Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ọkọ̀ òfúrufú tuntun tí Ààrẹ Tinubu wọ̀ lọ sí France

Airbus

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjọ Aje ọsẹ yii ni Aarẹ Bola Tinubu rinrinajo lọ si orilẹede France ninu ọkọ ofurufu tuntun ti ileeṣẹ Aarẹ ṣẹṣẹ ra.

Iwadii ileeṣẹ iroyin BBC fi han pe ọjọ Aiku ni ọkọ ofurufu naa balẹ si Naijiria ki Aarẹ le fi rinrinajo naa.

Bayo Onanuga, to jẹ ọkan lara awọn agbẹnusọ Aarẹ sọ pe “ọkọ baalu tuntun Airbus A330 ni yoo rọpo ọkọ ofurufu atijọ, Boeing B737-700 ti wọn ra labẹ ijọba Oluṣegun Obasanjo lọdun mọkandinlogun sẹyin.”

Amọ ọpọ awuyewuye lo ti tẹle atẹjade naa paapaa lasiko ti nnkan le koko faraalu.

Ọrọ mii ti awọn araalu tun n mẹnuba ni boya ileeṣẹ Aarẹ gba aṣẹ lọwọ ile igbimọ aṣofin ko to ra ọkọ ofurufu tuntun ọhun, bo ṣe yẹ ko ri gẹgẹ bii alakalẹ ofin.

Ohun ti a mọ nipa ọkọ ofurufu tuntun Airbus A330-200

Iwadii BBC fi han pe ọdun marundinlogun sẹyin ni wọn ṣe ọkọ ofurufu tuntun naa.

Lẹyin ti wọn ṣe e tan ni ileeṣẹ Saudi Arabia kan, Midroc Aviation, lo o lọdun 2019 ki ileeṣe naa to ta ọkọ ọhun fun ileeṣe AMAC Aerospace ni Sweden lọdun 2021, ki ijọba Naijiria to ra a bayii.

Papakọ ofurufu Basle Mulhouse Freiburg ni ọkọ naa wa lati nu oṣu Karun un ọdun yii ki wọn to gbe wa si Naijiria lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ ti a wa yii.

Ṣe ile igibimọ aṣofin buwọlu rira rẹ?

Ninu oṣu Kẹfa ọdun yii, iroyin ni Aarẹ fi afikun eto iṣuna ranṣẹ si awọn aṣofin lati buwọlu, ati pe owo baalu naa wa lara afikun eto iṣu ọhun, amọ Aarẹ ile aṣofin, Godswill Apabio sọ pe ko ri bẹẹ.

O ni “mo ti ka awọn lẹta ti Aarẹ fi ṣọwọ si wa, ko si sohun to jọ owo ọkọ orufuru ninu rẹ.

“Ti ẹ ba n gbọ iroyin nipa iku awọn eeyan bii igbakeji Aarẹ Malawi tabi Aarẹ Iran latari ọkọ ofufuru to yọnu, a ko ni gba ki irufẹ nnkan bẹẹ jẹ ipin wa ni Naijiria.”

Lẹyin naa, ko si iroyin kankan mọ nipa owo ọkọ ofurufu ọhun.

Iroyin ti awọn araalu yoo gbọ nipa ọkọ ofurufu Aarẹ Naijiria lẹyin naa ni pe ile ẹjọ kan fun ileeṣẹ ilẹ China, Zhongshan Fucheng Industrial Investment Co. Ltd laṣẹ lati gbẹsẹle ọkọ ofurufu Aarẹ Naijiria mẹta.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, idajọ naa waye lẹyin wahala to bẹ silẹ nipa adehun owo kan laarin ileeṣẹ naa ati ijọba ipinlẹ Ogun.

“Kii ṣe ohun to tọ ki Aarẹ ra ọkọ ofurufu lasiko ti epi n pa araalu”

Ẹwẹ, ni kete ti iroyin naa lu sita pe awọn aṣofin fẹ buwọlu ọkọ ofurufu tuntun fun Aarẹ ni ẹgbẹ alatako ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa.

Ninu atẹjade kan, oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour. Peter Obi sọ pe igbesẹ naa kii ṣe ohun to bojumu.

O ni “pẹlu eto abo to dagẹgẹ, ìṣẹ́ to wa niluu ati ebi ọpagba to wa nita, igbesẹ naa fi han pe ijọba ko mọ ohun ti araalu n koju.

“Kii ṣe ohun to ṣe itẹwọgba nitori bi ilu ṣe ri lasiko yii, ni ṣe lo yẹ ki ijọba gbajumọ bi ara yoo ṣe dẹ araalu.”

Ṣugbọn nigba ti yoo fesi, Onanuga sọ pe niṣe ni Obi n fẹ ki Aarẹ Naijiria jade lẹyin ijamba ọkọ ofurufu to gbẹmi igbakeji Aarẹ Malawi.

Wayi o, lẹyin ti iroyin jade pe ileeṣẹ China kan gbẹsẹle ọkọ ofurufu Aarẹ Naijiria, Obi sọ pe ohun itiju nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ.