Wo irúfẹ́ àwọn oúnjẹ táwọn èèyàn jẹ tí wọ́n sì gba ibẹ̀ kú láìpẹ́ yìí àti ohun tó fà á

Aworan ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Amalazone/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọpọ eeyan lo ti n kọminu lori bi iṣẹlẹ awọn eeyan to n jẹun ti wọn si n gba ibẹ ku ṣe n ṣẹlẹ lera lera lẹnu lọọlọ yii.

Eyi lo jẹ ki ọpọ eeyan maa ro wi pe majele lawọn eeyan to jade laye lẹyin ti wọn jẹun tan jẹ eyi to si ṣe okunfa iku wọn.

Ti a ba ka a ni ọkọọkan ejeeji, akọsilẹ fihan pe eeyan mẹtalelogoji lo ti ku bayii kaakiri orilẹede Naijiria laipẹ yii, lẹyin ti wọn jẹun tan.

Bakan naa ni a tun gbọ pe ọpọ eeyan mii ni wọn wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju latari ounjẹ ti wọn jẹ.

Awọn iṣẹlẹ yii lo ti jẹ kawọn oṣiṣẹ eleto ilera, awọn onimọ nipa ounjẹ jijẹ atawọn mii tọrọ kan pe fun didaabo ounjẹ sii ati imọtoto.

Wọnyi ni awọn iṣẹlẹ ounjẹ to ṣeku pawọn eeyan laipẹ yii ni Naijiria.

Iya ati ọmọ mẹta dero ọrun lẹyin ti wọn jẹ amala tan n’Ilorin

Iṣẹlẹ a gbọ bomi loju lo sẹlẹ lowurọ kutu ọjọ Aje ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ yii ni ilu Ilọrin tii ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.

Iṣẹlẹ naa wáyé ni ojule kẹta adugbo Asa-dam ni ijọba ibilẹ guusu Ilorin.

Ọkan lara awọn mọlẹbi tọrọ naa ṣoju rẹ, Ọgbẹni Wasiu ṣalaye pe, lẹyin ti wọn jẹ amala tan ni inu bẹrẹ si ni run wọn.

O fikun ọrọ rẹ pe ọkan ninu awọn ọmọ naa to jẹ ọmọ ọdun mẹwa lo kọkọ pariwo inu rirun ti wọn si gbe e lọ si ile iwosan nibi to ti jade laye.

Lẹyin naa ni a gbọ pe aburo rẹ ti wọn bi tẹle e naa bẹrẹ si ni di inu mu ti wọn si gbe oun naa lọ ile iwosan pẹlu ẹni ti wọn bi tẹle e ati iya awọn ọmọ naa, nibi ti wọn ti di oloogbe.

Lasiko ti BBC Yoruba ṣabẹwo si ile ibi iṣẹlẹ naa, wọn fi ye wa wi pe, ọkọ oloogbe naa ti ṣe baba awọn ọmọ to ku pẹ koto wọle ni ko ṣe bawọn jẹ ninu ounjẹ ọhun.

Ọmọ wọn kan ṣoṣo to ṣẹku jẹ ọmọ oṣu meje toun mu ọyan lọwọ naa ko jẹ ninu ounjẹ naa.

Ọmọ mẹrin ati iya ku ni Nnewi lẹyin ti wọn jẹun tan

Ṣaaju ni ibẹrẹ oṣu kẹjọ yii ni iroyin kan jade eyi to sọ pe iya ati ọmọ mẹrin dero ọrun lẹyin ti wọn jẹun tan niluu Abubor Nnewichi ni ijọba ibilẹ Nnewi nipinlẹ Anambra.

Eeyan meje ninu idile kan ku ni Sokoto lẹyin ti wọn jẹun tan

Ninu oṣu Kẹjọ yii naa iroyin kan tun fidi rẹ mulẹ pe eeyan meje ninu idile kan dero ọrun lẹyin ti wọn jẹun tan.

Ohun ti a gbọ ni pe ounjẹ ti wọn fi ẹgẹ ṣe lawọn eeyan na jẹ eyi ti wọn si gba ibẹ lọ sọrun lojiji.

Abule Runjin Barmo lẹkun Kajiji ni ijọba ibilẹ Shagari ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Eeyan marun un dero ọrun lẹyin ti wọn jẹ ọbẹ tan ni Sokoto

Ni ọjọ Aiku ọsẹ yii ni iroyin mii tun jade eyi to sọ pe marun un ninu eeyan meje to wa ni idile kan dero ọrun lẹyin ti gbogbo wọn jẹ ọbẹ ti wọn fi ajilẹ ti ọpọ mọ si Gishirin lalle se.

Kọmiṣọna fun eto ilera nipinlẹ Sokoto, Asabe Balarabe ṣalaye pe iṣẹlẹ ọhun waye ni abule Kaurar Wanke ni ijọba ibilẹ Shagari kan naa.

Balarabe ṣalaye pe awọn mọlẹbi naa ro pe maagi lawọn fi sinu ọbẹ ti wọn fẹ jẹ lai mọ pe ajilẹ ni.

Gẹgẹ bi kọmiṣọna ṣe sọ, mẹta ninu awọn eeyan yii lo kọkọ ku lọjọ Ẹti nigba tawọn meji yoku jẹ Ọlọrun nipe lọjọ Aiku.

Iroyin yii dabi iṣẹlẹ to waye ni nnkan bi ọsẹ kan sẹyin nipinlẹ Nasarawa nibi ti eeyan mẹfa ti dero ọrun lẹyin ti wọn jẹun tan ni abule Gidinye ni ijọba ibilẹ Obi.

