oniṣẹṣe ni wọn ti wa ni ikalẹ pẹlu orisirisi awọn ẹlẹsin abalaye miran lati ṣe ayẹyẹ ọdun iṣẹṣe ọdun yii.

Ijọba ipinlẹ ogun kede oni gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati fi ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọdun iṣẹṣe lọdun yii.

Awọn ẹlẹsin abalaye kan.
Awọn ẹlẹsin abalaye kan.
Àwọn ìpínlẹ̀ tó ti kéde ọ̀la gẹ́gẹ́ bíi ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ fún àyájọ́ ẹ̀sìn àbáláyé rèé
oro

Oríṣun àwòrán, @HeraldNG

Awọn ipinlẹ kan nilẹ Yoruba ti kede ọjọ Iṣegun, ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.

Isinmi naa ni wọn fun awọn eeyan ki awọn ẹlẹsin abalaye le ṣe ọdun wọn.

Ṣaaju ni awọn ipinlẹ kan nilẹ Yoruba ti kọkọ kede gbogbo ogunjọ ninu oṣu Kẹjọ, ọdọdun gẹgẹ bii ayajọ ọjọ awọn ẹlẹsin abalaye.

Ti e ko ba gbagbe, ki ikede naa to waye ni awọn ẹlẹsin abalaye ti n bere pe o yẹ ki ijọba yẹ awọn si, ko si fun awọn ni ọjọ isinmi.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ ninu ibere wọn ṣaaju, wọn ni awọn naa lẹtọ si ayẹsi ati ọjọ isinmi gẹgẹ bo ṣe wa fun awọn ẹlẹsin Kristẹni atawọn Musulumi.

Wọn sọ pe ti ijọba ba le maa ṣeyẹsi awọn ẹlẹsin to ku, to si n kede isinmi fun wọn lẹnu iṣẹ lati ṣe ọdun, awọn naa tọ si irufẹ ayẹsi ati isinmi bẹẹ.

Ko pẹ lẹyin naa ti ijọba kede ọjọ ọhun fun wọn.

Wayi o, kii ṣe gbogbo ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba lo kede isinmi naa.

Awọn ipinlẹ to ti kede isinmi lẹnu iṣẹ fun ayajọ ẹsin abalaye

Awọn ipinlẹ to ti kede ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni

  • Ipinlẹ Eko
  • Ipinlẹ Ogun
  • Ipinlẹ Oyo
  • Ipinlẹ Osun

Ẹwẹ, lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ijọba ipinlẹ Ondo ati ipinlẹ Ekiti ko tii kede irufẹ isinmi bẹẹ fun awọn eeyan wọn.