Ọmọ marun ati iya wọn ku ni Kano lẹyin ti wọn jẹun tan

Laipẹ yii ni a gbọ pe iya ati awọn ọmọ rẹ marun jẹ Ọlọrun nipe ni abule Karkari ni ijọba ibilẹ Gwarzo ni ipinlẹ Kano.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe lẹyin tawọn eeyan yii jẹun tan ni wọn bẹrẹ sii di mọ inu eleyii to sọ wọn dero ile iwosan.

Ounjẹ ibilẹ ti wọn n pe ni Danwake ti wọn maa n fi ẹgẹ ṣe ni a gbọ pe idilẹ naa jẹ.

Ọkan lara awọn alabagbe mọlẹbi naa sọ pe elubọ lanfun to ti bajẹ ni obinrin naa fi se ounjẹ fawọn ọmọ rẹ ti gbogbo wọn si dero ọrun lati ibẹ lọ.

Eeyan mẹfa ku ni Kogi lẹyin ti wọn jẹun amala lanfun

Ni bi ọjọ meloo kan sẹyin ni ijọba ipinlẹ Kogi kede wi pe eeyan mẹfa dero ọrun lẹyin ti wọn jẹ amala lanfun to ti bajẹ ni abule Anyoke ni ijọba ibilẹ Adavi.

Nigba ti o n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ Kogi, Dokita Amina El-Imam, sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ wi pe amala lanfun ti wọn jẹ naa lo ṣeku pa wọn.

Kọmiṣona naa fikun ọrọ rẹ pe oun ṣakiyesi pe ko si imototo ni agbegbe ti awọn mọlẹbi naa n gbe.

Nitori naa, Dokita El-Imam ni o dabi ẹni pe kẹmika to wa ninu ẹgẹ ti wọn fi ṣe elubọ lanfun ti wọn fi ro amala ti wọn jẹ lo ṣokunfa iku awọn eeyan yii.

Alaye ree lori ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan lẹyin ti wọn jẹun tan

Igbakeji aarẹ ẹgbẹ AFAN, ti i ṣe ẹgbẹ awọn agbẹ ni Naijiria, Ajibola Olawale Tajudeen, fidi rẹ mulẹ pẹlu iwe iroyin Daily Trust pe bi awọn eeyan kan ṣe ko ounjẹ lo n ṣokunfa iku awọn eeyan.

Ọgbẹni Tajudeen ṣalaye pe awọn kẹmika tawọn eeyan fi n tọju awọn ounjẹ ti ko pamọ lo n ṣakoba fawọn eeyan to n ra awọn ounjẹ naa.

O kepe ijọba lati gbe igbimọ kan dide ti yoo maa ri wi pe awọn eeyan ko ko ounjẹ pamọ mọ eyi to n ṣakoba fawọn to n ra awọn ounjẹ yii.

Ọjọgbọn Oluwasogo Olalubi to jẹ onimọ nipa eto ilera ṣalaye pe ẹgẹ jijẹ n fa majele fawọn eeyan kẹmika to wa ninu rẹ ko tii kuro tan.

O ni eyi wọ pọ pẹlu elubọ lanfun tori inu rẹ ni kẹmika majele yii ti pọju.

Ninu ọrọ tiẹ, alaga ẹgbẹ awọn oniṣẹ agbẹ, David Kayode Ehindero, sọ pe ohun to n fa iku ojiji lara ounjẹ tawọn eeyan n jẹ ni awọn ounjẹ ti ko dara to tawọn kan n ko wọ Naijiria.

Wo bi o ṣe le dena iku aitọjọ nipasẹ ounjẹ jijẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alakoso ajọ NAFDAC to n mojuto ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria ni ipinlẹ Kwara, Nadabo Nathan rọ awọn eeyan ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin Daily Trust wi pe ki wọn maa ri pe oje oloro to wa ninu ẹgẹ kuro tan ki wọn to fi ṣe elebọ lanfun.

O ṣalaye wi pe ojuṣe NAFDAC ni lati mojuto ounjẹ ati oogun to wa ninu ọra ati paali.

Ọgbẹni Nathan sọ pe ounjẹ tawọn eeyan n pese rẹ bi elubọ lanfun ko si lara awọn irufẹ awọn ounjẹ naa.

Amọ, o ni awọn eeyan ni lati maa rẹ ẹgẹ ti wọn fi n ṣe lanfun daadaa sinu omi ki oje ara rẹ le jade daadaa ki wọn to sa a lati fi ṣe elubọ.

O ni ko si bi oje oloro ara ẹgẹ yii ṣe fẹ jade tan ti wọn ba fẹ ṣe elubọ ni kiakia.

Ẹwẹ, aarẹ ẹgbẹ NMA ti i ṣe ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ oniṣegun ni Naijiria, Ọjọgbọn Bala Audu, naa ti rọ awọn araalu lati yago fun ounjẹ ti ọjọ ba ti lọ lori rẹ.

Ọjọgbọn Audi tun rọ awọn eeyan lati maa se ounjẹ ti wọn le jẹ tan ni kiakia tori ọpọ ounjẹ ti wọn n ko pamọ lo n ṣakoba fun ọpọlọpọ bayii.

Bakan naa ni o rọ awọn ti wọn ko ounjẹ pamọ lati ṣe akiyesi iru oogun ti wọn n lo lati fi ko ounjẹ naa pamọ ko si jẹ eyi ti ko le ṣakoba fawọn eeyan to ba n jẹ ounjẹ naa.

Ọjọgbọn Audu ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe iwadii gidi gbọdọ waye lori ohun to ṣe okunfa iku awọn eeyan to dero ọrun yii lẹyin ti wọn jẹun tan ki gbogbo eeyan le mọ ohun to ṣẹlẹ gan an.